Ẹ san N1.4bn fáwọn ẹbí awakùsà 33 tó kú sí àhámọ́ NSCDC ní ìpínlẹ̀ Niger àtàwọn awakùsà 44 tó ye ìṣẹ̀lẹ̀ náà - Ìgbìmọ̀ olùwádìí

Oríṣun àwòrán, Nigeria Security and Civil Defence Corps/Facebook
Igbimọ oluwadi ti ijọba apapọ gbe kalẹ lati tan imọlẹ si irufẹ iku to pa awọn awakusa mẹtadinlogoji ni ẹẹkannaa ni ahamọ ileesẹ aabo ara ẹni ni aabo ilu, NSCDC ni ipinlẹ Niger ri gbe iwadi rẹ kalẹ.
Abọ igbimọ naa salaye pe awọn alaisi naa ku lati ipasẹ airi afẹfẹ mi sinu daadaa, eyi to mu ki wọn kọkọ daku, ki wọn to ku patapata tawọn onisegun oloyinbo n pe ni asphyxiation.
Igbakeji Alaga igbimọ oluwadii naa, tii tun se igbakeji oludari tẹlẹ fun ileesẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, Jonathan Kure, lo sisọ loju eleyi lọjọ Aje lasiko to n gbe abọ iwadii rẹ kalẹ fun Minisita fọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo, nilu Abuja.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi ni koko aba mẹta ti igbimọ oluwadii gbe kalẹ nipa isẹlẹ awakusa to ku
Alaga igbimọ naa daba pe iku to se yẹ ni iku naa nitori awọn oloogbe naa, to fi mọ ọmọde mẹrinla, ko ba ti ku to ba jẹ pe wọn ko ti wọn mọle ninu ipo ti ko bojumu.
- Kure salaye pe igbimọ oluwadi naa daba pe ki ijọba san biliọnu kan ati miliọnu lọna irinwo naira fawọn ẹbi alaisi mẹtalelọgbọn ati awọn awakusa mẹrinlelogoji to ye isẹlẹ naa.
- Bakan naa ni igbimọ oluwadii yii, ninu abọ rẹ daba pe ki wọn gba isẹ lọwọ oludari ileesẹ aabo ara ẹni laabo ilu, NSCDC tipinlẹ Niger ati gbogbo awọn osisẹ ajọ naa to lọwọ ninu titi awọn awakusa naa mọle, titi ti wọn fi ku.
- Igbimọ naa tun daba pe ki ijọba se atunto ati atunse ileesẹ NSCDC lorilẹede yii, ki wọn si ro awọn lọgalọga nileesẹ naa lagbara si.
Minisita fọrọ abẹle, to tẹwọ gba abọ iwadii naa wa seleri lati se amusẹ awọn aba ti ajọ naa gbe kalẹ, ki idajọ ododo le wa fawọn eeyan ti ọrọ naa kan.
Tunji-Ojo tun pasẹ fun oludari agba fajọ NSCDC lati kede pe kawọn osisẹ ajọ naa to tete se afọmọ atimọle ti awọn oloogbe ku si, ki wọn le bo idajọ ododo mọlẹ lati lọ rọọkun nile na.
Isẹlẹ atimọle awọn awakusa yii si lo waye lọjọ Kẹtadinlogun osu Kẹsan ọdun 2026 nipinlẹ Niger nigba ti awọn awakuta mẹtalelọgbọn ti awọn osisẹ NSCDC ko si ahamọ jade laye.
Ki lo ti waye saaju lori isẹlẹ yii?
Bi iroyin iku awọn awakusa lọna aitọ mẹtadinlogoji to waye nipinlẹ Niger, lakata awọn ẹṣọ Aabo ara ẹni laabo ilu (NSCDC) ṣe n tan kalẹ, Gomina ipinlẹ naa, Mohammed Umaru Bago, ti sọ ohun to ni oun gbọ nipa rẹ.
Gomina Bago sọ fun BBC pe awọn kan ti ori ko yọ ninu awọn awakusa naa sọ pe wọn fin kinni kan si awọn afurasi awakusa naa lara ṣaaju iku wọn.
Ijọba ipinlẹ Niger wa kede ofin konile o gbele fun ọjọ kan ni ilu Minna, olu ilu ipinlẹ naa latari iwọde to bẹrẹ ni ilu naa lori iku awọn eeyan ti wọn fẹsun kan pe wọn n wakusa lọna aitọ to ku si ahamọ ajọ ẹṣọ aabo NSCDC.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ fun BBC pe lẹyin irun jimọ ni ofin konile gbele yoo ti bẹrẹ ti di ọla, ọjọ Abamẹta.
Ileeṣẹ ọlọpaa rọ awọn eeyan lati tẹle ofin naa lojuna ati da aabo bo emi ati dukia awọn ati lati dena dida ilu ru latọwọ awọn kọlọransi eeyan.
Awọn fidio to wa lori ayelujara ṣafihan bawọn ọdọ kan ṣe ya sawọn opopona to ṣe koko ni ilu Minna lati fẹhonuhan lori iku awọn eeyan naa.
Fidio naa ṣafihan bawọn ọlọpaa ṣe n gbiyanju lati fi afẹfẹ gaasi tajutaju lati fi tu awọn eeyan naa ka.
Ijọba apapọ Naijiria ti wa sọ pe ki ọga agba ileeṣẹ alaabo NSCDC nipinlẹ Niger lọ rọkunle, nitori b'awọn afurasi kan ṣe ku si ahaamọ labẹ iṣakoso rẹ.
Suberu Aniviye lorukọ ọga agba naa ti ijọba apapọ ni kọ lọ rọkunle.
Minisita fọrọ abẹle, Olubunmi Tunji-Ojo lo fidi iroyin yii mulẹ ninu atẹjade to fi sita lorukọ ijọba apapọ Naijiria.
Atẹjade naa ti oludamọran pataki fun minisita naa lori eto iroyin, Alao Babatunde buwọ lu, jẹ ko di mimọ pe ohun to ku diẹ kaato ni iku awọn eeyan naa.




























