Ijó ló ń jó ló báṣubú lulẹ̀! Awuyewuye lórí ohun tó fa bí obìnrin kan ṣe ṣubúlulẹ̀ níbi tó ti ń jó lóde àríyá

Obinrin to n jo lọwọ to ku loju agbo
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ohun kan naa ni yoo jẹ aṣegbẹyin fun ẹda nigba ti iku ba de, ohun ti yoo jẹ ko ye eeyan, ibi ti iku yoo si ka kaluku mọ ko han sẹnikan.

Latigba ti fidio to ṣafihan obinrin kan to n jo lọwọ to si mu ẹyin relẹ, to ku lagbo ijo ti jade lori ayelujara ni ọpọ eeyan ti n sọ ohun ti wọn ro pe o le ṣokunfa iku naa.

Bawọn kan ṣe n sọ pe ara obinrin naa le, nnkan kan ko ṣe e tẹlẹ lo ṣe le fi gbogbo ara jo lode ariya, bẹẹ lawọn kan n sọ pe o le jẹ aisan ẹjẹ riru wa lara rẹ, tabi ko jẹ ṣuga ara rẹ lo deede lọ silẹ lojiji to si mu iku wa.

Ki lohun to ṣẹlẹ gan-an?

Ninu fidio to lu ori ayelujara pa l'Ọjọru, ọjọ kejidinlogun oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii, obinrin kan n jo kikankikan lode ariya.

Aṣọ Ankara alawọ ewe ti wọn mu lode naa lo wọ, o fi yẹri seti pẹlu ẹgba ọrun, eeyan ko si le sọ pe aarẹ kankan wa lara rẹ bo ṣe n fi idunnu jo si orin Fuji to gba ode naa kan.

Lasiko kan, obinrin to n jo naa ko ijo ọhun mọlẹ, bẹẹ lo n rẹrin-in, awọn ti wọn jọ wa loju agbo naa si n ki i bo ṣe n ra ijọ naa ni mẹlọmẹlọ.

Nibi ti iya to n jo yii ti ko ijo mọlẹ naa lo ti mẹyin lọ silẹ, o ṣubu sọwọ ẹyin lai ṣe pe ẹnikẹni de ọdọ rẹ tabi ti I ṣubu.

Eyi lo mu oju agbo naa daru, awọn to n fidio ijo ọhun paapaa ko ri nnkan kan ka silẹ mọ bi ko ṣe irọgiri lati gbe iya naa dide.

Bawọn kan ṣe n sọ pe ki wọn gbe omi wa ni awọn kan n pe orukọ Jesu, ẹnikan si fi orukọ ọmọ obinrin naa pe e, o ni: Iya Kabira, dide."

Amọ obinrin to n jo niṣẹju diẹ ṣaaju naa ti di oku, ko le dide mọ, bẹẹ lo si ṣe gba oju agbo ijo de ajule ọrun.

A gbọ pe ilu Ibadan ni iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ, bẹẹ lo si n jẹ kayeefi gidi fawọn eeyan to mọ obinrin naa ati bo ṣe tán si agbo faaji.

Ki lo le fa ki eeyan deede ṣubu lulẹ ko si ku?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lati ṣalaye ohun to ṣee ṣe ko fa iru iku yii, BBC News Yoruba kan si Dokita John Omotoso, Aarẹ ẹgbẹ awọn Dokita ni Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital, Sagamu, ipinlẹ Ogun, o si ṣalaye pe:

"Emi naa ri fidio obinrin yẹn, ohun to le fa ki ẹni to n jo lọwọ deede ṣubu lulẹ ko si ku pin si meji si mẹta.

" Eyi to wọpọ ju ni eyi ti a n pe ni Heart attack, ti ọkan to n gbe ẹjẹ yoo deede duro.

"Lọpọ igba, o le ma fun eeyan ni ami kankan, paapaa nigba ti eeyan ba n ṣiṣẹ agbara lọwọ tabi to n mu ki ohun to n pin ẹjẹ sita maa ṣiṣẹ agbara.

"Ti a ba n ṣiṣe, gun oke, ti a n jo, ti a n sare, bi ọkan wa ṣe maa n gbe ẹjẹ jade maa n po si i.

"O le jẹ ọkan to funra ẹ ti ṣeṣe tẹlẹ, to jẹ ọkan to nilo ẹjẹ funra ẹ tẹlẹ, eyi lo maa n ṣe awọn ti ifunpa wọn ga, tabi awọn ti kindinrin wọn ko ṣiṣẹ daadaa.

"Ṣugbọn nitori ki I saaba jẹyọ gboogi, ti ki I ṣe pe eeyan ko ni le dide, ọpọlọpọ igba lawon eeyan maa n foju fo o, eeyan le maa sọ pe stress ni, igba to ba wa nilo ẹjẹ ti ẹjẹ yẹn o wa to, o le fa iku.

Ẹni to n jo yẹn, iṣẹ agabra lo n ṣe, bi idaraya ni.

Dokita Omotoso sọ pe ọkan yẹn n ṣiṣẹ gbii gbii gbii, ọkan yẹn funra ẹ si nilo ẹjẹ lati le ṣe ohun ti ẹni to n jo yẹn n ṣe.

O ni o ṣee ṣe ki ọkan yẹn ti ni aṣiṣe kan tẹlẹ, ṣugbọn ti ẹjẹ ko tun wa to si ọkan naa, o le fa ki ọkan da iṣẹ ṣilẹ.

"Ko sibi ti iru iku yii ko ti le ṣẹlẹ, tiṣa ti ku si yara ikawe ri, bẹẹ ni dokita ti ku si tiata to ti n siṣẹ abẹ ri"

Dokita Omotoso sọ pe ko sibi ti eyi ko ti le ṣẹlẹ.

O ni:

Ti patí la ri, ti olukọ to n kọ awọn akẹkọọ lọwọ nkọ, to ku sibẹ, ti dokita to n tọju eeyan lọwọ n kọ to dakẹ sinu tiata."

Dokita Omotoso sọ pe ti iru ẹ ba ṣẹlẹ, ọna abayọ lo yẹ ki eeyan wa.

"Ti iru ẹ ba ṣẹlẹ, ọna jiji oku pada ta a mọ si CPR (Cardiopulmonary resuscitation) lo yẹ kawọn to wa nitosi wa.

"O dun mi pe awon to wa nitosi obinrin yẹn ko mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe niru iṣẹlẹ bẹẹ.

"To ba ṣẹlẹ, ki ẹ tẹ ẹni naa silẹẹlẹ ni, kẹ ẹ kọkọ wo o pe ṣe o n mi, ti ko ba mi mọ, ẹ tete pe fun iranlowo, kẹ ẹ si ṣe CPR.

Iru imọ yẹn la nilo, o ni ibi ti wón a maa tẹ nibi ọkan ẹ , ti wọn a maa fẹ atẹgun si I lati ẹnu lati ri I pe ẹdọforo rẹ ran an lọwọ lati mi.

"Awọn ẹkọ to yẹ ki awujó wa mọ niyẹn, ki I ṣe fun awọn dokita nikan, o dun mi pe o ṣi n ri bayii lorilẹede wa."

Bẹẹ ni Dokita Omotoso wi.

O fi kun un pe ayẹwo oku ta a mọ si Autopsy lo maa jẹ ki wọn mọ ẹya ara pato ti wahala ba lara obinrin to n jo naa to fi ja siku.