Ṣé lóòótọ́ ni wọ́n yan Rotimi Okpaise gẹ́gẹ́bí adarí tuntun ijọ Fountain of Life Church lẹ́yìn yíyọ Jimmy Odukoya, àti pé kí ló kan Kunle Areogun nínú gbas-gbos yìí

Oríṣun àwòrán, Church gist/Ethnic African Stories/Jimmy Odukoya
Awọn igbimọ majẹobajẹ ileejọsin Fountain of Life Church ti wọn yọ oluṣọaguntan agba ijọ naa kuro nipo lọjọ Iṣẹgun ti wa yan oludari tuntun fun ijọ naa bayii.
Oluṣọaguntan Rotimi Okpaise ni oludari tuntun ti wọn yan fun ijọ ọhun, ti wọn si ni yoo di ipo naa mu gẹgẹbi adari fidihẹẹ titi di igba ti ohun gbogbo yoo to pada.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita, eleyii ikannni 'Church Gist fi sita ṣalaye pe igbimọ naa fidi rẹ mulẹ pe awọn ṣi duro lori ipinnu wọn lati yọ Jimmy Odukọya nipo gẹgẹbi oludari agba ijọ naa.
Wọn ni Pasitọ Okpaise ni yoo maa mojuto akoso ati iṣẹ isin ijọ naa.

Oríṣun àwòrán, Church Gist
Wọn ni awọn ko ri Pasitọ Odukọya gẹgẹbi oludari ijọ naa mọ, nitorinaa ko fi ipo naa silẹ lẹyẹ o ṣọka.
Gẹgẹ bii atẹjade Church Gist, Rotimi Okpaise jẹ ọkan lara awọn oluṣo agutan agba ninu ijọ naa ṣaaju iyansipo rẹ gẹgẹ bii adari fidihẹ lẹyin ti wọn yọ Jimmy Odukoya nipo.
Iroyin ni o ko ipa ribiribi ninu iyansipo Jimmy lati gba ọpa aṣẹ ijọ ọhun lọdun 2023 ki wọn to yọ ọ ni 2026.
Ta ni pasitọ Kunle Areogun ti Taiwo Odukoya n fẹ ko rọpo rẹ?

Oríṣun àwòrán, Ethnic African Stories
Lati igba ti gbogbo awuyewuye lori yiyọ ti awọn agbaagba majọobajẹ ijọ Fountain of Life Church kan ti yọ Pasitọ Jimmy Odukọya nipo gẹgẹbi oluṣọaguntan agba ijọ naa ni orukọ Pasitọ Arẹogun ti bẹrẹ si ni ja ranyinranyin kaakiri bayii.
Ninu fidio kan ti oludasilẹ ijọ naa, Pasitọ Taiwo Odukọya ṣe silẹ, eyi ti wọn ni o ka silẹ loṣu kẹjọ ọdun 2021 ki o to wa ku ni ọdun meji lẹyin rẹ lo ti sọ pe ẹni ti oun fẹ ko di alufaa agba ijọ naa 'bi oun ba ku tabi ti nnkankan ba ṣẹlẹ ti oun ko le sọrọ tabi kọwe', ni Pasitọ Arẹogun. o tẹsiwaju ninu fidio naa lati sọ wi pe augbalẹgbẹ ni ki ọmọ oun Jimmy Odukọya jẹ fun un, ko si tun maa ṣe adari ẹka awọn ọdọ.
Amọṣa ibeere ti ọpọ wa n beere bayii ni pe, ta gan ni Pasitọ Arẹogun?
Eyi lawọn ohun to yẹ lati mọ nipa pasitọ naa:
1. Pasitọ to ti pẹ ninu ijọ Fountain of Life Church ni
Kunle Areogun jẹ ọkan gboogi lara awọn pasitọ agba ijọ Fountain of Life Church niluu Eko, o tun jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu iṣẹ amojuẹrọ to yan laayo.
Ileeṣẹ iroyin Church Gist jabọ pe Areogun ti wa pẹlu ijọ naa fun ọpọ ọdun.
Ninu awọn akọsilẹ iwaasu ijọ naa, a ri pe o ti n waasu nibẹ lati ọdun 2017.
Onimọẹrọ nipa apopọ kẹmika ni, o si ti ṣiṣẹ daadaa lẹka epo rọbi
Yatọ si iṣẹ oluṣọaguntan to gba, Pasitọ Arẹogun tun jẹ akọṣẹmọṣẹ onimọẹrọ pọnbele.
Gẹgẹ bii atẹjade Church Gist, o kawe nile ẹkọ Obafemi Awolowo University (OAU), to wa niluu Ile-Ife, laarin ọdun 1982 si 1987.
Yatọ si eyii, o tun n ṣiṣẹ ni ẹka epo rọbi.
O ti fi akoko igba kan ṣiṣẹ gẹgẹ bii ọga nileeṣẹ Bourbon Interoil Nigeria Limited ri.
Lara awọn ileeṣẹ mii to ti ṣiṣẹ ni Transcoastal Marine Limited (1998–2001), Sirpi Alusteel Construction Nigeria Limited (1993–1998), ati Consultant International Ltd (1988–1992).
Pasitọ Arẹogun ti le ni ọgọta ọdun
Bi Pasitọ Arẹogun kii ṣe e ṣe ọmọde ninu iṣẹ iranṣẹ naa ni kii ṣe ọmọde ni ti ọjọ ori.
Ni oṣu kẹjọ ọdun 2024 lo ṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọgọta ọdun
Gbas-gbos nílé Olúwa! Ìgbìmọ̀ ìjọ Fountain of Life Church yọ Pásítọ̀ Jimmy Odukoya, àmọ́ ó takú pé òun kò lọ

