BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Toyin Abraham sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ sí i èyí tó gbomi lójú rẹ̀
Ilumọọka oṣere naa sọrọ yii nibi isin orin Bestie Jesu Concert 2026 to waye niluu Eko lopin ọsẹ to kọja.
Ododo kéde ọjọ́ mẹ́ta láti kẹ́dùn Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀ Ibrahim Idris tó doólògbé
Gomina Usman Ododo kéde ọjọ́ mẹ́ta láti kẹ́dùn Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀ Ibrahim Idris tó doólògbé
Atiku bínú sí Tinubu tó rán aṣojú ló sípàdé UNGA fún ìgbà kẹ́ta, ó ní ṣe ẹ̀rù ń ba Ààrẹ láti wọ America ni
Ọla ode yii ti i ṣe ọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ipade naa yoo bẹrẹ pẹrẹwu, Igbakeji aarẹ Naijiria, Kashim Shettima ni yoo si ṣoju fun Aarẹ.
Fídíò, Mo fẹ́ràn obìnrin lóòótọ́ àmọ́.... – Ayo Olaiya, Duration 3,34
Olaiya sọ fun BBC News Yoruba pe nitori pe iya oun ṣe wahala nigba ti wọn n tọ oun, ti iku ko si jẹ ki iya naa gbadun obi to gbo ko to mu u sọdọ ni oun fi sọ ara oun ni Olaiya.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,59
Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri àgbáyé tí kò ṣe è má gbọ̀ ọ́
Èèyàn lè gbé ẹ̀sìn lórí àmọ́ kí ìwà rẹ̀ burú – Ìyàwó Femi Adebayo tẹ́lẹ̀
Omotayo lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instagram rẹ ni iranti ayẹyẹ ọdun mẹrinlelogoji rẹ loke eepẹ.
Ẹ yé gbé irọ́ kiri, kìí ṣe gbèsè ₦8,000 ló sọ Mohammed tó kú dèrò àtìmọ́lé, ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé - Ọlọ́pàá Oyo ṣàlàyé
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọkunrin naa dero ahamọ lọgba ẹwọ Agodi tori o kuna lati pese awọn nnkan ti ileẹjọ beere fun beeli rẹ, kii ṣe wi pe ọlọpaa ti i mọlẹ nitori gbese ₦8,000 to jẹ.
Owó tí àwọn ọmọ Naijiria ń ná láti wọ ọkọ̀ kò pọ̀ tó ti àtijọ́ mọ́ – Tinubu
Tinubu lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan pe bẹrẹ lati ọjọ Kinni, oṣu Kẹwaa, awọn araalu yoo bẹrẹ si n janfani owo ti ko pọ lori ọkọ wiwọ mọ labẹ eto National Affordable CNG Transit Programme.
Ìjọba APC kò pèsè iná la ṣe ń fowó ra epo tanná sí títì- Seyi Makinde dá a padà fún Sharafadeen Alli
Ẹ o ranti pe igun Sharafadeen Alli lo fesun yii kan Seyi Makinde, lẹyin ti gomina naa sọ pe lọya ti ko de kootu ri ni Alli n ṣe.
Ẹgbẹ́ ọmọ ogun Houthi ní òun ti fi àdó olóró ránṣẹ́ sí olú ìlú Saudi Arabia
Ijọba Saudi sọ pe oun koju ado oloro kan loju ofurufu, eyii ti wọn kọkọ fi ṣọwọ si Riyadh amọ ko sọ nipa awọn ikọlu mii tabi awọn ti iṣẹlẹ naa kan.
Ìdí tí Trump fi fòfin de CNN àti iléeṣẹ́ ìròyìn méjì mii ní White House
CNN ti ṣapejuwe ikede Donald Trump gẹgẹ bi eyi to tako ominira ileeṣẹ iroyin Amẹrika ati igbesẹ to lodin sofin.
