"Àwọn ọmọ Naijiria nílò iná ọba, yéé ṣe àwáwí asán fún wọn"-Atiku tako Tinubu lórí ìlérí ọdún 2023

Atiku Abubakar lapa osi, o mu ẹrọ gbohungbohun dani, Aarẹ Bola Tinubu lapa ọtun, oun naa mu gbohungbohun dani.
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bi awuyewuye ṣe n lọ lori ileri ipese ina ọba to duro deede ti Aarẹ Tinubu ṣe ni 2023 lasiko ipolongo ibo, ọkan gboogi ninu awọn alatako rẹ; Atiku Abubakar, ti ni ki Aarẹ yee sọ awọn awawi ti ko mu nnkan kan wa.

Atiku to fẹ dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC ni 2027, bu ẹnu atẹ lu Tinubu lori ina ọba to n ṣe segesege lorilẹede yii.

O ni awọn ọmọ Naijiria nilo ina, iya si n jẹ wọn lai si ina ọba to wulo fun ọrọ aje wọn.

Tẹ o ba gbagbe, Atiku Abubakar wa lara awọn to lewaju ninu alaye, pe Tinubu ti funra rẹ sọ pe kawọn ọmọ Naijiria ma dibo foun lẹẹkeji, boun ko ba pese ina ọba to duro deede fun wọn ni saa akọkọ.

Peter Obi ati Seyi Makinde tawọn naa fẹ di aarẹ lọdun to n bọ ninu ẹgbẹ ADC ati APM naa si wa lara awọn to n sọ pe Tinubu ti kuna lori ileri rẹ lati fun araalu ni ina ọba to duro deede laaarin ọdun mẹrin akọkọ rẹ nipo.

"Awawi rẹ yii ti su awọn ọmọ Naijiria, awawi lasan ko le tan ina fun wọn"

Ninu atẹjade ti Akọwe iroyin agba fun Atiku, Phrank Shuaibu, fi sita lọjọ Aiku ni wọn ti koro oju si bi ina ọba ṣe n buru si i bayii lorilẹede yii.

Atiku sọ ninu atẹjade naa, pe awọn awawi Tinubu lori ina ko le tan imọlẹ, o ni ki Aarẹ wa bi ileri rẹ to ṣe yoo ṣe wa si imuṣẹ ni.

"Awọn awawi Tinubu ko le tan ina si ile kan ṣoṣo. Awọn ọmọ Naijiria nilo ina, aroye kọ ni wọn fẹ.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Kaakiri Naijiria ni wọn ti pin awọn onibaara to n lo ina si ipele A, B, C, D ati E, ni iye owo ti ko jọ ara wọn.

Lọpọ agbegbe, awọn onibaara to wa ni Band A maa n san to N209.50 fun yuniiti ina kan ṣaaju owo ele ori ọja bi Atiku ṣe wi.

"Atiku tẹsiwaju pe gbogbo awọn to wa ni isọri yii naa lo n jiya ai ri ina lo.

O ni ijọba ko pese ina, wọn si n mu iwe owo ina wa pe kawọn eeyan maa san.

O ni Ọpọ ile lo n wa lokunkun, bẹẹ ni awọn okoowo n fidi rẹmi.

Oludije fun ipo aarẹ naa sọ pe ki Tinubu yee fi ọrọ ina Naijiria ṣe oṣelu, niṣe ni ko pese ina fawọn eeyan ibẹ.

O fi kun un pe araalu nilo alaye Tinubu nipa bi wọn ṣe wa lokunkun latigba yii wa.

O ni wọn ko nilo lati ṣẹṣẹ maa fi ọrọ ẹnu Tinubu mọ ohun ti wọn yoo ṣe to ba jẹ ti ki wọn ma dibo fun un mọ ni.

Bakan naa ni Atiku sọ pe ijọba Tinubu ko pese nnkan amayedẹrun lọwọ ara rẹ to le mu ki ina tun ṣe daadaa lorilẹede yii ju bẹẹ lọ.

