NAFDAC ṣàwárí èròjà aṣekúpani tó fa ikú ọ̀pọ́ èèyàn nínú ọtí l'Ondo, àlàyé rèé

Ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, o n sọrọ lọwọ, o mu ẹrọ gbohungbohun dani

Oríṣun àwòrán, NAFDAC

Àkọlé àwòrán, Ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ajọ to n ri si aabo ounjẹ ati oogun lorilẹede Naijiria NAFDAC, ti kede eroja aṣekupani kan to wa ninu ọti ibilẹ to fa iku ọpọ eeyan nipinlẹ Ondo.

Ninu atẹjade kan ti ọga agba ajọ NAFDAC, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye, fi sita lọjọ Ẹti ni wọn ti kede pe eroja kan ti a mọ si Methanol lo fa iku awọn eeyan naa.

NAFDAC kede pe Methanol yii pọ lapọju ninu ọti ọhun, eyi to pada ja siku fawọn to mu un.

"Ayẹwo mọkanla ninu mẹẹẹdogun fi han pe eroja kan ti a mọ si Cannabis indica tun wa ninu awọn ọti naa"

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe tẹsiwaju, yatọ si Methanol to jẹ aṣekupani, iwadii nipa ọti ibilẹ to mu iku wa naa tun fi han pe eroja kan ti a mọ si Cannabis indica tun wa ninu ọti naa.

Ẹ o ranti pe ibẹrẹ oṣu Kẹsan-an yii ni iroyin iku ojiji to n pa wọn nijọba ibilẹ Odigbo, niluu Ondo naa jade sita.

Ni bayii, akọsilẹ lori rẹ fi han pe eeyan mejidinlaadọta (48) lo ti ku, bẹẹ ni iṣẹlẹ naa ti kan eeyan mejilelọgọsan-an (182).

Awọn ilu ti iṣẹlẹ naa ti kan bi NAFDAC ṣe kede ni :

Odole, New Town, Okele, Orita Odigbo, Araromi-Obu ati Oniparaga, amọ Odigbo Town ati Araromi-Obu ni wọn lo ti gbilẹ ju.

Nigba ti yoo fi di Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii, eeyan eeyan aadọrun (90) lo balẹ sile iwosan, amọ wọn pada yọnda wọn lati maa lọ sile.

Awọn mẹfa wa nibẹ ti wọn n gba itọju, awọn mọkanlelọgbọn (31) n ti ile waa gba itọju nileewosan, eeyan marun-un padanu iriran wọn patapata, nigba tawọn meji n riran baibai latari ọti ọhun ti wọn mu gẹgẹ bi NAFDAC ṣe wi.

Ki ni Methanol?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Eroja ti a mọ si Methanol yii mọ gaara, ko ni awọ kan pato, o si maa n tete gbina nitori kẹmika to wa ninu rẹ.

O maa n run bii ọti, o si fi ara pẹ eroja ti a mọ si Ethanol.

Wọn maa n lo o fun awọn nnkan bii kẹmika, ike, awọn eroja ti wọn fi n fọ ilẹ, fun ẹnjiini ọkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Bi Methanol ṣe wulo fun awọn nnkan wọnyi to, ewu gidi lo jẹ fun ẹda eeyan.

O yatọ si eroja irufẹ Ethanol kan to maa n wa ninu awọn nnkan mimu.

Gẹgẹ bawọn dokita ṣe wi, bi eeyan ba mu diẹ kekere ninu Methanol, o le fa ki oju ẹni naa fọ, o le fa ki awọn ẹya ara pataki bii kindinrin ati ẹdọ daṣẹ silẹ, o si le fa iku paapaa.

NAFDAC ninu ikilọ ti wọn fi sita, ṣalaye pe awọn eeyan to mu ọti yii amọ ti wọn moribọ ṣi le pada ku bi wọn ba tun mu iru rẹ lẹẹkan si i.

Ajọ naa sọ pe eeyan mẹẹẹdogun ni ọwọ ofin ti ba lori ẹsun yii, bẹẹ ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mọ bi Methanol yii ṣe pọ to, atawọn eroja mi-in to tun ṣee ṣe ko wa ninu awọn ọti yii.

"Bi Methanol ba wa ninu nnkan mimu, o lewu gidi.

"Bi eeyan ba mu un, o le fa ki eeyan ma riran mọ, ki ẹya ara daṣẹ silẹ ati iku."

