Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Postpartum Haemorrhage tí Aisha Lawal sọ pé òun ní lẹ́yìn ìbímọ

Oríṣun àwòrán, Aisha Lawal/Instagram
Gbajumọ oṣerebinrin, Aisha Lawal, ti sọrọ lori bi igbeyawo rẹ ṣe tuka, ati awọn nnkan to lakọja nipa ilera rẹ lẹyin to bímọ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu Chude Jideonwo, ni Arabinrin Lawal, ti ṣalaye pe oun la aisan kan ti wọn n pe ni Postpartum Haemorrhage, ati awọn iriri mii kọja, lẹyin ti oun bimọ tán.
Postpartum Haemorrhage ni aisan to maa n kọlu awọn obinrin lẹyin ti wọn ba bimọ tan, to si ma n mu ki ẹ̀jẹ̀ o dà lara wọn ju bo ṣe yẹ, to si maa n ṣekú pa ọpọlọpọ obinrin.
Aisan ọhun, ni Aisha Lawal ṣalaye pe, fi oun si ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun, nitori pe, fun ọjọ mẹta gbako, ni oun ko fi laju saye.
O ni iriri naa mu ki oun ni iporuru ọkan.
Ohun to yẹ ko o mọ nipa Postpartum Haemorrhage (PPH)
Aisan postpartum haemorrhage ni ki ẹ̀jẹ̀ o maa da lara obinrin to ṣẹṣẹ bimọ. Apọju ẹjẹ yii le waye laarin wakati mẹrinlelogun ti obinrin bimọ, titi di bi ọsẹ mẹfa lẹyin to bimọ tan.
Gẹgẹ bi awọn ajọ ilera orilẹede United Kingdom, NHS, ṣe sọ, loootọ ni kii ṣe pe ẹjẹ ko nii jade lara obinrin to ṣẹṣẹ bimọ, ṣugbọn to ba ti di pe ẹjẹ to jade to iwọn ẹẹdẹgbẹta miligiraamu (500 ml), laarin wakati mẹrinlelogun akọkọ lẹyin ibimọ, o ti pọ ju. Eyi si ni wọn n pe ni Postpartum Haemorrhage.
Oriṣiriṣi nnkan lo le mu ki ẹjẹ o jade obinrin to ṣẹṣẹ bimọ ju bo ṣe yẹ. Ileeṣẹ ilera Clever Land Clinic Lara wọn ni ki awọn ẹjẹ to dì, máa jade. Eyi le jẹ àpẹẹrẹ.
Awọn àpẹẹrẹ miran tun ni ki ifunpa lọ silẹ, ooyi, ki oju o maa wo baibai, ọkan yoo maa lu kìkì ju ti tẹlẹ lọ. Yatọ si àwọn nnkan yii, oju ara tabi iho idi, wu, ko si tun fa irora nitori ẹjẹ to di sibẹ.
Ki ni idi ti Postpartum Haemorrhage ṣe maa n waye?
Awọn nnkan to ma n mu ki ẹjẹ o da lara obinrin ju bo ṣe yẹ lọ lẹyin ibimọ ko fi bẹẹ pọ.
Ileeṣẹ ilera Clever Land Clinic sọ pe, ibi ọmọ, ti wọn n pe ni placenta ni ede Gẹẹsi, ma n so mọ ogiri ile ọmọ obinrin, to si maa n pese ounjẹ ati eemi fun ọmọ to wa ninu alaboyun.
Lẹyin ti obinrin ba bimọ tan, ile ọmọ yoo maa fun pọ, ìyẹn 'contraction', lati le ti ibi jade. Bi ile ọmọ ṣe n fun pọ, yoo tun maa sun awọn ọpa to n gbe ẹjẹ sunmọra pada, nibi ti olubi ti kuro.
Sugbọn nigba miran, bi ile ọmọ ṣe n funra rẹ pọ, ko lagbara to lati da ẹjẹ ibimọ duro. Eyi si lo maa n fa bii ida ọgọrin ninu ọgọrun un awọn obinrin to n ni iriri postpartum haemorrhage.
Ẹjẹ tun le pọju, ti diẹ lara ibi ọmọ ba ṣẹ́kù sinu ile ọmọ tabi ti oju ara ati ẹnu ile ọmọ ba ya.
Eyi le mu ki ifunpa lọ silẹ lojiji, to si le fa iku ojiji ti awọn ẹya ara bii ọpọlọ, ọkan, ati awọn mii, ko ba ri ẹjẹ to to gba, ayaafi ti awọn oṣiṣẹ ilera ba tete dawọ ẹjẹ naa duro.
Nitori naa, ti iwọ gẹgẹ bi obinrin to ṣẹṣẹ bimọ tabi wa ni ayika obinrin to ṣẹṣẹ bimọ, ba n ri awọn àpẹẹrẹ ti a mẹnuba yii, tete gba ileewosan lọ.

























