Wo awọn Sẹnetọ ti wọn ko tii gbe aba kankan lọ sile igbimọ asofin Naijiria lati 2023

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate/Facebook
Ajọ to n ṣagbeyẹwo akọsilẹ ati bi nnkan se n lọ ninu ilana orileede ati agbaye, iyen StatiSense ti ṣe akọsilẹ orukọ awọn asofin agba Naijiria ti wọn ko tii gbe aba kankan lọ sile igbimọ asofin latigba ti wọn ti wa nipo.
StatiSense gbe orukọ awọn aṣofin agba ti wọn jẹ ọkunrin ati obinrin, ti wọn ko tii gbe aba kankan, ti awọn aṣofin yoo jiroro le lori tabi ṣagbeyẹwo rẹ.
Ọdun 2023 ni eto idibo to gbe awọn aṣofin Kẹwaa wọle sipo, ti wọn si ti lo to ọdun mẹta oṣu mẹfa bayii.
Akọsilẹ StatiSense ṣafihan akọsile ọhun lati ọdun 2023 titi di oṣu Kọkanla, ọdun 2026.
Awọn sẹnetọ wo ni?
Ninu akọsilẹ ti StatiSense gbe soju opo wọn laipẹ yii, awọn alakoso naa tọka si sẹnetọ mẹjọ, pẹlu ẹkun ti wọn n ṣoju.
Awọn naa ni:
Nwachukwu Emmanuel to n ṣoju ekun Guusu Anambra South
Abdulaziz Abubakar Yari to n ẹkun Ila-Oorun Zamfara
Ahmad Ibrahim Lawan to n ṣoju ekun Ariwa Yobe North
Olaka Nwogu to n ṣoju ẹkun Guusu Ila-Oorun Rivers
Dayo Faduyile to n ṣoju ẹkun Guusu Ondo
Jiya Peter Ndalikali to n ṣoju ẹkun Guusu Niger
Ikeje Israel Asogwa to n ṣoju ẹkun Ariwa Enugu
Danladi Envulu-Anza, to n ṣoju ẹkun Ariwa Nasarawa.
Ajọ naa wa fidi rẹ mule akọsilẹ yii ko ni ohunkohun lati ṣe pelu oniruuru iṣẹ ati igbesẹ ti wọn ti gbe nipa didasi ọrọ nile igbimọ naa.
Awọn obinrin to dije fun ipo sẹnetọ lọdun 2023
Siwaju sii ni akọsile ọhun tun ṣafihan awọn akojọpọ obinrin to dije fun ipo sẹnetọ kaakiri ẹkun nilẹ Naijiria lọdun 2023.
Awọn naa ni Ẹkun:
Guusu Guusu - oludije mejilelogun
Guusu Iwọ-Oorun - oludije mọkanlelogun
Ariwa Ila-Oorun - oludije mọkanlelogun
Guusu Ila-Oorun - oludije mẹrindinlogun
Aarin Gbungbun Ariwa - oludije mẹwaa
Ariwa Iwọ-Oorun - oludije meje
Gbogbo ẹkun guusu mẹtẹẹta ni wọn ni akọsilẹ obinrin mọkandinlọgọta lapapọ, leyi to ṣafihan ida ọgọta le mẹjọ (60.8%) gbogbo awọn metadinlọgọrun-un lapapọ kaakiri Naijiria.
Ẹkun Guusu Iwọ Oorun ni akọsile perete pẹlu oludije meje pere.
Ẹkun Guusu Guusu ni oludije mejileleogun, nigba ti awọn ẹkun Guusu Iwọ-Oorun ati Ariwa Ila-Oorun ni oludije mọkanlelogun ati mọkanlelogun.
Awọn sẹnetọ ti wọn ti gbe aba to pọ lọ sile igbimọ aṣofin agba lati ọdun 2023
Laaarin oṣu Kẹfa, ọdun 2023 si oṣu Kọkanla, ọdun 2026, ko din ni sẹnetọ mẹrinla ti wọn ti gbe aba lọ sile igbimọ aṣofin.
Apapọ aba naa lo jẹ marundinlọgbọn, ti wọn si ti ṣe agbeyẹwo pupọ ninu rẹ, koda ti awọn miran ti di ofin lati tẹle.
Sẹnetọ Michael Opeyemi Bamidele – Aba mẹsan
Sẹnetọ Barau I. Jibrin – Aba mẹta
Sẹnetọ Adeola Solomon Olamilekan – Aba meji
Sẹnetọ Joel-Onowakpo Thomas Ewomazino – Aba kan
Sẹnetọ Fadeyi Oluwole Olubiyi – Aba kan
Sẹnetọ Mohammed Sani Musa – Aba kan
Sẹnetọ Ikra Aliyu Bilbis – Aba kan
Sẹnetọ Umar Shehu Buba – Aba kan
Sẹnetọ Sani Bello Abubakar – Aba kan
Sẹnetọ Ekpenyong Asuquo – Aba kan
Sẹnetọ Mukhail Adetokunbo Abiru – Aba kan
Sẹnetọ Patrick Ndubueze – Aba kan
Sẹnetọ Abdulhamid Mallam-Madori Ahmed – Aba kan
Sẹnetọ Jibrin Isah – Aba kan
Apapọ awọn aba naa jẹ marundinlọgbọn, to si jẹ pe pupọ ninu rẹ ni Aarẹ ti buwọ lu, leyi ti ida mẹrindinlogoji ninu wọn jẹ eyi ti Sẹnetọ Michael Opeyemi Bamidele gbe dide.
Bakan lo jẹ pe awọn sẹnetọ mẹta mu ida mẹrindinlọgọta.
Awọn sẹnetọ mọkanla yooku ni wọn ni abakọọkan.


























