Mo bẹ gómìnà Imo láti gba àláàfíà láàyè lásìkò ìbò gómìnà l‘Osun, kó sì rántí pé ọmọ ìpínlẹ̀ Imo ni aya mi - Davido

Bi eto idibo gomina nipinlẹ Osun se ku diẹ, awọn iwa idaluru, jagidijagan, ipaniyan ati iwa ipa lorisirisi lo ti n waye nipinlẹ naa.
Ọpọ eeyan si lo ti n kaya soke nipa awọn isẹlẹ naa, eyi ti awọn eeyan n kọ̀minu pe o le nipa lori abajade eto idibo naa.
Idi ree ti gbajumọ akọrin takansufe nni, David Adeleke, ẹni ti gbogbo eeyan mọ si Davido, to tun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Osun se sọrọ soke nipa awọn isẹlẹ naa.
Davido, ẹni to seto ipade awọn akọroyin nilu Osogbo ni ọjọru sọrọ nipa idi to se yẹ ki gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa gba alaafia laaye saaju, lasiko ati lẹyin idibo naa.
Bi ẹ ko ba gbagbe, aburo baba Davido, Ademola Adeleke ni gomina lọwọ bayi nipinlẹ Osun, to si ti n doju kọ oniruuru ipenija eto aabo bi eto idibo naa se n sunmọle.
Davido ti wa sọrọ lori bi eto aabo ṣe mẹhẹ ni ipinlẹ Osun lọwọ lọwọ bayii., ati bi eto idibo si ipo gomina Ipinlẹ Ọsun ṣe di ogun.

"Mo bẹ gomina Ipinlẹ Imo lati fi aaye gba alaafia nipinlẹ Ọsun, mọ gbọ pe, gomina Ipinlẹ Imo ti leri lati da omi alaafia Ipinlẹ Ọsun ru"
Ninu ọrọ rẹ, Davido eto idibo ko yẹ ko jẹ ohun ti yoo di ogun tabi fi fi ẹmi sofo rara. O yẹ ki o jẹ ti alaafia ni.
Gbajugbaja olorin takasufe ọhun tun tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, gbogbo ọna ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako n gba lati fi tipatipa gba ijọba lọwọ gomina Ademola Adeleke, ni wọn n wa.
Sugbọn o ki gbogbo ololufẹ gomina Ademola Adeleke lọ fi ọkan balẹ pe, ti Oluwa ni yoo sẹ ni ọjọ Kẹdogun osu Kẹjọ ọdun yii, ti eto idibo gomina naa yoo waye.
"Ẹ jade sita lati dibo ni ọjọ Kẹdogun osu Kẹjọ ọdun yii nitori didi ibo yin fun gomina Adeleke lo le pa ẹnu awọn ẹgbẹ oṣelu alatako mọ.
Mo bẹ gomina Ipinlẹ Imo lati fi aaye gba alaafia nipinlẹ Ọsun, lati jẹ ki awọn olugbe Ipinlẹ Ọsun dibo fun ẹni to wu wọn.
Nitori mọ gbọ pe, gomina Ipinlẹ Imo ti leri lati wa si Ipinlẹ Osun lasiko idibo si ipo gomina lati da omi alaafia Ipinlẹ Ọsun ru.
Ẹ jẹ ki awọn eeyan Ipinlẹ Ọsun dibo fun ẹni to wu wọn, gomina Ipinlẹ Imo, mo fẹ ki ẹ ranti pe, iyawo mi Ipinlẹ Imo lo ti wa."
Davido, tun rọ gbogbo awọn oloselu pe, ki wọn jẹ ki alaafia ko pada si Ipinlẹ Ọsun ki wọn si fi aaye gba alaafia laaye.
Bi ẹ ko ba si gbagbe, gomina Hope Uzodimma ti ipinlẹ Imo lo n dari eto ipolongo ibo fun ẹgbẹ oselu APC lapapọ lori eto idibo ipinlẹ Osun.
Davido, mura lati gba aburo baba rẹ bii ara awọn onijo lẹyin rẹ tori o seese ko ma nisẹ lọwọ mọ, to ba fi fidi rẹmi ninu ibo gomina to n bọ - Gomina ipinlẹ Imo fesi
Wayi o, gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodimma ti fesi lori awọn ẹsun ti Davido fi kan an.
Atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ rẹ feto iroyin, Ambrose Nwaogwugwu, fọwọsi, wa rọ akọrin takansufe naa lati bawọn araalu sọrọ, dipo fifi ẹsun kan oun.
Uzodimma ni "O jẹ iwa ailoye ki Davido maa rawọ ẹwẹ si oun nitori pe iyawo rẹ ti ipinlẹ Imo wa amọ awọn oludibo nipinlẹ Oyo lo yẹ ko gbajumọ.