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Fídíò, Òṣìṣẹ́ báǹkì tó di ẹni tó ń ta pọ̀nmọ́ aláta lọ́jà nílùú Ibadan, Duration 5,13
Ninu ifọrọwerọ yii, Ọgbẹni Adeloye Adekunle ṣalaye irinajo rẹ lati inu banki nibi ti owo gbe n so titi de idi aro nibi to ti n fi irungbọn fẹ ina pọnmọ alata.
NAFDAC ṣàwárí èròjà aṣekúpani tó fa ikú ọ̀pọ́ èèyàn nínú ọtí l'Ondo, àlàyé rèé
Ninu atẹjade kan ti ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, fi sita lọjọ Ẹti ni wọn ti kede pe eroja kan ti a mọ si Methanol lo fa iku awọn eeyan naa.
Ìdí rèé tí mo ṣe kọ̀ láti polongo ìbò fún APC ní Eko - Toyin Abraham
Ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ lọjọ Ẹti, Toyin Abraham sọ pe kii ṣe nitori awọn to n bu oun lori ayelujara ni oun ṣe kọ ipo naa nitori awọn eeyan ori ayelujara kọ ni wọn maa ṣe ipinnu fun oun.
Wo kókó ohun tí Atiku bá àwọn ọmọ Nàìjíríà, Tinubu sọ nípa àlèkún tó ń bá owó epo bẹntiróòlù
Nibi ọrọ ti Atiku ba awọn ọmọ Naijiria sọ lọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlogun, oṣu Kẹsan-an ni o ti sọrọ nipa iye owo epo bẹntiroolu, awọn eto ibojuaanuwoni ati bi awọn araalu ṣe n gbe, to si sọ pe yiyọ iranwọ ori epo ti mu alekun ba owo tawọn eeyan fi n wọkọ, ounjẹ ati ipese ọja.
Kò yẹ kí nǹkan tó bá ń ṣẹlẹ̀ lọ́jà àgbáyé máa mú ìnira bá àwọn ọmọ Nàìjíríà
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ ni awọn orilẹede tawọn naa ni epo lagbaaye bii Naijiria ti n ṣeranwọ fun araalu latari owo epo to n lọ soke lagbaaye.
Àwọn afurasí márùn-ún tó jí akẹ́kọ̀ọ́ Oyo gbé láwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n nilé-ẹjọ́
DSS ni, awọn afurasi naa jẹ ọmọ ẹgbẹ Jama'atu Ansarul Muslimina fi-Biladis Sudan (ANSARU), eyi ti wọn pe ni ẹgbẹ janduku agbebọn aṣekupani.
Mọ̀ nípa àìsàn tó máa ń mú èèyàn gbàgbé nǹkan tó ṣe Olu Jacobs kó tó jáde láyé
Aarọ Ọjọru, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni awọn mọlẹbi Olu Jacobs kede ipapoda rẹ.
Ìjọba Nàìjíríà mókè lórí àkànṣe iṣẹ́ iná tí ìrétí wà pé yóò máa pèsè mẹ́gáwáàtì 1,500
Lati ọpọ ọdun sẹyin ti wọn ti n gbero lori iṣẹ ina yii ṣugbọn awọn igbẹjọ to wa lori rẹ ni ko jẹ ki wọn tẹsiwaju.
Ọdún mẹ́tàlá lo fi báwa gbé, a máa ṣàfẹ́kù rẹ -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí kọrin arò lẹ́yìn tí ajá a rẹ̀ jáde láyé
Ayaworan nileeṣẹ aarẹ tẹlẹ, Pete Souza, sọ pe nnkan iwuri lo jẹ foun wi pe oun ṣiṣẹ pọ pẹlu aja naa to n jẹ Sunny.
Ọlọ́pàá Ogun ri iPhone akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kánlá gba padà lọ́wọ́ afurasi Adigun jalè meji
Atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa, Babaseyi Oluseyi fi sita lo fidi iroyin naa mulẹ f'awọn akọroyin niluu Abeokuta.