Bẹẹ ni NAFDAC kilọ.

Ìjọba ìpinlẹ Ondo ṣetán láti fọwọ́ òfin mu ẹni tó bá ṣì n ta 'Monkey tail'

Ọkunrin kan loṣo pẹlu kondoro niwaju rẹ

Oríṣun àwòrán, Ondo Police command/X

Lori ọrọ iku eeyan to ti le ni mọkandinlaadọta bayii ni ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe ọwọ ofin yoo maa tẹ ẹnikẹni to ba ṣi ni agbo 'Monkey Tail' ni ori igba.

Bayii ijọba Ondo ti kede pe ofin ti wa lori gbogbo agbo lai ki nṣe Monkey Tail nikan ti ko ba ni ontẹ NAFDAC, ajọ to n mojuto ounjẹ, oogun ati ohun ti awọn ọmọ Naijiria n lo.

Atẹjade ti kọmiṣanna feto iroyin ati ilanilọyẹ nipinlẹ naa, Idowu Ajanaku fi sita lọjọ Abamẹta to kọja fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lati dẹkun iku awọn araalu lọna aitọ.

Ajanaku sọ pe iku awọn eeyan ọgbọn naa lo nii ṣe pẹlu ọti lile ti wọn mu, to si lawọn ko tun gbọdọ jẹ ko tan kaakiri ipinlẹ ọhun.

O tun fidi rẹ mulẹ pe igbesẹ naa waye lẹyin ti kọmiṣanna feto ilera, Dokita Banji Awolowo-Ajaka fidi rẹ mulẹ pe eeyan mọkandinlọgbọn ku lẹyin ti wọn mu ọti lile tan, ati pe iṣẹle to to ọgọta iru rẹ ni awọn ti ṣe akọsilẹ rẹ.

Kọmiṣanna feto ilera sọ pe awọn mẹta lo ti wa lori bẹẹdi, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, nigba ti wọn n wo iṣesi awọn mẹtadinlọgbọn miran.

Mọ̀ nípa 'monkey tail', ọtí tó ń ba ẹ̀dọ̀ àti ìfun jẹ́ tó ti gbẹ̀mí èèyàn 49

Dokita Fashua Ayodeji Anthony to n tọju awọn eeyan to mu ogogoro ''monkey tail'' to ti ṣekupa eeyan mọkandinlaadọta bayii nipinlẹ Ondo sọ pe ọti ogogoro tuntun lo tun n ṣekupa awọn eeyan bayii nipinlẹ naa.

Dokita Anthony to jẹ ọga ile iwosan Life Care Hospital ni Orita Odigbo sọ pe ''iwadii fi han wi pe wọn ṣẹṣẹ po ọti ogogoro tawọn eeyan n mu lọwọ bayii eyi to n ṣakoba fun agọ ara wọn pọ ni.

O yato si eyi ti wọn kọkọ mu to ṣakoba fun ọpọ eeyan ni ibẹrẹ oṣu Keje to kọja lọ.

A tun ri pe lara awọn eeyan ti ọti yii n ṣakoba fun ti ni awọn aisan kan tabi omiran lara tẹlẹ.

Ọpọ ninu wọn lo ti ni arun Hepatitis B lara, awọn ni aisan ẹjẹ ruru, bẹẹ lawọn mii ni aisan ẹdọ ninu agọ ara wọn.

Ọpọ awọn eeyan yii ni wọn ko mojuto aisan to wa lara wọn tẹlẹ ki wọn to tun lọ mu ogogoro yii.''

Ọga agba ile iwosan Life Care ni Orita Odigbo sọ pe awọn eeyan mii tun le dagbere faye ti wọn ko ba dẹkun mimu ogogoro to wa nita naa.

Dokita Anthony fikun ọrọ rẹ pe awọn kan wa ti ọti yii ko jẹ ki wọn riran mọ.

Ọga agba ile iwosan Life Care sọ pe awọn to ti gbadun naa si tun n wa fun ayẹwo loorekoore ki awọn le mọ ibi ti ara wọn ku si.

Àwọn kan ò ríran mọ́ lẹ́yìn tí wọ́n mu ọtí 'monkey tail' l'Ondo, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn míì sì kú, àyàfi... - Dókítà ṣàlàyé

Dokita Anthony ṣalaye pe ''inu ifun ni ogogoro yii maa n kọkọ lọ gbara ti wọn ba ti mu un.

