Ìpínlẹ̀ Osun kò nílò ẹ̀jẹ̀ ẹnikẹ́ni láti tẹ̀ síwájú, ẹ̀yin olóṣèlú tó ń pa èèyàn, ẹ jáwọ́ níbẹ̀ – Olùdíje gómìnà ZLP
Bi eto idibo gomina nipinlẹ Osun se n sunmọle, BBC News Yoruba ba oludije sipo gomina fun ẹgbẹ oselu Zenith Labour Party, ZLP, Enginia Olufemi Adesuyi sọrọ lati mọ ọpọ ohun to fẹ se fun araalu.
Lasiko to n takurọsọ pẹlu wa, Adesuyi ni ti kii ba se pe ẹni to ni arojinlẹ nipa ohun ti araalu n fẹ lo le dipo ipo gomina.
O ni aabo ẹmi ati dukia yoo jẹ ijọba oun logun ti oun ba wọle sipo gomina naa, ti oun yoo si tun mu eto ọgbin ati ipese ounjẹ fawọn eeyan ipinlẹ naa ni ọkunkundun.
Bakan naa ni Adesuyi ni oun yoo maa seto ironilagbara lati gbe ọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun soke, ti agbega ọrọ aje ipinlẹ naa ko si tun gbẹyin.

"Gbogbo oun ti eeyan nilo lati de ipo gomina ni mo ni, boya nidi eto ẹkọ ni tabi iriri, mo ni awọn ojutuu lọwọ lati wa ọna abayọ sawọn isoro to n koju wa nipinlẹ Osun"
Adesuyi fikun pe eto ilera to peye , ti owo rẹ ko gunpa gbọdọ wa ni arọwọto awọn araalu.
Oludije gomina naa sisọ loju rẹ pe oun ti rin yika ipinlẹ Osun lati mọ isoro to n koju awọn araalu, ti oun si tun ti wa ọna abayọ si.
"Gbogbo oun ti eeyan nilo lati de ipo gomina ni mo ni, boya nidi eto ẹkọ ni tabi iriri, gbogbo rẹ ni mo ni.
Mo si ni awọn ojutuu lọwọ lati wa ọna abayọ sawọn isoro to n koju wa nipinlẹ Osun."
"Ẹni ti Ọlọrun yoo lo lati mu ki ipinlẹ Osun tẹsiwaju, o ti mọ ọ, tori naa, a ko nilo pe ka fi agbara kaka se e"
Nigba to n sọrọ lori isẹlẹ idaluru ati ipaniyan to n fi ojojumọ waye nipinlẹ Osun bi eto idibo gomina naa se n kanlẹkun gbọn gbọn, Adesuyi wa rọ gbogbo oloselu to wa ni ipinlẹ Osun lati dawọ ipaniyan duro.
"Mo n bẹ gbogbo awọn oloselu to n ha ibọn fawọn eeyan ni ipinlẹ Osun lati maa da ilu ru, pa awọn eeyan pe ki wọn dẹkun iwa bayii.
Mo ti gbe akọle kan sita to ni ipinlẹ Osun ko nilo ẹjẹ ẹnikẹni lati tẹsiwaju, tori naa, ẹ jẹ ka yago fun iwa jagidijagan.
Ẹni ti Ọlọrun yoo lo lati mu ki ipinlẹ Osun tẹsiwaju, o ti mọ ọ, tori naa, a ko nilo pe ka fi agbara kaka se e.
Mo tun n rọ awọn oludibo nipinlẹ Osun lati se pẹlẹ, ka si bawọn ọmọ wa sọrọ pe ki wọn ma se jagidijagan.
Awọn ọmọ wa ti wọn ti pa danu, awọn ogo ọla ni wọn, mo si gbadura pe wọn ko ni fi ẹjẹ wa se etutu ibo.
Mo tun rọ awọn oludibo pe ki wọn tẹ ika wọn si ibi to yẹ lati dibo, mo n fẹ ki wọn fi ibo wọn se atilẹyin fun emi, tii se oludije fun ẹgbẹ oselu Zenith Labour Party."






