Ọdún mẹ́tàlá lo fi báwa gbé, a máa ṣàfẹ́kù rẹ -Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí kọrin arò lẹ́yìn tí ajá a rẹ̀ jáde láyé

Aja dudu duro, o si yọ ahọn dinu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aja aarẹ orilẹede Amẹrika tẹlẹ, Barack Obama, ti orukọ rẹ n jẹ Sunny ti jade laye lẹni ọdun mẹtala.

L'Ọjọru ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kẹsan an yii ni Obama kede iku Sunny loju opo X rẹ.

Aarẹ Amẹrika tẹlẹ kẹdun loju opo X rẹ pe ''a ti padanu ọkan pataki ninu ẹbi wa.''

Obama ṣapejuwe aja naa bi ẹni to ṣe fi ọkan tan, eyi to maa n duro ti ẹbi oun nigba gbogbo.

Ó di gbéré! A ti pàdánù ọ̀kan pàtàkì nínú ẹbí wa - Ààrẹ tẹ́lẹ̀rí ṣèdárò ajá rẹ̀ tó kú

Irufẹ aja Portuguese Water Dogs meji ni ẹbi Obama ni nile ijọba Amẹrika White House lasiko to wa lori oye gẹgẹ bi aarẹ Amẹrika.

Nigba ti Obama wọle saa keji lọdun 2013 ni ẹbi rẹ ra Sunny.

Oniruuru awọn alejo lati ilẹ okeere lo ba aja yii to n jẹ Sunny ni ileeṣẹ aarẹ Amẹrika nigba naa to fi mọ Papa Mimọ tẹlẹ Pope Francis.

Ọdun 2009 ni ẹnikan fun awọn ọmọbinrin Obama, Sasha ati Malia lẹbun aja keji wọn ti wọn n pe ni Bo.

Aja yii ṣeranwọ fun ẹbi Obama lati jẹ ki ara wọn mọle nileeṣẹ aarẹ, amọ, ọdun 2021 ni Bo jade laye.

Aarẹ Amẹrika tẹlẹ sọ pe ni kete ti Sunny wọ inu ẹbi oun ni gbogbo awọn fẹran rẹ.

Obama sọ pe Sunny jẹ aja kan to lagbara gidi gan an nigba aye rẹ.

Sunny jẹ aja kan to fẹran ki ẹbi Obama maa wa pẹlu rẹ ni gbogbo igba.

O fẹran lati maa sun silẹ ki eeyan si maa fi ọwọ ra inu rẹ fun igba pipẹ.

''Ẹbi wa yoo ṣafẹri Sunny gan an, amọ, o ti lọ darapọ mọ buọda rẹ, Bo to kọkọ ku''

''Sunny fẹran awọn ọmọbinrin wa, ni ṣe ni wọn maa n fọwọ ra a nikun lati ba a ṣere.

Aja yii fẹran ẹbi wa pupọ, o maa n tẹle wa kaakiri, o si tun maa n ṣeranwọ fun wa lẹnu iṣẹ.

Sunny maa n pariwo, kii si i fẹ ki omi da si i lara rara, koda; iwọnba omi diẹ lo maa n mu.

Fun ọdun mẹtala lo maa n fi wa lẹgbẹẹ wa, o si roro titi ti o fi jade laye,'' Obama ṣalaye.

Obama ni ẹbi oun yoo ṣafẹri Sunny gan an, amọ, aarẹ Amẹrika tẹlẹ naa sọ pe o ti lọ darapọ mọ buọda rẹ, Bo.

Sunny maa n wa nibi oriṣiiriṣii ipade ni White House, bakan naa lo tun maa n bawọn ọmọde ṣere lasiko ọdun Keresimesi.

Ayaworan nileeṣẹ aarẹ tẹlẹ, Pete Souza, sọ pe nnkan iwuri lo jẹ foun wi pe oun ṣiṣẹ pọ pẹlu Sunny.

Souza ni ara ọtọ ni Sunny jẹ tori o jẹ aja kan ti aarẹ Amerika ati Papa Mimọ ba ṣere.

Ohun ọsin jẹ nnkan to wọpọ nileeṣẹ Aarẹ Amẹrika, amọ, Aarẹ Donald Trump nikan ni igbagbọ wa pe ko ni nnkann ọsin kankan nileeṣẹ aarẹ ni nnkan bii ọgọrun un ọdun sẹyin.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post