Ìdí rèé tí mo ṣe kọ̀ láti polongo ìbò fún APC ní Eko - Toyin Abraham

Toyin Abraham wọ aṣọ alawọ esuru, we gele, o n wo iwaju lai rẹrin-in

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbajumọ oṣere tiata, Toyin Abraham ti ṣalaye idi ti to ṣe kọ bi wọn ṣe forukọ rẹ sara awọn oṣere ti yoo polongo ibo fun ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni ipinlẹ Eko.

Ninu atẹjade to fi soju opo X rẹ lọjọ Ẹti, Toyin Abraham sọ pe kii ṣe nitori awọn to n bu oun lori ayelujara ni oun ṣe kọ ipo naa nitori awọn eeyan ori ayelujara kọ ni wọn maa ṣe ipinnu fun oun.

O ni oun kọ ipe naa nitori wọn ko sọ ohunkohun fun oun ki wọn to forukọ oun si ara awọn to maa polongo ibo.

O sọ pe oun ti sọ ọ ṣaaju pe oun ko ni kopa ninu oṣelu lasiko yii ati pe nnkan to tọ ni oun ṣe nitori oun kan deedee ri orukọ oun lori ayelujara lai ṣe pe ẹnikẹni ba oun sọ nnkankan tẹlẹ.

Ni ọjọru ni atẹjade kan ti gba ori ayelujara eyi to ṣafihan awọn ti yoo maa ṣe ipolongo fun ẹgbẹ oṣelu APC ni ipinlẹ Eko ti orukọ Toyin Abraham ṣi wa nibẹ.

Amọ ko pẹ ti iroyin naa jade ni Toyin Abraham fi ikede sita pe oun ko si lara ikọ ipolongo kankan ati pe oun ko lọwọ ninu oṣelu lasiko yii.

Ẹ o ranti pe Toyin Abraham koju awọn ipenija lori ayelujara nibi ti ọpọ eeyan ti n bu, ti wọn si dẹyẹ sii nitori pe o ṣe atilẹyin fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu nibi eto idibo ọdun 2023.

Ìpinyà láàárín Toyin àti Kolawole? Ohun tí a mọ̀ rèé

Toyin Abraham ati Kolawole Ajeyemi wọ aṣọ otutu. Toyin wa lori iduro o gbe ọwọ le Kolawole to wa lori ijokoo ni ejika.

Oríṣun àwòrán, ToyinAbraham/Instagram

Agba oṣere nni, Toyin Abraham ti sọrọ lori iroyin to n lọ lori ayelujara pe igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, Kolawole Ajeyemi ti tuka.

Ni ọjọru ni ọkan lara awọn to maa n gbe iroyin lori ayelujara, Fatitell Gist kọ soju opo Instagram rẹ pe kudiẹkudiẹ ti n waye ninu igbeyawo Toyin Abraham ati ọkọ rẹ ati pe Toyin ti ko jade nile lọ si ile tuntun kan to ṣẹṣẹ kọ.

O kọ soju opo rẹ naa pe awuyewuye to ṣi n lọ labẹnu ni iroyin naa ati pe eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Bukky Jesse lo kọkọ gbe iroyin naa sita pe aarin Toyin ati ọkọ rẹ ko danmọran mọ.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Amọ Toyin Abraham ti wa fesi si ahesọ ọrọ naa pẹlu esi to fi sabẹ iroyin ti Fatitell Gist gbe sita naa.

Toyin kọ sabẹ iroyin naa pe "a kọ lorukọ baba, ọmọ ati ẹmi mimọ, ori wa kọ ọ, ẹlẹdaa wa kọ ọ."

Esi Toyin Abraham ṣafihan pe ahesọ ọrọ lasan ni iroyin ati pe irọ to jina si ootọ ni pe igbeyawo wọn n koju wahala tabi pe awọn mejeeji ti pinya.

Agba oṣere naa tun kọ pe ipinya ko si ninu irinajo oun ati ọkọ oun nitori oun ko gbadura fun ituka laaarin oun ọkọ oun ati pe oun n fi adura jagun fun idile naa.

Igba akọkọ kọ niyi tawọn tọkọtaya naa yoo ma kojun irufẹ iroyin bayii.

Ọpọ igba ni wọn ti gbe iroyin pe igbeyawo Toyin ati ọkọ rẹ, ti oun naa jẹ agba oṣere, ti fori ṣọpọn ṣugbọn ti awọn ololufẹ mejeeji yoo tako iroyin bẹẹ.

Ni ọdun 2019 ni Toyin ati Kolawole ṣe igbeyawo ranpẹ ni ilana ibilẹ lẹyin ti awọn mejeeji ti ṣe ọrẹ fun ọpọ ọdun lagbole ere sinima Yoruba.

Lẹyin igbeyawo naa ni tọkọtaya ọhun bi ọmọ ọkunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Ire.

Ṣaaju igbeyawo naa ni Kolawole ti bi ọmọbinrin kan eyi ti Toyin maa n pe ni akọbi rẹ, to si maa n sọ pe ọmọ meji ni Ọlọrun fi kẹ igbeyawo awọn.