Igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá fipò sílẹ̀ nítorí ẹ̀sùn ìbálòpọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹyin ọsẹ mẹta ti wọn fi ẹsun aṣemaṣe ibalopọ kan an, Igbakeji ọga ọlọpaa lorilẹ ede South Africa ti kọwe fipo rẹ silẹ.
Igbakeji ọga ọlọpaa naa, Lt Gen Shadrack Sibiya, fiwe ọhun silẹ nipasẹ agbẹjọro rẹ, lọjọ Aje, ọjọ kejila oṣu Kẹwaa ọdun 2026 yii.
Ki ni wọn ni ọlọpaa naa ṣe gan-an?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi ẹsun ọhun ṣe ka, wọn ni ọga ọlọpaa Sibiya ba ọmọbinrin ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹrindinlogun (16), ṣe awada akọ ti ko tọ, wọn lo tun fipa ba obinrin mi-in toun jẹ ẹni ọdun mejidinlogun (18) lo pọ.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun mimu eeyan kuro nibi to wa fun ilokulo kan an .
Sibiya jiyan pe oun ko ṣẹ awọn ẹṣẹ yii.
O ni loootọ loun ba ọmọ ọdun mejidinlogun naa lo pọ, amọ ki I ṣe pelu ipa, bi ko ṣe pe ajọsọ awọn ni lati jọ gbaduna ara awọn.
Lati ọsẹ kẹta sẹyin ti ẹsun yii ti waye ni ọkunrin naa ti wa ni atimọle, nigba ti kootu kọ lati fi aaye oniduuro silẹ fun un.
Agbẹnusọ ọlọpaa ibẹ, Athlenda Mathe, sọ ninu atẹjade to fi si oju opo X rẹ, pe bi Sibiya ṣe fiṣẹ silẹ yii mu ẹtẹ ati abuku wa fun un.


























