Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Danielle Adewusi, ọmọ Nàíjíríà tó gba Miss Universe

Oríṣun àwòrán, danielle_adewusi/Instagram
Gbajugbaja ọmọ ilẹ Naijiria nni, Danielle Adewusi to gba aami ẹyẹ Omidan Agbaye tun ti balẹ si orileede Puerto Rico.
Danielle lọ si orileede Puerto Rico lati kopa ninu idije awọn omidan to dara julọ lagbaye, ẹlẹẹkarundinlọgọrin iru rẹ to fẹẹ waye.
Onimọ iṣẹgun oyinbo ni Danielle, ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni
Ọdun 2026 ti a wa yii ni Danielle gba aami ẹyẹ Omidan to rẹwa julọ lagbaye, bẹẹ si ni yoo tun ṣoju Naijiria lorileede Puerto Rico.
Danielle lo kede lori ikanni ayelujara rẹ wi pe oun ti balẹ si orileede Puerto Rico lati kopa nibi eto Omidan to rẹwa julọ lagbaye.
Nigba to n kede, Danielle rọ awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye lati ṣatilẹyin fun, nipa idibo ori ayelujara, ko tun le gbegba oroke.
Awọn alakoso sọrọ
Awọn alakoso eto naa rọ gbogbo awọn ọmọ Naijiria lati dibo fun Danielle ni ẹka 'Beyon the Crown'.
Wọn ni oju opo idibo naa ti wa ni ṣiṣi silẹ fun awọn ololufẹ rẹ lati dibo fun un titi digba ti eto ọhun yoo fi waye, ati pe gbogbo ibo ni yoo di kika.
Eto ẹlẹẹkarundinlọgọrin yii, ni yoo waye lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kọkanla ni gbọngan Coliseo de Puerto Rico José Miguel Agrelot to wa ni San Juan, orileede Puerto Rico.
Awọn akopa lati orileede ti ko din ni ọgọfa ni yoo figagbaga, gẹgẹ bi awọn alakoso Miss Universe Organisation.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni Adewusi ṣoju ipinlẹ Eko nibi eto Omidan Obinrin Agbaye ti Naijiria, eyi to waye ni gbọngan Balmoral to wa nile itura Federal Palace, ni Victoria Island, ipinlẹ Eko.
Adewusi bori awọn akẹgbẹ rẹ mọkandinlogun ti wọn ba a figagbaga.
Taani Danielle?
Ọmọ bibi ipinlẹ Eko ni Danielle
Ẹkọ nipa oogun lo kọ ni King's College niluu London, nibẹ lo ti gba oye MBBS ninu imọ Psychology.
Danielle jẹ ọmọ bibi Tonia Okogbenin, ẹni ṣoju Naijiria lati kopa ninu idije Omidan Agbaye lọdun 1991.
Danielle ni oludasilẹ ajọ Scrub the Stigma, agbekalẹ eto ilera awọn obinrin to gbajumọ ọrọ eto ẹkọ nilẹ Niajiria ati nilẹ Gẹẹsi.



