O ni ijọba Tinubu n pete ati fopin si owo iranwọ ina lati 2027, o si tun fi n da araalu loju pe oun ko ni I fi owo kun ina ti wọn n san lẹṣẹkẹsẹ.

Atiku beere pe ki ni yoo ṣẹlẹ si owo ti wọn n san bi sọbsidi ba tan.

Ìlérí ìpèsè iná ọba déédé tí Tinubu ṣe ní 2023 tí wọ́n fi ń takò ó báyìí, ki ni Ààrẹ sọ nígbà náa gan-an?

Aarẹ Bola Tinubu

Lọwọlọwọ yii, awọn alatako n gbena woju Aarẹ Bola Tinubu ati ẹgbẹ oṣelu APC, nitori ileri ipese ina ọba fun araalu ti wọn ni Aarẹ ṣe nigba to n polongo ibo ni 2023.

Ileri naa ni wọn ni Tinubu ko muṣẹ titi dasiko yii, to jẹ ina ọba n buru si I ni.

Ẹsun ti wọn fi n kan Aarẹ Tinubu

Awọn eeyan bii Atiku Abubakar, Peter Obi, Seyi Makinde ati bẹẹ bẹẹ lọ to n tako Tinubu n sọ pe Aarẹ ṣeleri lati pese ina ọba fawọn ọmọ Naijiria bi wọn ba dibo fun un nigba naa, ti ina ọhun ko ni I ṣẹju.

Wọn ni Tinubu sọ ọ nita gbangba, akọsilẹ si tun wa fun un pẹlu, bẹẹ ni fidio rẹ tun wa, pe boun ko ba pese ina ọba naa ni saa akọkọ, kawọn eeyan ma dibo foun ni saa keji mọ.

Amọ ileri naa ko wa si imuṣẹ ni ẹsun ti wọn fi n kan Tinubu bayii, wọn ni kaka ko pese ina to ṣeleri, niṣe ni ina ọhun n buru si i.

Ẹsun mi-in ti wọn ka si Aarẹ lẹsẹ ni pe o loun yoo fopin si ki araalu maa sanwo ina nilana iṣiro mita aṣonka (Estimated billing).

Pe iye ina ti araalu ba lo nikan ni wọn yoo maa sanwo rẹ pẹlu onka boun ba di Aarẹ.

Tinubu ko tun ṣe eyi naa ni ẹsun mi-in ti awọn alatako fi n kan an, o si pẹlu ohun ti wọn fi n tako ipinnu rẹ lati tun fẹ lọ fun saa keji bayii.

Ki ni Tinubu sọ nigba naa gan-an?

Ninu fidio kan ti Tinubu ti sọ ọrọ to pada di awuyewuye yii lọdun naa, Tinubu sọ pe:

"Ni ọna yowu ko jẹ, gbogbo ọgbọ́n, ẹ gbọdọ ni ina ẹlẹtiriki, ẹ o si ni i sanwọ ina oni-biili ti wọn n ṣe onka rẹ mọ. (Estimated billings).

"Ileri ti eeyan ba ṣe, o gbọdọ mu un ṣẹ, ti mo ba yẹ adehun naa ti mo si wa pada wa pe ki ẹ dibo fun mi ni saa keji, ẹ ma dibo fun mi mọ, otitọ ibẹ niyẹn.

"Afi ti mo ba fun yin ni idi gboogi ti mi o fi le ṣe ohun ti mo sọ."

Bẹẹ ni Aarẹ Tinubu sọ ninu fidio ọhun.

Ọrọ naa lo di ohun ti wọn fi n tako o bayii.

Wọn ni ko yẹ ki Tinubu tilẹ loun yoo tun dupo aarẹ Naijiria mọ, nigba ti ko mu adehun ina ọba atawọn nnkan mi-in to ṣe lakọkọ ṣẹ.