Wó kókó ohun márùn-ún tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìpolongo ìbò tí Ààrẹ Tinubu bẹ̀rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Kaduna

Bi orileede Naijiria ṣe n gbaradi fun eto idibo apapọ ọdun 2027, ẹgbẹ oṣẹlu APC ti bẹrẹ eto ipolongo idibo fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, eyi to bẹrẹ lọjọ Kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 nipinlẹ Kaduna.
Eto ipolongo naa, ni awọn eekan-eekan, agba oṣelu, gomina, to fi mọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati afẹnifẹre kaakiri orileede Naijiria yoo ti kopa.
Eyi si ni o jẹ ọkan lara awọn igbesẹ ati ilana ẹgbẹ fun igbaradi ipadabọ Tinubu fun saa keji.
Ipade yii ni yoo tun fun ẹgbẹ APC lanfaani lati ṣagbekalẹ awọn ilana bi eto ipolongo wọn yoo ṣe lọ, ati ọna ti wọn yoo gba lati polongo awọn aṣeyọri Tinubu ni saa akọkọ yii fun awọn araalu.
Fun idi eyi, ki lo de to jẹ pe ipinlẹ Kaduna ni eto ipolongo naa ti bẹrẹ? Ki ni awọn ohun to ṣee ṣe ko jẹyọ nibẹ, ati pe ki lo de ti APC fi yan ipinlẹ Kaduna laayo lati fi ṣide eto ipolongo wọn?
Awọn nnkan wọnyi ni BBC yoo maa ṣagbeyẹwo rẹ fun yin.
Igba wo ni eto ipolongo idibo bẹrẹ?

Gẹgẹ bi eto to ti wa nilẹ, ọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026 ni eto ipolongo idibo yoo bẹrẹ.
Ipolongo naa ni yoo jẹ iṣide ati akọkọ oniruuru iwọde ipolongo ti APC gba lero lati ṣe kaakiri ẹkun ati agbegbe orileede Naijiria, lati fi wa ojurere gbogbo awọn oludibo ṣaaju eto idibo ọdun 2027.
Gẹgẹ bi alaga igbimọ eto ipolongo Aarẹ Tinubu, Gomina Abdul'aziz Yari to jẹ gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ, wọn tun ti ṣagbekalẹ eto ipolongo kaakiri awọn ipinlẹ miran.
Lẹyin ipolongo Kaduna, awọn ipinlẹ bii Port Harcourt, Rivers State ati Maiduguri, nipinlẹ Borno ni wọn yoo tun gbe ipolongo naa lọ.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe ẹkunrẹrẹ nipa eto ipolongo naa ni igbimọ alakoso ipolongo yoo gbe jade.
Nibo ni ipolongo naa yoo ti waye?

Ifilọlẹ eto ipolongo idibo Aarẹ Tinubu yoo waye ni papa iṣere ipinlẹ Kaduna to wa ni ilu Kaduna.
Igbakeji gomina ipinlẹ Kaduna, Ọmọwe Hadiza Balarabe, to jẹ alakosoo eto ipolongo naa, sọ pe gbogbo eto lo ti pari patapata lati gba Aarẹ ati awọn eekan-eekan lalejo.
Balarabe sọ eyi di mimọ lasiko to ṣe abẹwo lọ sinu ọgba papa iṣere naa, to si fidi rẹ mulẹ gbogbo ohun to yẹ ni wọn ti fi lelẹ fun eto ọhun lati waye.
Ki lo de to jẹ ipinlẹ Kaduna?
Kaduna jẹ ọkan lara awọn agbegbe ni ẹkun Ariwa Naijiria to ṣe pataki fun oṣelu. Ilu naa lo ti figba kan ri jẹ olu ileeṣẹ eto oṣelu lẹkun Ariwa Naijiria, leyi to jẹ ki wọn ṣe pataki ninu itan ẹkun naa.
Igbimọ ipolongo naa ṣalaye pe fun Aarẹ lati yan agbegbe naa, o ṣafihan bi Aarẹ Tinubu ]se mu ọrọ agbegbe naa lọkunkundun, ati erongba lati mu ki irẹpọ wa laaarin awọn eeyan to wa nibẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni Kaduna dara fun oniruuru eto ati ayẹyẹ nitori pe o ṣe pataki fun ẹkun Ariwa, atpe o jẹ ipinlẹ to gba oniruuru ẹya mọra.
Ohun miran ti wọn lo tun fa a, ni igbiyanju APC lati ro ẹkun Ariwa-Iwọ-Oorun lagbara, iyẹn ẹkun to ṣe pataki lati maa wa ibo fun Aarẹ.
APC ti sọ pe awọn fẹ ki Tinubu ri ọpọ ibo lati awọn ipinlẹ ẹkun Ariwa. Ẹkun ti ẹgbẹ naa ti sọ pe awọn yoo wa ibo miliọnu meji fun Tinubu lasiko eto idibo ọdun 2027.
Iru awọn eto wo lo ti wa nilẹ fun ipolongo yii?

Ijọba ipinlẹ Kaduna ati igbimọ olupolongo idibo naa sọ pe eto aabo to muna doko ti wa nilẹ fun eto ọhun lati waye.
Kọmiṣanna feto iroyin, Maiyaki sọ fun BBC pe ipinlẹ naa ati ileeṣẹ eleto aabo ijọba apapọ ni wọn ti gbaradi lati daabo bo ẹmi ati dukia, paapaa Aarẹ, awọn olori ẹgbẹ ati awọn akopa.
Bakan naa lo tun kede pe gbogbo awọn to ba n wọle sinu papa iṣere naa ni wọn yoo ṣayẹwo ara wọn lati rii pe eto aabo to daju wa.
Lara awọn olugbe ipinlẹ naa to ba BBC sọrọ sọ pe awọn ti ri awọn eleto aabo lọpọ yanturu lawọn agbegbe to ṣe pataki bii opopona kaakiri Kaduna.
Bawo ni Kaduna ṣe ṣe pataki si Tinubu to?
Fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, Kaduna ṣe pataki, kii ṣe fun agbegbe eto ipolongo idibo oṣelu nikan, ṣugbọn o tun jẹ anfaani lati ṣafihan agbara ti ẹgbẹ naa ni, iṣọkan awọn agbaagba, to fi mọ atilẹyin to ri gba lati ẹkun naa.
Kaduna jẹ ipinlẹ to kun fun oniruuru ẹya, ẹsin ati oṣelu. Eleyi lo si jẹ ki atilẹyin maa wa lati ọdọ awọn eeyan fun Tinubu.
Bakan naa ni Kaduna tun jẹ pataki fun Aarẹ Tinubu lati ri oludibo to pọ lati ẹkun naa, ati pe gẹgẹ bi ajọ eleto INEC ṣe sọ, ẹkun naa lo ni awọn to forukọ silẹ fun eto idibo to pọ julọ nilẹ Naijiria.
Lọdun 2023, Atiku Abubakar tẹgbẹ oṣelu PDP nigba naa ni ibo to le ni idajọ miliọnu kan (554,360), eyi to fi bori Tinubu to ni ibo ẹgbẹrun lọna irinwo din diẹ (399,293).


