Ọti yii maa n jẹ ki wọn maa bi, eebi yii le ṣakoba fun nnkan miran ninu ara.

Amọ, awọn ti wọn ko ba bi pupọ ju, o ṣee ṣe ki ọti naa lọ sinu ọpọlọ wọn.

Bayii ni ọti naa yoo kọja lọ sinu oju ti yoo si ba oju jẹ, o le kọja lọ sinu kindinrin naa lati ba a jẹ.

O tun le lọ sinu ẹdọ tabi inu ọkan lati ba a jẹ, lẹyin iyẹn bayii, iku lo kan.''

Ọga agba ile iwosan Life Care ni ijọba ti ṣiṣẹ takun takun lori iṣẹlẹ naa tori wọn ti fọwọ ofin mu ọpọ awọn to n ta ọti yii.

Dokita naa ṣalaye wi pe lara awọn to n ta ọti ọhun gan an naa ti ku lẹyin tawọn naa mu un tan.

O sọ pe ijọba ti n ṣe polongo kaakiri fun araalu wi pe ki wọn ye ta tabi ra ọti ''monkey tail'' to n pawọn eeyan naa mọ.

Amọ, Dokita Anthony sọ pe awọn eeyan ti wọn n gbe ninu oko ti wọn ko lanfaani lati gbọ iroyin lo ṣee ṣe ki wọn tun maa mu ọti yii.

Eeyan 49 lo ti ku bayii lẹyin ti wọn mu ọti ''monkey tail'' l'Ondo

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ondo ti kede pe o ti di eeyan mọkandinlaadọta to ti ku bayii lẹyin ti wọn mu ogogoro ''monkey tail'' nipinlẹ naa.

Ijọba ni eeyan aadọsan ni akọsilẹ fi han pe ọti naa ṣe akoba fun kaakiri ipinlẹ Ondo.

Iṣẹlẹ naa to kọkọ waye Araromi-Obu ati Odigbo ni ijọba ibilẹ Odigbo ti de ijọba ibilẹ Irele bayii nibi ti a gbọ pe eeyan mẹjọ ti ku.

Alaga ijọba ibilẹ Odigbo, Ọgbẹni Taiwo Adegoroye, ti sọ ṣaaju wi pe eeyan mẹjo lo ku ni Araromi-Obi nigba ti eeyan mẹrindinlogun jade laye ni Odigbo.

Amọ, awọn to ti ku bayii ti di mọkadinlaadọta gẹgẹ bi iroyin to jade nirọlẹ ana Ọjọru.

Kọmiṣọna fun eto ilera nipinlẹ Ondo, Dokita Banji Ajaka, naa fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan ti ọti naa ti ṣakoba fun tun ti pọ si i.

Dokita Ajaka ni ọpọ eeyan ni ọti yii ṣẹṣẹ sẹkupa nijọba ibilẹ Irele; o fikun ọrọ rẹ pe eeyan mẹjọ lo ku lalẹ ọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii.

Ìjọba fi fòfin de títa ọtí tí kò bá ní nọ́mbà NAFDAC lára l'Ondo

Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Ondo fofin de tita gbogbo oniruuru ọti lile ati awọn miran to n gba ẹnu wọle sinu ara, eyi ti ko ba ti ni ontẹ ajọ to n ṣakoso ounjẹ ati oogun lilo, iyẹn NAFDAC.

Igbesẹ yii lo waye lẹyin iku awọn ti ko din ni ọgbọn, to waye laipẹ yii nipinlẹ naa.

O ni ida marundinlaadọrun awọn ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si ni wọn jẹ ọkunrin ti wọn wa laaarin ọdun mẹrindinlogun si marundinlọgọta.

Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe awọn agbegbe bii Orita Odigbo, Araromi-Obu, Newtown, Odole, Okele ati Oniparaga ni iṣẹlẹ naa ti waye.

Ajaka tun fi kun ọrọ rẹ pe awọn aisan bii ori fifọ, ara riro, irẹwẹsi ara, ailẹ min daadaa ati awọn miran lo jẹyọ lara awọn eeyan naa.

O ni ọrọ ilera awọn miran tete yiwọ patapata, leyi to ṣokunfa iku wọn laarin wakati perete.