Ka ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọ̀dọ́kùnrin Zamfara tó pè fún pípa àwọn Kristẹni

Ọwọ to mu ibọn dani ati awọn obinrin to wọ aṣọ dudu ti wọn n gbe ara dalẹ bi wọn ṣe n sunkun
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Zamfara ti fidi fidio kan mulẹ, ti wọn lo ṣafihan ọdọkunrin ọmọ ipinlẹ Zamfara kan pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ, nibi ti wọn ti n pariwo pe ki wọn fun awọn ni ibọn lati lọ fi pa awọn ẹlẹsin Kristẹni.

Afurasi to lewaju ninu fidio naa ni orukọ rẹ n jẹ Umar Ibrahim Gandi Maradun.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Zamfara, Muhammad Bello, ṣe ṣalaye lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii nipa iṣẹlẹ naa, o ni Umar ni afurasi to lewaju ninu fidio naa.

Aṣọ ijọ ẹlẹsin Islam ti wọn kọ 'Jama'atu Izalatil Bidi'a Wa'ikamatus Sunnah' (JIBWIS),ẹka ti Zamfara, si lara lo ni afurasi naa wọ.

Bello sọ pe ninu fidio naa ni wọn ti n kọ orin to n sọ pe 'Ẹ fun wa ni ibọn lati lọ fi pa awọn Kristẹni'.

Bakan naa lo ni awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ Islam meji nijọba ibilẹ Maradun naa wa ninu fidio ti Umar lewaju, ti wọn jọ n kọ orin iku naa.

Awọn ile ẹkọ naa bi wọn ṣe darukọ wọn ni:

Nurul Islam Islamiya ati Akidatul Sahiha Islamiya, ti mejeeji ko ju kilomota ọgọfa (120 kilometres) si Gusau ti I ṣe olu ilu Zamfara lọ.

Iwadii ọlọpaa fidi ẹ mulẹ, pe wọn ya fidio naa lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii, lasiko ti Umar Ibrahim Gandi Maradun n lọ si Mọṣalaṣi Ibn Abi Thalib.

Iroyin sọ pe Umar yii pẹlu awọn kan ni wọn pese aabo fawọn eeyan lasiko irun ati waasi ti wọn ṣe lọjọ Jimọ naa ni mọṣalaṣi ọhun.

Igbesẹ wo ni ọlọpaa gbe lori Umar ati ẹgbẹ rẹ ?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi Kọmiṣanna ọlọpaa Zamfara ṣe wi, o ni ohun to ṣe koko ni lati pese aabo fun awọn olugbe ibẹ lai fi ti ẹsin ti wọn n sin ṣe.

Bello sọ pe lẹsẹkẹsẹ tawọn ti ri fidio naa lawọn ti gbe ikọ ọtẹlẹmuyẹ dide lati mọ awọn to wa nidii rẹ ati idi ti wọn tiẹ fi ṣe fidio ọhun.

Iroyin sọ pe ijọ JIBWIS ti afurasi naa n ṣe lo tiẹ fa a le ọlọpaa lọwọ fun iwadii.

Ọlọpaa tẹsiwaju pe awọn ba awọn olori JIBWIS lẹka apapọ ati ti ipinlẹ sọrọ lori iṣẹlẹ yii.

Wọn ni ijọ naa loun ko mọ nnkan kan nipa fidio ti Umar ṣe, awọn ko si mọ idi to fi ṣe e.

Amọ ọlọpaa ti mu afurasi naa sọdọ gẹgẹ bi kọmiṣanna ṣe fidi ẹ mulẹ, bẹẹ ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii.

Ileeṣẹ ọlọpaa koro oju si fidio naa, ṣapejuwe rẹ bii eyi to kun fun ikorira to si le da rogbodiyan silẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa Zamfara rọ awọn olori ẹsin, obi, alagbatọ, ile ẹkọ atawọn alẹnulọrọ, lati kilọ fawọn ọmọ wọn, paapaa awọn ọdọ lati ṣọra fun iru iwa bayii.

O ni ki araalu fọkan balẹ, ki wọn ma si ṣe ohunkohun ti yoo da rogbodiyan silẹ rara.

Ta a ni Umar Ibrahim Gandi Maradun?

Gẹgẹ bi ileeṣẹ ọlọpaa Zamfara ṣe ṣalaye, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2004 ni wọn bi Umar Ibrahim Gandi Maradun.

Ẹni ọdun mejilelogun (22) ni.

O lọ sile ẹkọ alakọọbẹrẹ Mualledi Model Primary School ati Government Day Secondary School, Maradun, ipinlẹ Zamfara.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Umar darapọ mọ JIBWIS ni 2025, o si ṣẹṣẹ fẹẹ wọ Yunifasiti lati kẹkọọ nipa iṣẹ iroyin ni Yunifasiti ipinlẹ Zamfara ni.

Wọn yoo gbe e lọ sile ẹjọ lori bi iwadii ba pari bi ọlọpaa ṣe sọ.

Ẹsun ti wọn yoo fi kan an ni sisọ ohun to le da rogbodiyan silẹ, dida omi alaafia ilu ru, ati idunkooko mọni.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun 2025 to kọja yii ni Aarẹ orilẹede America, fi ẹsun kan pe awọn eeyan kan n pa Kristẹni ni Naijiria, to si dide lati gbeja wọn.

Bo tilẹ jẹ pe awọn alẹnulọrọ dide nigba naa, ti wọn ni Kristẹni nikan kọ ni ipaniyan naa n kọ, nitori awọn to n pa eeyan naa n wọ mọṣalaṣi pẹlu.