Báwo ni wọ́n ṣe pa Masussuka, gbajúmọ̀ Ìmáàmù arọwààsí ní Katsina?

Sheikh Yahya Ibrahim Masussuka nigba to wa laye
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina ti fidi rẹ mulẹ pe otitọ ni wọn ti pa gbajugbaja Imaamu arọwaasi nni, Sheik Yahya Masussuka si ile rẹ to wa ni Dutsen-Ma.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC, ọga ọlọpaa ẹkun Dutsen-Ma sọ pe awọn agbebọn lo ṣeku pa mọle ni irọlẹ ọjọ Aje to kọja.

Ọga ọlọpaa naa, CSP Auwalu Gwadabe sọ pe ẹnu ọna ile Masussuka ni wọn yinbọn pa a si, ti awọn dokita si fidi rẹ mulẹ pe o ti ku, nigba ti wọn gbe e dele iwosan.

Akọwe agba Imaamu arọwaasi naa, Ọmọwe Mustapha Haruna, fidi iroyin naa mulẹ, to si ni ile iwosan ijọba ti Dutsen-Ma ni wọn ti fidi iku rẹ mulẹ, ni kete ti wọn gbe e debẹ.

Ọkan lara awọn agba ẹsin toun naa ṣe waasi bii ti Masussuka, Sheikh Usman Dangungu, sọ pe iroyin iku oloogbe naa ba oun lojiji.

Danungu sọ pe awọn yoo gba awọn agbofin laaye lati ṣiṣẹ iwadii finnifinni, lati mọ awọn to lọwọ ninu iku Masussuka.

Ṣaaju ki wọn too ṣeku pa a, Sheikh Masussuka wa lara awọn agba Musulumi ti waasi wọn maa n fa ariyanjiyan ati awuyewuye kaakiri ẹkun Ariwa Naijiria, ati orileede to sunmọ ilẹ naa.

Bi awọn agba ẹsin naa ṣe n tako awọn waasi Masussuka lori bo ṣe n tako awọn ilana Muhammad ti awọn Musulumi nigbagbọ ninu ẹ, pẹlu awọn aritọtasi ninu Kuraani, naa ni awọn miran n ṣatilẹyin fun.

Ọkan lara awọn waasi oloogbe naa, lo jẹ ki ijọba ipinlẹ Katsina ranṣẹ pe e ninu oṣu Kọkanla, ọdun 2025, nipa bo ṣe n bu ẹnu atẹ lu awọn agba ẹlẹsin naa, to si n tẹ awọn ọrọ Wolii Muhammad loju mọlẹ.

Bí wọ́n ṣe pa Sheikh Masussuka

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Katsina fi sita lati ọwọ agbẹnusọ rẹ, Abubakar Aliyu, o jẹ ko di mimọ pe nnkan bi agogo meje aabọ irọlẹ ni wọn lọ ka Sheik Masussuka mọ ẹnu ọna abawọle rẹ nijọba ibilẹ Dutsen-Ma, ipinlẹ Katsina.

Atẹjade naa ṣalaye pe, "wọn pa arọwaasi naa pẹlu ọrẹ rẹ, Adamu Abubakar pẹlu ibọn ni."

Akọwe arọwaasi naa sọ pe Masussuka fẹẹ jade nile, lati lọ sibi to ti ma lọ n ṣe aṣaro, gẹgẹ bi iṣe rẹ ni, lasiko ti wọn ka a mọ.

Ọlọpaa sọ pe kete ti awọn agbebọn naa lọ, lawọn eeyan sare gbe Masussuka ati ọrẹ rẹ lọ sile iwosan lati doola ẹmi wọn, to si jẹ pe ibẹ ni wọn ti fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeeji ti ku.

Atẹjade naa tun fidi rẹ mulẹ pe ọga ọlọpaa ipinlẹ naa to paṣẹ pe ki ẹkunrẹrẹ iwadii bẹrẹ lati tọpinpin awọn agbebọn ati gbogbo awọn to lọwọ ninu iku rẹ.

Ìmọ̀ nipa ẹ̀kọ́ wáàsí rẹ̀

Gẹgẹ bi kii ṣe e fi imọ ati oye rẹ pamọ, Sheikh Masussuka jẹ ẹnikan to n tẹle ẹkunrẹrẹ oye to ni nipa Kuraani, eyi to si ti jẹ ko maa bu ẹnu atẹ lu awọn adiiti (Hadiths) to sọ pe "o n ṣakoba fun iru ẹda ti ojiṣẹ Muhammad jẹ."

O ti fun ara rẹ lorukọ ti wọn fi n pe e, "Ritaya Dole", eyi to fi n sọ pe oun ni ipinnu lati jẹ ki awọn alatilẹyin oun maa tẹle, lati ni oye nipa ohun not pe ni "Salaf".

Bakan naa lo tun loun fẹ ki wọn mọ ohun to n jẹ Ahlussunnah, tabi awọn ọmọ ẹgbẹ Izala sect, burki.

Ọrọ yii ni wọn sọ pe igbagbọ pe o ti jẹ ki ariyanjiyan wa laaarin awọn alatẹle Salaf ati arọwaasi naa, pẹlu bi wọn ṣe bẹrẹ sii sọrọ kugbakgba sira wọn lori ayelujara.

Sheikh Masussuka ni ileeṣẹ amohunmaworan ati redio, to fi mọ awọn ile-ẹkọ ni Dutsen-Ma, ipinlẹ Katsina, eyi to gbe kalẹ lati maa fi ṣe igbelarugẹ fun ilana ẹkọ Kuraani.