Alaafia ni mo maa n polongo lojoojumọ, mo si tun pinnu pe eto idibo gomina ipinlẹ Osun yoo lọ nirọwọ-rọsẹ.
Awọn oludibo nipinlẹ Osun lo ti gbaradi lati fi ibo le aburo baba Davido kuro nipo Gomina nitori ẹsun pe o kuna lati mu awọn ileri ipolongo ibo rẹ sẹ, ti wọn yoo si dibo yan Bola Oyebamiji, tii se oludije fẹgbẹ oselu APC.
Gomina ipinlẹ Imo wa rọ Davido lati maa reti ijakulẹ ninu eto idibo to n bọ dipo ko maa parọwa kiri.
Bakan naa, Uzodimma tun sọ fun Davido pe ko setan lati gba aburo baba rẹ bii ara awọn to n jo kiri lẹyin rẹ ninu ẹgbẹ akọrin rẹ nitori o seese ko ma nisẹ lọwọ mọ to ba fi fidi rẹmi ninu ibo gomina to n bọ.
Kí ló tún da omi àláàfíà rú l‘Osun tí Adeleke ṣe ń lọgun ké sí Tinubu pé ọlọ́pàá ti gbàbọ̀dè, bí Oyebamiji ṣe lọgun pé APC ló ń kojú ìpànìyàn l'Osun?
Gomina ipinlẹ Osun, Ademola Adeleke, to jẹ oludije sipo gomina fegbẹ Accord ti sọ pe oun ko foya lori eto idibo gomina ipinlẹ naa to n bọ, amọ, gomina sọ pe oun ko ni igboya ninu ileeṣẹ ọlọpaa ṣaaju eto idibo naa.
Gomina Adeleke ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe oun si ni igbagbọ ninu igbimọ to n pe fun alaafia ninu eto idibo to n bọ eyi ti Olori ologun orilẹede Naijiria tẹlẹ ri, Ọgagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar jẹ alaga rẹ.
Nigba to n sọrọ lẹyin eto ''Ọjọ Kan Pẹlu Gomina'' eyi ti ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ ṣagbatẹru rẹ, Adeleke ni oun ko mikan rara tori Ọlọrun wa lẹyin oun ati lẹyin awọn eeyan ipinlẹ Osun.
Lẹyin to buwọlu adehun alaafia ṣaaju eto idibo gomina ọjọ kẹẹdogun oṣu yii to n bọ, Gomina Adeleke sọ pe ''igbimọ to n ri si bi eto idibo to n bọ yoo ṣe lọ ni alaafia ti ṣeleri lati bawọn ọlọpaa sọrọ.
Amọ, mi o ni igbagbọ ninu awọn ọlọpaa lọwọ yii, mo gbadura pe Ọlọrun yoo fọwọ tọ wọn lọkan.''

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/X/Bola Oyebamiji/X
"Ẹgbẹ oselu alatako kan n halẹ lasan ni, emi ni maa bori ibo gomina Osun"
Adeleke fikun ọrọ rẹ pe o da oun loju wi pe oun yoo jawe olubori ninu ibo gomina to n bọ, o ni awọn ẹgbẹ oṣelu alatako kan n halẹ lasan an ni.
Gomina ipinlẹ Osun sọ pe gbogbo nnkan ti ẹgbẹ oṣelu alatako n ṣe lati da eto idibo naa ru yoo jasi pabo.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord ni awọn araalu yoo dibo foun tori awọn akanṣẹ isẹ ti oun ti ṣe nipa ipese ohun amayedẹrun, mimu ileri toun ṣe fun araalu ṣẹ, ati sisan owo ajẹmọnu fawọn oṣiṣẹ .
''A ti wa ni igbaradi, mo si fẹ rọ awọn araalu wi pe ki wọn ma foya.
Ijọba awarawa ni a wa, ẹnikẹni ko gbọdọ bẹru idunkoko ẹgbẹ oṣelu APC.
Ifẹ Ọlọrun ati ti eniyan nikan ni yoo ṣẹ, mo n rọ gbogbo eeyan lati jade wa dibo lọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii.
Ṣaaju lọsẹ ti kọja ni alaga ẹgbẹ oṣiṣẹ ẹka ipinlẹ Osun, Kọmureedi Christopher Arapasopo, ti sọ pe awọn oṣiṣẹ ko ni pada si igba to buru jai laye ijọba APC nipinlẹ Osun.
O rọ gbogbo oṣiṣẹ wi pe ki wọn ma bẹru lati jade dibo lọjọ kẹẹdogun oṣu yii tori ẹtọ wọn ni.
