Gbajúmọ̀ òṣèré Anike Sinleke jáde láyé

Adenike Abike Babajide wọ aṣọ funfun pẹlu ilẹkẹ lori rẹ
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ oṣere Adenike Abike Babajide tawọn eeyan mọ si Anike Sinleke ti jade laye lẹyin ti arun jẹjẹrẹ ile ọmọ ba a finra.

Ọjọ kejilelolgun, oṣu Kọkanla ọdun 2026 yii ni iroyin kan jade wi pe Anike Sinleke ti dagbere faye.

Asiwaju Bukola Fagbuyi to maa n ṣe eto 'Rubbin Minds With Bukky' lori Instagram lo kede iku oṣere naa.

Fagbuyi sọ pe o yẹ ki Anike wa sori eto naa lọjọ to ku ki oun to gbọ iroyin iku rẹ.

Ohun to yẹ ki o mọ nipa Anike Sinleke to jade laye

Anike Sinleke bẹrẹ iṣẹ tiata labẹ agbaọjẹ osere, Remmy Shitta, o si tun ṣiṣẹ pọ pẹlu Deji Adenuga naa.

Sinleke yẹba fun iṣẹ tiata diẹ laarin kan lati kẹkọọ gboye HND lẹnu ẹkọ rẹ.

Yatọ si ere tiata ṣiṣe, Anike Sinleke tun kopa ninu eto arinrin oge Sisi Eko beauty pageant niluu Eko.

Anike Sinleke fi tọkan tọkan ṣisẹ lori eto arinrin oge naa, eyi ti wọn ṣe ifilọlẹ rẹ lọdun 2011.