Èèyàn mẹ́tàdínlógún jáde láyé báwọn agbébon ṣe ṣíná ìbọn bolẹ̀ fáwọn èrò inú ọkọ̀

Awọn ero to pọ to n ṣe idaro iṣẹlẹ laabi
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa South Africa ni awọn ti bẹrẹ iwadii lori iku eeyan mẹtadinlogun ti wọn ṣekupa bi awọn kan ṣe sina ibọn bolẹ lorilẹ ede naa.

Eeyan mẹjọ ni wọn far agba ọta ibọn yannayanna ni ẹkun KwaZulu-Natal tawọn ọlọpaa si kede pe awọn eeyan naa ti jade laye nigba ti wọn fi maa de ibẹ.

Lẹyin wakati diẹ ni wọn tun ṣawari eeyan mẹsan-an mii tawọn naa tun fara gbọta ni ẹkun iwọ oorun Pretoria.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn iṣẹlẹ naa ko ni ohunkohun ṣe pẹlu ara wọn ati pe wọn ko le fidii ohun to ṣokunfa ipaniyan naa mulẹ.

South Africa n koju ipenija nla lati gbogunti iwa ọdaran ni orilẹ ede naa to fi mọ bi awọn ọmọ ganfe ṣe maa n pa ara wọn.

O wa lara awọn orilẹ ede ti ipaniyan ti maa n waye julọ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn gba ipe pe wọn n yinbọ ni ilu Pietermaritzburg KwaZulu-Natal ti wọn si ri ọkọ kan to le gba eeyan meji ti wọn ti fi ọta ibọn ba gbogbo ara rẹ jẹ.

Awọn ọkunrin meje lo wa ninu ọkọ naa pẹlu ọgbẹ ọta ibọn lara.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, Robert Netshiunda sọ pe awọn ko i tii le sọ bi iṣẹlẹ naa ṣe waye, ti awọn si ti n ko ẹri jọ lati mọ ohun to ṣokunfa ipaniyan ọhun ati lati ṣawari awọn to wa nidii ikọlu naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori awọn to ṣiṣẹ ibi naa.

Àwọn ìgbà tí ìkọlù tún ti wáyé

Ko din ni oku eeyan mẹsan ti awọn ọlọpaa ṣawari wọn agbegbe Jeffville to wa ni Atteridgeville, ẹkun Iwọ-Oorun Pretoria tii ṣe ọkan lara awọn ilu to gbajumọ ni South Africa.

Iro ibọn lawọn eeyan n gbọ, to jẹ ki onikaluku sa asala fun ẹmi ara wọn, ṣugbọn ọkunrin mẹfa, ati obinrin mẹta ba ikọlu naa lọ.

Inu yara mẹrin ni wọn pa awọn eeyan naa si ni nnkan bi agogo mẹwaa ati mọkanla alẹ ọjọ Aiku.

Niṣe ni oku awọn eeyan naa wa nilẹ kaakiri awọn inu yara ọhun, pẹlu awọn ọta ibọn to wa nilẹ kaakiri.

Awọn ara adugbo sọ pe niṣe lawọn kọkọ ro pe ara lo san, lai mọ pe ikọlu ibọn ni.

"Ọga ọlọpaa ẹkun Gauteng ti ko awọn ọmọ ogun lọ sibẹ lati gbe igbesẹ to yẹ, to fi mọ awọn oniṣẹ iwadii nileṣẹ ọlọpaa lati rọwọ to awọn afurasi to ṣiṣẹ naa," agbẹnusọ ọlọpaa, Brigadier Brenda Muridili sọ bẹẹ.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n ti pa àwọn èèyàn

Kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn yoo maa yinbọn lọpọ lati gbẹmi awọn eeyan ree lagbegbe naa.

Ninu oṣu Kinni, ọkunrin marun-un ni wọn yinbọn pa mọ inu ṣọọbu itaja kan lọsan gangan.

Pupọ awọn eeyan lo n gbe ibọn kaakiri lọna aitọ, to si n pọ lojoojumọ, eyi to n jẹ ki wọn maa yinbọn pa awọn eeyan ni gbogbo igba.

Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹsan, eeyan meji ni wọn yinbọn pa lagbegbe ọtọọtọ.

Bakan naa, lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹsan, awọn eeyan mejidinlogun ni wọn yinbọn ba nile faaji kan to wa nitosi Johannesburg. Awọn eeyan mẹrinla lo farapa yannayanna lọjọ naa.

Ko tan sibẹ, lọjọ keji ni wọn tun pa eeyan mẹwaa niwaju ita ile igbafẹ kan lasiko ti wọn n ṣe faaji lọwọ nitosi Cape Town, nibẹ si lawọn mọkanla ti farapa.

Awọn ikọlu yii la gbọ pe o n waye laaarin awọn ẹgbẹ awọn to n gbe egboogi oloro ati awọn to n wa kusa lọna aitọ.

Ninu oṣu Keji, Aarẹ Cyril Ramaphosa ṣapejuwe awọn iwa ọdaran naa gẹgẹ bi eyi to n dunkooko mọ eto oṣe awa-ara-wa, ayika ati idagbasoke eto ọrọ aje wọn.

Ni ibẹrẹ ọdun yii, ileeṣẹ ologun ko awọn ọmọ ogun rẹ sita, bẹẹ naa lawọn ọlọpaa ko oṣiṣẹ sita si ẹkun nla marun-un, to fi mọ Gauteng, lati le gbogun ti oniruuru iwa ọdaran.

Gẹgẹ bi ohun ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ, awọn to din diẹ ni ẹgbẹrun marun ataabọ (5,427) ni wọn pa kaakiri orileede naa laaarin oṣu Kẹrin si Kẹfa, ọdun 2026.

Ọlọpaa ni ko din ni ọgọta eeyan ti wọn n pa lojumọ.