Oríṣun àwòrán, x/Jimmy Odukoya
Iroyin kan jade lowurọ ọjọ Iṣẹgun eyi to tọ̀ka si atẹjade kan ti awọn kan ti wọn pe ara wọn ni igbimọ majẹobajẹ ijọ Fountain of Life Church nilu Eko ninu eyi ti wọn ti n kede pe wọn ti yọ oluṣọ aguntan ijọ naa, Pasitọ̀ Jimmy Odukọya nipo.
Ohun ti igbimọ naa n sọ̀ ni pe ilana ti baba pasitọ naa, Pasitọ Taiwo Odukọya to da ijọ naa silẹ fi silẹ tako iyansipo rẹ gẹgẹbi iku rẹ.
Ki lawọn idi ti igbimọ naa la kalẹ fun yiyọ Pasitọ Jimmy Odukọya?

Oríṣun àwòrán, Jimmy Odukoya/x
Awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ naa ṣalaye ninu atẹjade wọn ọhun pe awọn ti ri fidio kan ti baba oluṣọaguntan naa fi silẹ ki o to ku ninu eyi ti wọn ni awọn rii pe ọtọ ni ojuṣe ti baba oluṣọaguntan naa yan fun un lẹyin iku rẹ.
Gẹgẹbi igbimọ naa ṣe sọ, wọn ni ohun ti oludasilẹ ijọ naa sọ ninu fidio ọhun ni pe ẹlomiran ni ko jẹ oludari ati pasitọ agba ijọ naa lẹyin iku rẹ. Wọn ni, ninu fidio naa ti Pasitọ Taiwo Odukọya ka silẹ ni oṣu kejila ọdun 2021, ohun to sọ ni pe ipo amugbalẹgbẹ fun ẹni to yan gẹgẹbi oluṣọaguntan lẹyin ara rẹ ni Oloogbe Pasitọ Taiwo Odukọya ni ki ọmọ rẹ dimu, ki o si maa dari ẹka awọ̀n ọdọ ni ijọ naa.
Wọn ni iroyin to wa ni arọwọto awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ yii nigba ti baba rẹ ku lọdun 2023 ni wọn fi yan Pasitọ Jimmy Odukọya gẹgẹbi pasitọ agba ijọ naa nigba naa.
Idi miran ti wọn tọka si ni awọn abala kan ninu iwe ofin ile ijọsin naa.
Bakan naa ni wọn tun kọminu lori igbeyawo ti pasitọ naa ṣe laipẹ yii lẹyin to kọ iyawo rẹ akọkọ silẹ eleyi ti wọn ni o tako ẹkọ ati ohun ti awọn to da ijọ naa silẹ fi lelẹ. Wọn ni ko si tun ba ilana adari nipa ẹmi mu.
Awọn ọmọ igbimọ Majẹobajẹ naa ni igbesẹ yii ti n mu ẹrẹ ba ijọ naa.
"Nitori eyi, Pasitọ Jimmy Odukọya kii ṣe oluṣọaguntan agba ijọ Fountain of Life Church mọ."
'Jimmy odukọya ṣi ni oluṣọaguntan ijọ wa, awọn kọlọransi ọmọ igbimọ majẹobajẹ lo wa nidi ikede yíyọọ́ nipo'

Oríṣun àwòrán, Taiwo & Bimbo Odukoya/x
Wayii o ninu atẹjade mira to jade loju opo ayelujara ijọ naa ni ọsan ọjọ Iṣẹgun, ijọ naa sọ pe ko si otitọ ninu iroyin to n sọ pe wọn ti yọ Pasitọ Jimmy Odukọya nipo gẹgẹ bi oluṣọaguntan agba ijọ Fountain of Life Church.
Atẹjade ọhun sọ pe awọn kọlọransi kan ninu igbimọ majẹobajẹ inu ijọ naa ni wọn wa nidi ikede naa.
Atẹjade naa sọ pe lati oṣu kẹta ọdun 2026 ni wọn ti paṣẹ fun awọn ọmọ igbimọ majẹobajẹ yii lati kọwe fi ipo wn silẹ nitori ohun ti atẹjade naa pe ni 'ṣiṣe lodi si iwe ofin ijọ naa'.

























