Ìdí tí mo fi padá lẹ́yìn Ààrẹ Tinubu lẹ́yìn tí mo tì í lẹ́yìn ní 2023- Gómìnà Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde, ti ṣalaye idi to fi ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ninu eto idibo sipo aarẹ lọdun 2023, to si wa di asiko yii ti ko tẹle e mọ.
Makinde ni ede aiyede to wa ninu ẹgbẹ oṣelu ti oun wa, pẹlu bi ẹni to ti figba kan ri jẹ Igbakeji aarẹ, iyẹn Atiku Abubakar, ṣe kọ jalẹ lati jẹ ki iṣejọba pada si apa Guusu orilẹ-ede yii wa lara ohun to ṣẹlẹ.
Gomina Makinde to ṣalaye ọrọ yii lori eto ileeṣẹ redio kan niluu Ibadan, sọ pe oun ati awọn akẹgbẹ oun tọwọ bọ iwe adehun pẹlu Aarẹ Bola Tinubu nibi ipade kan.
O ni Gomina ipinlẹ Eko; Babajide Sanwo-Olu to ṣoju fun Tinubu ninu ipade naa, fohun sọkan lati sowọpo, ki Bola Tinubu le jawe olubori ni ipinlẹ awọn.
Makinde ni awọn ṣiṣẹ tọ ijaweolubori naa, Tinubu si wọlẹ sipo Aare.
o ni ṣugbọn Aarẹ ko tẹlẹ gbogbo alakalẹ adehun tawọn ni pẹlu rẹ mọ lẹyin to jawe olubori ninu ẹtọ idibo ọhun, eyi to fa a toun fi pada lẹyin rẹ.
Àkóyawọ́ gbọdọ wa lori isiro epo rọbi
Makinde to fẹ dupo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu Allied People's Movement, APM, lọdun to n bọ, pe fun akoyawọ ijọba apapọ Naijiria lori epo rọbi ati bi wọn ṣe n ta a fun araalu.
O ni o yẹ ki ijọba ṣalaye lẹkunrẹrẹ fawọn ọmọ Naijiria lori bi wọn ṣe n fowo kun owo epo , ki araalu le ni agbọye ibi ti bata ti n ta eto ọrọ-ajẹ orilẹede yii lẹṣẹ.
Gomina salaye pe fifun ijọba apapọ ni agbara to pọ ju n mu kudiẹ kudiẹ ba awọn apa kan iṣejọba yooku lati kopa tiwọn lori idagbasoke ọrọ aje ilẹ yii.
Makinde sọ pe o yẹ ki ijọba ipinlẹ ati ibilẹ le kopa tiwọn naa ninu idagbasoke, bo se wa ni awọn orilẹ-ede bii Singapore atawọn ibomi-in.
Ẹgbẹ oṣelu alatako gbọdọ fọwọsowọpọ
Bakan naa ni Gomina Makinde ṣọ pe ifọwọsowọpọ awọn ẹgbẹ oselu alatako nile Naijiria, paapaa bi idibo ọdun 2027 ṣe n sunmọ jẹ ohun to le wa si imuse.
O ni awọn oludije ati ẹgbẹ oselu alatako gbodo ṣera wọn losusu-ọwọ nipa bi orilẹ-ede yoo ṣe tẹsiwaju, ki wọn duro ṣinṣin bii ẹgbẹ ti araalu le dibo yan dipo APC.
Nipa ohun ti yoo ṣe to ba le depo aarẹ ilẹ yii, Seyi Makinde sọ pe ọrọ aje yoo mọyan lori, idagbasoke yoo si kari.
Eto ẹkọ, ọgbin ati bẹẹ bẹẹ lọ yoo gba idasi pẹlu, gẹgẹ bi Makinde ṣe sọ.
