Kò sí gómìnà tó ní àṣẹ láti dá iṣẹ́ ẹgbẹ́ awakọ̀ NURTW dúró ní ìpínlẹ̀ rẹ̀ - NURTW ṣèkìlọ̀ fún Gómìnà Adeleke l'Osun
Nibẹ ni wọn ti sọ pe igbesẹ Gomina Ademola Adeleke lati dawọ gbogbo iṣẹ NURTW nipinlẹ Osun ko ba ofin ati ilana ti wọn fi da ẹgbẹ wọn silẹ mu.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
A ò fẹ́ irú àjọṣepọ̀ tí ò ń bèèrè fún – Àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlù APC kẹyìn sí Fayose lórí ìbò 2027
Nyesom Wike wa sọ pe Aarẹ Bola Tinubu loun ba da owo pọ kii ṣe awọn gomina APC.
Agbébọn darandaran pá ọlọ́pàá méjì, ṣe ọ̀gá ọlọ́pàá léṣe ní Benue
Aondongu ọ pe ọga ọlọpaa ẹkun ọhun lọ gba nnkan niluu Makurdi , ati pe asiko toun pẹlu ikọ akọwọrin rẹ n pada lọ si ibudo wọn, ni awọn agbebọn naa da wọn lọna.
Fídíò, Ǹjẹ́ ó tọ́ kí òbí máa kàn án ní dandan f'áwọn ọmọ láti tọ́jú wọn lọ́jọ́ ogbó?, Duration 3,37
Ọpọ lo maa n gbadura pe ki awọn jẹun ọmọ ṣugbọn ohun to n lọ kiri lode oni ko fi ara jọ pe o n fẹ ri bẹẹ.
Ọwọ́ tẹ afurasí agbébọn márùn-ún lẹ́yìn ìkọlù silé iṣẹ́ ọmọ ogun ní Igbeti ní Oyo
Awọn afurasi marun-un naa ni wọn mu lasiko ti wọn ri wọn ninu aṣọ ọmọ ologun ninu igbo Ọba to wa ni agbegbe ọhun.
Igbó ni wọ́n ń gbìn dípò kòkó káàkiri oko ní ìpínlẹ̀ Edo báyìí - NDLEA
Ofoyeju sọ pe igbo ti awọn eeyan n gbin, lo ti n rọpo awọn ohun jijẹ to yẹ ki wọn maa fi oko ati igbo gbin bayii, leyi to si le ṣe akoba pupo fun alaafia ilu.
Àwọn ọ̀dọ́ bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn lórí ìpànìyàn lemọ́lemọ́ tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Osun
Nibi ikọlu to waye ni garaaji Mayfair naa ni wọn ti yinbọn pa ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ naa, Olalekan Oyeymi, ẹni tọpọ mọ si Emir Ajagungbade.
Fídíò, Wo omi Atan tó ń ‘ṣe ìwòsàn, fún ni lọ́mọ’ ní Ikare Akoko, àmọ́ obìnrin tó bá fọwọ́ kàn án, nǹkan oṣù rẹ̀ yóò gbẹ, Duration 3,32
Adagun omi Atan lo wa laarin ori oke meji takọtabo nilu Ikare Akoko nipinlẹ Ondo, eyi ti wọn lo kun fun ọpọ ohun iyanu.
Fídíò, Àwọn olólùfẹ́ Kola Oyewo sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ lẹ́yìn ìsìnkú rẹ̀, Duration 3,24
Tẹ o ba gbagbe, Oloye Oyewo jade laye lọjọ kejila, oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii lẹni ọgọrin ọdun.
Fídíò, Ìtàn Balogun Oderinlo tí àjà gbé lọ fún àádọ́rin ọjọ́, ó padà dé pẹ̀lú àpò àbìrà tí ọ̀sanyìn wà, ó di alágbára fún Ibadan, Duration 5,53
Ogun marundinlaadọjọ ni itan sọ pe Balogun Oderinlo ja nigba to wa laye, to si bori rẹ, ko to di pe o fi aye silẹ lọdun 1850












































































