Gbajúmọ̀ òṣèré, Ọmọ Iyabo Ogunsola Ẹfúnṣetán jáde láye

Oríṣun àwòrán, others
Iku doro, iku tun ti se ika, iku tun ti mu gbajumọ osere tiata mii lọ.
Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni yajoyajo ti fidi rẹ mulẹ gbajumọ osere tiata, Ọmọwe Olatunde Ogunsola-Oluyemi ti jade laye.
Olayemi jẹ ọkan lara ọmọbinrin ti gbajugbaja osere tiata, Ishola Olusola Ogunsola fi silẹ saye lọ.
Bakan naa ni oloogbe tun jẹ gbajumọ osere tiata, Iyabo Ogunsola, ti ọpọ eeyan mọ si Efunsetan bi.
Nigba to n fi idi isẹlẹ iku oloogbe Oluyemi mulẹ fun BBC News Yoruba, ọkan lara ọmọ Isola Ogunsola, Isho Senior salaye pe ana ọjọ Aiku ni obinrin naa mi kanlẹ.
Ishow Senior ni "Aisan lasan lo se, amọ o jade laye ni ọjọ Aiku ana."
Ọpọ awọn osere tiata si lo ti n se idaro iku obinrin naa.
Oloogbe naa, ti ọpọ eeyan n pe ni Aunti Tunde tabi Mummy Iwa ni wọn si sapejuwe bii ololufẹ ọmọnikeji ati oniwa tutu.

Oríṣun àwòrán, wumiolabimtan\Instagram
Bakan naa ni ọrẹbinrin oloogbe naa lagbo tiata, Wumi Olabintan, loju opo ayelujara Instagram rẹ kede iku oloogbe Oluyemi.
Gẹgẹ bi Olabimtan ti wi, iku oloogbe naa ya pupọ, to si nira fun oun lati ki pe o kigbose lasiko yii.
"Ẹgbọn mi, ọrẹ mi, alabaro mi, ẹni to se iyebiye si ọkan mi, korofo lasan nile aye yii lai jẹ pe ẹ wa nibẹ.
Ẹ maa sun lọ laya Olugbala titi ti a fi pade."
Gbajumọ osere tiata, Ayoola Oluyemi ni ọkọ oloogbe naa, ti ọba oke si fi ọmọ mẹta ta wọn lọrẹ.


























