Ẹ̀rù ò bodò ló bá dé fún Seyi Makinde- Dotun Oyelade

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X
Kò yà wá lẹnu pé àwọn tó wà léyìn Makinde tẹlẹ n kọ̀wé fipò sílẹ̀- Ijọba Oyo
Ariwo ti awọn eeyan n pa lori ayelujara bayii ni pe ṣe ẹru ko maa ba Gomina Seyi Makinde nibayii ti ọpọ n kuro lẹyin rẹ paapaa awọn to ti n ba a ṣiṣẹ tẹlẹ?
Ẹru ko ba odo ni Omoọba Dotun Oyelade sọ lori koko yii.
O ni pe Seyi Makinde n ṣiṣẹ bo ṣe yẹ nipinlẹ Oyo ati pe ko sewu loko.
Kọmíṣọ́nà fun eto iroyin nipinlẹ Oyo, Ọmọba Dotun Oyelade, ti sọ pe ikọwefiposilẹ Kọmisọna fun eto ìṣúná ati ọrọ ajé, Amofin Ayobami Oluwaseun Ojo ko jẹ iyalẹnu.
Ọmọba Oyelade sọ ninu atẹjade kan ti o fi sita pe Gomina Seyi Makinde ko tiẹ ri ọrọ ikọwefiposilẹ naa ro rara.
Kọmisọna fun eto iroyin nipinlẹ Oyo sọ pe Makinde ko mi ọkan rara lori b'awọn eeyan to n ba a ṣiṣẹ pọ kan ṣe n kọwe fipo sílẹ lera lera.
"Ko tii ṣẹlẹ ri ni Naijiria ki Gomina kan duro lori ẹsẹ rẹ, nigba t'awọn eeyan kàn n dunkooko mọ ọ t'awọn alabaasiṣẹpọ rẹ si n ta ko o.
Nnkan ti Gomina Ipinlẹ Oyo n sọ fun gbogbo wa ni pé oun duro lori otitọ ati pe ẹrí ọkàn oun da oun lare," Oyelade lo sọ bẹẹ.
Ọmọba Oyelade ni Makinde fi n dawon ọmọ Naijiria lójú ni pe o dara ki eeyan ni igboya nigba ti iru ẹni bẹẹ ba n kojú ìṣòro lagbo òṣèlú.
O ni Gomina ipinle Oyo tun fi n dawon ọmọ Naijiria papaa julọ awọn eeyan ipinlẹ̀ Oyo loju pe ko yẹ ki eeyan ni ojo l'asiko to n koju ìṣòro lagbo òṣèlú.
Ọmọba Oyelade sọrọ yii lẹyìn tí Amofin Ojo kọwe fipo sílẹ gẹgẹ bíi Kọmíṣọ́nà fun eto ìṣúná ati ọrọ ajé nipinlẹ Oyo lọjọ Aje ọjọ keji osu Kọkànlá yìí.
Èèkàn ìlú míì tún kọ̀wé fípò sílẹ̀ nínú ìṣèjọba Seyi Makinde lẹ́yìn Segun Ogunwuyi
Ṣaaju lẹyin ọjọ kan ti olori oṣiṣẹ ile ijọba ipinlẹ Oyo, Segun Ogunwuyi kọwe fipo silẹ loṣu Kẹwaa to kọja ni alaga igbimọ to n ri si akoso ile ẹkọ College of Agriculture and Technology, Igboora, Dokita Damilare Gideon Amusan naa ti kọwe fipo rẹ silẹ.
Dokita Amusan ninu lẹta to kọ ranṣẹ si Gomina Seyi Makinde lati kede ikọwefiposilẹ rẹ ni ọjọ Kẹtala ni igbesẹ naa ti bẹrẹ lẹyẹ o sọka.
O sọ pe oun gbe igbesẹ fipo naa silẹ lẹyin ti oun ṣagbeyẹwo ọrọ naa daadaa, to si ni oun dupẹ lọwọ Seyi Makinde fun anfaani to fun oun lati kopa oun lori idagbasoke ile ẹkọ naa.
Amusan ni enikẹta to n kọwe fipo silẹ laaarin ọjọ kan ninu iṣejọba Seyi Makinde lẹyin Segun Ogunwuyi, Tara Adefope, ti oun naa fipo silẹ gẹgẹ bi adari ileeṣẹ Due Process.
Wo igi lẹ́yin ọgbà fún gómìnà Seyi Makinde méje tó ti kúrò lẹ́yìn rẹ̀
Se ni ariwo n sọ lori ayelujara nipa bi awọn alabasisẹpọ ati eekan gboogi ninu ijọba gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo se n fi ipo wọn silẹ ni ẹyọ kọọkan.
Bi ẹ ko ba gbagbe, gomina Makinde lo kuro ninu ẹgbẹ oselu PDP lọ si APM, to si n dije dupo fun ipo aarẹ orilẹede yii latinu ẹgbẹ oselu naa.
Amọ bawọn igi lẹyin ọgba rẹ yii se n fi ojoojumọ ya kuro lẹyin rẹ lo n mu kawọn eeyan maa beere pe ki lo de ti eyi se ri bẹẹ.
Ni ana ode yii ni Olori osisẹ ni ọọfisi gomina, Hon Segun Ogunwuyi naa kọwe fipo silẹ pe oun ko sisẹ olori osisẹ ni ọọfisi gomina mọ.
Eyi si lo mu kawọn ọmọ Naijiria maa figbe bọnu pe ki lo de tawọn eekanlu fi n kuro lẹyin Gomina Seyi Makinde?
Lara awọn oloṣelu ati alatilẹyin jankan-jankan to ti kuro lẹyin Seyi Makinde ni iwọnyi:
1. Alhaji Rasak Gbadegesin (Ọmọ igbimọ Advisory Council).
2. Babs Oduyoye (Ọmọ igbimọ Advisory Council).
3. Amb Taofik Arapaja, (Igbakeji Makinde tẹlẹ).
4. Abbas Oloko ( Igbakeji alaga ajọ to n ri si eto irinna lọ si irinajo mimọ lọ si Mecca fawọn musulumi).
5. Yomi Olajide (Ọre Gomina, Royal Umbrella).
6. Barrister Micheal Lana (Ọmọ igbimọ Advisory Council).
7. Fatai Owoseni (Former SA Security)



