Mo ke pe Aarẹ Bola Tinubu lati dẹkun rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun, ileesẹ ọlọpaa ti gbabọde – Adeleke
Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Osun ti ke pe Aarẹ Bola Tinubu lati wa ojutuu si rogbodiyan ati ipaniyan to n lọ lọwọ nipinlẹ naa ṣaaju eto idibo gomina ọjọ kẹẹdogun ọsu yii.
Adeleke sọrọ yii niluu Osogbo nibi to ti n ṣe ipolongo ibo ni ijọba ibilẹ Olorunda.
Gomina ran Aarẹ Tinubu leti wi pe ẹgbẹ oṣelu oun, Accord, ti yan an gẹgẹ bi oludije ti wọn yoo dibo fun ninu ibo aarẹ ọdun 2027.
O rọ aarẹ lati ṣe ojuṣe baba ki o si fopin si iṣẹlẹ ipaniyan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Osun bayii.
Adeleke ko ṣai fi idi rẹ mulẹ pe awọn araalu yoo tako erongba ẹnikẹni to ba fẹ ṣe eeru ninu eto idibo to n bọ.
''Aarẹ Tinubu, nnkankan n ṣẹlẹ nipinlẹ Osun ti ẹ o tii fi opin si.
Ni ṣe ni wọn n ṣekupa awọn eeyan wa, ẹyin si ni aarẹ ati baba gbogbo wa.
Ipinlẹ Osun ti sọ pe awọn ko ni faye gba yiyi ibo, ẹ ranti nnkan to ṣẹlẹ lọdun 1983 o.
Ilẹ Yoruba ni o ti bẹrẹ lẹyin ti wọn ṣe eeru fun Bola Ige ati Adekunle Ajasin.
Osun ko ni i gba o, a fẹ ki eto idibo to n bọ lọ ni irọwọ rọsẹ.
Aarẹ Tinubu, ki lo de ti wọn tun n pa wa lẹyin ti a ti yan yin gẹgẹ bi oludije aarẹ ti a o dibo fun lọdun 2027?'' Adeleke sọrọ soke.
Gomina Adeleke fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa wi pe wọn n ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kan lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun.
O wa rọ ijọba apapọ lati dẹkun ipaniyan to n ṣẹlẹ ki iru rogbodiyan to ṣẹlẹ lọdun 1983 ma ba tun ṣẹlẹ.
''Emi atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo n fara kaasa rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun - Oyebamiji
Ẹwẹ, oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun, Bola Oyebamiji, ti ọpọ mọ si Ambo ti pariwo lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa ṣaaju eto idibo ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ to n bọ.
Oyebamiji ṣalaye pe ko din ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹẹdọgbọn to padanu ẹmi wọn ninu rogbodiyan to ṣẹlẹ sẹyin lọdun 2022 l'Osun.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ niluu Eko, Ambo ṣalaye pe kii ṣe ẹgbẹ oṣelu APC lo n da rogbodiyan silẹ kaakiri ipinlẹ Osun.
O ni ijọba to wa lori aleefa gan an lo n da ilu ru lati le dẹru bawọn araalu ki wọn ma ba le jade dibo.
Oludije sipo gomina fẹgbẹ APC sọ pe ''mo n fi asiko da awọn eeyan ipinlẹ Osun ati gbogbo ọmọ Naijiria loju wi pe emi atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo n fara kaasa rogbodiyan to n ṣẹlẹ l'Osun.
O le ni ọmọ ẹgbẹ APC mẹẹdọgbọn ti a gbọ pe ẹgbẹ oṣelu ijọba to wa lori oye ṣekupa lasiko eto idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2022.
Wọn ṣekupa alaga ijọba ibilẹ Irewole, Remi Abass, to jẹ ijọba ibilẹ temi gan an.
Bakan naa ni ẹgbẹ wa ni akọsilẹ oriṣiiriṣii ikọlu ati ipaniyan eyi ti a n beere pe ki idajọ ododo waye lori rẹ.
Eyi tumọ si pe ijọba to wa lori oye bayii nipinlẹ Osun lọwọ ninu rogbodiyan to n ṣẹlẹ bayii.
Laipẹ yii ti ọga agba ọlọpaa Naijiria ṣabẹwo si ipinlẹ Osun ni o sọ pe awọn janduku ọdaran kan ti ọlọpaa n wa sapamọ sile akọwe ijọba ipinlẹ Osun.
Bakan naa ni wọn tun ṣe ikọlu si awọn ọmọ ẹgbẹ wa niluu Ede to jẹ ilu Gomina Adeleke.''
Oyebamiji ko ṣai fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu APC ṣetan lati da ogo ipinlẹ Osun pada.































