Èèyàn lè gbé ẹ̀sìn lórí àmọ́ kí ìwà rẹ̀ burú – Ìyàwó Femi Adebayo tẹ́lẹ̀

Oríṣun àwòrán, Kemity Aunty Sidi
Iyawo Femi Adebayo tẹlẹ, Omotayo Sanusi, ti ọpọ mọ si Iyan Aladuke ti juwe ọdun mẹrin ṣeyin gẹgẹ bii eyii to fi ja ogun ti ko yẹ ko ja.
Omotayo lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Instagram rẹ ni iranti ayẹyẹ ọdun mẹrinlelogoji rẹ loke eepẹ.
Nigba to n sọrọ naa lori aworan kan to ni oun ya lọdun mẹrin ṣeyin, to jẹ ọdun to pe lẹni ogoji ọdun, o ni oun rope oun yoo bẹrẹ si n gbadun aye oun ni amọ ara ọtọ ni ọdun naa gba yọ fun oun.
Aladuke sọ pe nigba ti oun ko mọlẹbi oun wa siluu Eko lati maa gbe ninu ile nla kan, oun ro pe igbadun ti bẹrẹ niyẹn.
O ṣalaye pe akoko ti oun ro pe igbadun ti bẹrẹ loun bẹrẹ si n ni idojukọ to lagbara.
Bo tilẹ jẹ pe o ni ilọsiwaju de ba aye oun lasiko naa, kii ṣe gbogbo eeyan ni inu wọn dun si ilọsiwaju ọhun gẹgẹ bii oun ṣe lero ṣaaju.
Amọ ṣa, o ni ọdun mẹrin naa ti kọ oun ni ọpọ ẹkọ ti oun ko ni le gbagbe ni kankan.
Lara awọn ẹkọ na gẹgẹ bo ṣe ṣalaye ni pe ile aye ko ṣe e fi oju lasan gbe; ohun buburu maa n ṣẹlẹ si eeyan oninu ire; eeyan le gbe ẹsin lori amọ ki iwa rẹ buru; ọrẹ le da'ni; oogun abẹnu gọngọ wa, aye n bẹ, eeyan wa; ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ibaṣepọ oun ati Femi Adebayo
Ọjọ kẹsan an, oṣu Kẹwaa, ọdun 2016 ni Omotayo ati Femi Adebayo ṣe igbeyawo niluu Eko.
Bo tilẹ jẹ pe Adebayo ni oun ko fẹ ki oju wa lara iyawo oun, ọpọ eeyan lo pada mọ arabinrin naa ti wọn si maa n fi ifẹ han si ara wọn ni gbangba.
Ọdun 2025 ni iroyin gbode pe igbeyawo oun Adebayo ti daru.
Ninu oṣu Kinni ọdun 2026, Omotayo fẹsun kan Adebayo pe o le oun ati iya oun jade kuro ninu ile kan ti ile ounjẹ rẹ, Iyan Aladuke wa.
Amọ mọlẹbi Adebayo fesi pe iṣẹ ọwọ ile ifowopamọ ni iṣẹlẹ naa, kii ṣe iṣẹ ọwọ Adebayo.
Lẹyin naa ni iroyin tun gbode pe awọn oṣere tiata meji, Toyin Abraham ati Funke Akindele wa lara awọn to da igbeyawo awọn mejeji ru.
Amọ nigba ti yoo di inu oṣu Keje, ọdun 2026, Omotayo sọ nita gbanga ori ayelujara pe Toyin Abraham ko ni nnkankan lati ṣe pẹlu ẹsun ti wọn fi kan an.



























