Owó tí àwọn ọmọ Naijiria ń ná láti wọ ọkọ̀ kò pọ̀ tó ti àtijọ́ mọ́ – Tinubu

Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Aarẹ Naijiria ti sọ pe awọn araalu to n gbe lawọn ipinlẹ ti wọn ti n lo gaasi CNG ko na owo to pọ to ti atijọ mọ lori ọkọ wiwọ.

Tinubu lo sọ ọrọ yii ninu atẹjade kan pe bẹrẹ lati ọjọ Kinni, oṣu Kẹwaa, awọn araalu yoo bẹrẹ si n janfani owo ti ko pọ lori ọkọ wiwọ mọ labẹ eto National Affordable CNG Transit Programme.

O ni eto naa waye lẹyin ipade to ṣe pẹlu gbogbo awọn gomina mẹrindinlogoji to wa ni Naijiria lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹjọ, nibi ti wọn ti fẹnuko lori ọna ati din iye ti araalu n na lori ọkọ wiwọ ku.

Tinubu sọ pe igbimọ ti yoo jẹ ki eto naa ṣe aṣeyọri ti wa ni ikalẹ labẹ idari alaga ẹgbẹ awọn gomina, AbdulRahman AbdulRazaq.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, igbimọ naa, iyẹn PI-CNG & EV, awọn gomina atawọn ti ọrọ naa kan ti bẹrẹ iṣẹ lori igbesẹ ọhun.

O fi kun pe igbesẹ naa ṣe pataki ni bayii ti epo ti n gbowo lori kaakiri agbaye, ati pe o ṣeeṣe lati din ti iye ti araalu n na lori ọkọ ku nipasẹ CNG.

O ni "Ni Borno, awọn ọkọ akero to n lo CNG ti n gbe awọn eeyan ni ₦50 si ₦100 lọ si awọn ibi ti ọkọ igboro n gbe wọn lọ ni ₦300 si ₦600 tẹlẹ."

Aarẹ fi kun pe ọkọ akero to n lo CNG ti n gbe awọn eeyan lọfẹ lawọn agbegbe kan ni Kaduna, o si ti gbe eeyan to le ni miliọnu mẹta lọdun kinni to bẹrẹ iṣẹ, to n tumọ si pe o ti gba araalu lọwọ inawo ti iye rẹ to ₦3.5b.

Tinubu tun mẹnuba ọkọ akero CNG ti ijọba gbe fun Pacesetter Transport nipinlẹ Oyo, eyii to din owo ọkọ araalu ku lati ₦8,000 si ₦3,200.

Nipinlẹ Adamawa, Aarẹ sọ pe lilo ọkọ akero CNG ti din owo ọkọ ku lati ₦8,000 si ₦4,000.

Tinubu ni ijọba oun yoo tẹsiwaju lati maa ṣe awọn ohun ti yoo mu aye dẹrun faraalu lasiko oun lori oye.