Ìjọba UK kéde ohun mẹ́rin tí o gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún tóo bá fẹ́ gba físà kóo má baà kó sọ́wọ́ oníjìbìtì

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti kede ohun mẹrin ti awọn eeyan gbọdọ ṣọra fun lasiko ti wọn ba n kọwe fun fisa ilẹ naa ki wọn ma ba a ko sọwọ awọn onijibiti.
Ọọfisi to n ri si ọrọ fisa ọhun, UKVI, lo fi ikilọ naa lede loju opo X rẹ, to si rọ wọn pe ki wọn ṣọra.
Ninu atẹjade naa wọn ni "Eyii ni awọn nnkan mẹrin ti ẹ gbọdọ ṣọra fun ti ẹ ba n kọwe fun visa. Daabo bo ara rẹ lọwọ jibiti to n waye nidi fisa nipa kikọ ẹkọ nipa awọn ohun ti a gbe jade yii."
Ohun mẹrin ti o gbọdọ ṣọra fun ti o ba fẹ gba fisa
- UKVI sọ fun awọn eeyan ki wọn ṣọra fun awọn to n ba eeyan ṣe fisa pẹlu ileri wọn maa riṣẹ ni UK lai si aniani.
- Ti ẹni to ba n ọ ṣe fisa ba fun ọ ni ọjọ ti fisa naa yoo jade amọ ti o ko le fidi ọrọ naa mulẹ loju opo ajọ UKVI.
- Ti awọn ẹni ti o k mọ ba n bere owo lọwọ rẹ tabi ti wọn ba n bere iroyin to ṣe koko nipa rẹ lọwo rẹ.
- Ohun ẹkẹrin ti wọn ni ki awọn eeyan sọra fun ni ti ẹnikẹni ba fun wọn ni iwe kankan to si n sọ pe fisa wọn daju pẹlu irufẹ iwe bẹẹ.

Oríṣun àwòrán, @UKVIgovuk
Awọn ikilọ mii lati akata ijọba UK
Lọdun 2025 nikan, iwadii fidi rẹ mulẹ pe iye owo to le ni biliọnu mọkandinlogun naira ni wọn gba awọn ọmọ Naijiria to fẹ gba fisa ilẹ okere.
Yatọ si awọn nnkan to wa loke yii, UKVI tun tẹnumọ pe awọn kọlọrọsi kan maa n gba owo lọwọ awọn eeyan pẹlu ileri pe wọn maa ba wọn ṣe nnkan ti fisa wọn fi tete jade.
Wọn ni "Awọn oṣiṣẹ fisa wa ko ni bere owo lọwọ yin lojukoju, lori atẹjiṣẹ email tabi lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ lailai."
UKVI tun ṣalaye pe awọn kii gba owo fisa lati ori atẹjiṣẹ email tabi si apo banki eeyan kankan.
Ijọba ilẹe Gẹẹsi wa rọ gbogbo awọn to ba fẹ gba fisa ki wọn ṣe bẹẹ loju opo ti ijọba ilẹ Gẹẹsi ti la kalẹ fun eto naa nikan ṣoṣo.
Lori lilo ayederu iwe, UKVI sọ pe awọn ko ni fun ẹnikeni to ba lo ayederu iwe ni fisa, bẹẹ ni wọn le fofin de irufẹ ẹni bẹẹ ko ma le wọ UK fun odidi ọdun mẹwaa gbako.
Lẹyin naa ni wọn rọ awọn eeyan ki wọn ma fun ẹnikẹni ni iroyin kankan nipa ara wọn, paapaa ti wọn ba fura pe onijibiti ni irufẹ ẹni bẹẹ.
Wọn tun wa rọ araalu ki wọn fi to awọn leti ti wọn ba kofiri jibiti fisa ilẹ naa.



























