Lẹ́yìn wákàtì díẹ̀ tí ọkọ kú nípìńlẹ̀ Ogun, ìyàwó rẹ̀ náà jáde láyé

Oluwo Ifa Ikosa, Oloogbe Kabiru Rasaq (Amigboro) ati iyawo rẹ, Oloogbe Kehinde
Àkọlé àwòrán, Oluwo Ifa Ikosa, Oloogbe Kabiru Rasaq (Amigboro) ati iyawo rẹ, Oloogbe Kehinde
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Kayeefi ni iku tọkọtaya kan, Kabiru Rasaq, to jẹ babalawo ati iyawo rẹ, Kehinde ṣi n jẹ fawọn eeyan niluu Odogbolu, idi ni pe lẹyin wakati diẹ ti ọkọ ku ni iyawo rẹ naa jade laye.

Iṣẹlẹ yii waye lọjọ Ẹti, ọgbọnjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2026, niluu Ikosa, Odogbolu, nipinlẹ Ogun.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Oloye ni Oloogbe Kabiru Rasaq tawọn eeyan mọ si Amigboro, ọkunrin naa ni Oluwo Ifa Ikosa, bẹẹ lo si tun jẹ babalawo niluu Odogbolu.

Ẹnikan torukọ ẹ n jẹ Fadipe Gbenro, loju opo Facebook, lo kede iku naa lọjọ Abamẹta to si ṣalaye pe ọjọ kan naa ni awọn tọkọtaya mejeeji jade laye.

O fi kun un pe adanu nla ni iku naa jẹ fun ẹbi Amigboro ati Ojurongbe pẹlu ilu Odogbolu lapapọ.

Fadipe Gbenro ko ṣalaye iru iku to pa awọn tọkọtaya naa, amọ ẹka iroyin Punch royin pe iṣẹ abẹ ni Oloye Amigboro ṣe to ja si iku.

Ẹka iroyin naa sọ pe ẹnikan to ba awọn sọrọ lai darukọ rẹ, sọ pe lẹyin iṣẹ abẹ naa ni Oloye Amigboro ku, ati pe bi wọn ṣe tufọ iku naa fun iyawo rẹ ni obinrin naa ṣubu lulẹ.

Bi Kehinde ṣe ṣubu naa ni wọn lo daku rangbọndan, wọn sare gbe e lọ sile iwosan amọ obinrin naa ko ye e.

Eyi ni iku naa si ṣe n jẹ kayeefi fun gbogbo eeyan niluu naa, titi kan ori ayelujara.

Latigba naa ni idaro ati ọrọ oriṣiriṣi ti n waye lori iṣẹlẹ naa.