Àwọn afurasí márùn-ún tó jí akẹ́kọ̀ọ́ Oyo gbé láwọn kò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n nilé-ẹjọ́

Awọn afurasi tọwọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS tẹ ree, aworan keji ni ti awọn akẹkọọ ati olukọ ti wọn jigbe lasiko ti wọn gba itusilẹ

Oríṣun àwòrán, AGF/XBayo Onanuga/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Gbogbo awọn afurasi tọwọ tẹ lori ijinigbe Oriire nipinlẹ Oyo lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026 ni wọn ti sọ niwaju ile-ẹjọ wi pe awọn ko jẹbi ẹsun ti ajọ ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fi kan wọn.

Ẹsun meje ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ijinigbe ati ifiyajẹni lọna ni ajọ DSS fi kan awọn maraarun-un niwaju ile-ẹjọ lorukọ ijọba apapọ.

DSS ni, awọn afurasi naa jẹ ọmọ ẹgbẹ Jama'atu Ansarul Muslimina fi-Biladis Sudan (ANSARU), eyi ti wọn pe ni ẹgbẹ janduku agbebọn aṣekupani.

Alakoso ajọ DPP nilẹ Naijiria, Rotimi Oyedepo to lewaju ikọ amofin DSS, ti kọwe lati bẹrẹ ẹjọ awọn afurasi naa ṣaaju, lai fi akoko ṣofo, ni ibamu pẹlu ofin ọdaran ti ọdun 2015.

Bakan naa lo tun rọ ile-ẹjọ lati gba awọn tọrọ naa kan, ti wọn jẹ ẹlẹri laaye lati jẹri si iṣẹlẹ naa, nipa bibo oju wọn lasiko igbẹjọ.

Igbesẹ yii ni lati daabo bo awọn ẹlẹri naa, ko ma ba a di pe wọn yoo tun lọ ṣe ikọlu si wọn nigba ti wọn ba de ile.

Niwọn igba ti agbẹjọro awọn afurasi naa ko ti tako ẹbẹ yii, loju ẹsẹ ni Onidajọ Salim Ibrahim ti fontẹ lu u.

Kí ló wà nínú ìwé ẹ̀sùn náà?

Gẹgẹ bi ẹsun naa ti wọn ti ṣe agbeyẹwo rẹ ṣe ṣalaye, o ni Mahmud Muhammad ati Abubakar Abbas lo paṣẹ fun awọn mẹta yooku lati maa ji awọn eeyan gbe, ki wọn si maa pa awọn eeyan kaakiri Naijiria, ko to di pe ọwọ tẹ wọn.

Iwe ẹsun naa sọ pe aṣẹ yii lo fa bi wọn ṣe lọ ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe lawọn ile-ẹkọ to wa nijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo.

Bakan na ani wọn tun fẹsun ipaniyan kan awọn afurasi wọnyi, ti wọn si lawọn lo pa awọn olukọ meji, Oyedokun ati Olaleye.

"Wọ́n fìyà jẹ wá"

Ọkan lara awọn ẹlẹri ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ si, ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa bi ijinigbe naa ṣe waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026.

Ẹlẹri naa sọ pe awọn akẹkọọ ati olukọ ti ko din ni mọkandinlaadọta ni awọn ajinigbe ọhun jigbe wọnu igbo lọ fun ọjọ mẹrindinlọgọta.

O fi kun ọrọ rẹ pe abẹ ibanujẹ ati iporuru ọkan ni wọn wa lahaamọ, pẹlu oniruuru ifiyajẹni ti ko ba ileri gidi mu.

Siwaju sii lo ni ẹsẹ lasan ni awọn fi rin lọ si agbegbe mẹfa ọtọọtọ, to si jẹ pe ori koriko ni awọn n sun si, ninu ojo ati ninu oorun, ko to di pe awọn eleto aabo gba wọn jade.

O ni ọkada mejila ni awọn agbesunmọmi ọhun gbe wọle nigba ti wọn wa ji wọn gbe, ti wọn si n yinbọn lakọlakọ, lati ma jẹ ki awọn olukọ ati akẹkọọ salọ.

O ni eeyan mẹrin-mẹrin ni wọn gbe sori ọkada kọọkan, ti wọn si tun lo ọkọ ọkan lara awọn olukọ lati fi gbe awọn yooku wọnu igbo lọ.

Ìgbẹ́jọ́ n tẹ̀síwájú lónìí

Lẹyin o rẹyin, ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ki igbẹjọ tẹsiwaju lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2026.

Àwọn afurasí márùn-ún tó jí akẹ́kọ̀ọ́ Oyo gbé yóò tún fojú ba ilé-ẹjọ́ lónìí

Mẹta ninu awọn afurasi tọwọ tẹ ree

Oríṣun àwòrán, Attorney-General of the Federation (AGF)

Lonii ni ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ, DSS yoo foju gbogbo awọn afurasi tọwọ tẹ lori ijinigbe awọn olukọ ati akẹkọọ nijọba ibilẹ Oriire, ipinlẹ Oyo.

Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Karun-un, ọdun 2026 ni awọn janduku agbebọn ṣe ikọlu si awọn ile-ẹkọ bii mẹta, ti wọn si ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe, nibi ti wọn ti pa olukọ meji danu.

Fun bi ọjọ mọkanlelaadọta ni awọn olukọ ati akẹkọọ naa lo ninu igbekun awọn ajinigbe yii, ko to di pe wọn ri itusilẹ gba.

Ile-ẹjọ giga tijọba apapọ to wa niluu Abuja ni awọn afurasi naa yoo ti sọ tẹnu wọn, lori ẹsun mẹfa ti ajọ DSS fi kan wọn ninu ẹjọ nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CR/438/2026.

Ẹjọ naa ti Rotimi Oyedepo to jẹ alakoso agba nileeṣẹ to n ri sọrọ ifiyajẹni labẹ ofin, gbe dide lorukọ ijọba apapọ lo ti darukọ awọn afurasi naa.

Mahmud Muhammad, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Bara'a ati Abbas Mukhtar; Abubakar Abbas, ti wọn n pe ni Isah Adam ati Mallam Mahmuda Al-Nigeri; to fi mọ Abdulrazak Umar, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Khalifa ati Abu Khalid.

Awọn meji yooku ni Yunusa Musa, ti inagijẹ rẹ n jẹ Abu Yunusa Bin Musa; ati Shamsu Adamu Sani, ti inagijẹ tiẹ naa n jẹ Abu Itisar.

Kí ló ṣẹlẹ̀ ṣáájú?

Ọjọru, ọsẹ yii ni awọn afurasi naa foju bai le-ẹjọ, ṣugbọn ti ọrọ pada yiwọ nigba ti agbẹjọro kan dide lati tẹsiwaju nipa gbigba ẹnu sọ fawọn maraarun-un.

Igbakeji alakoso agba ni ajọ 'Legal Aid Council', Akilaluyel Shettima, lo fi ara rẹ han lati duro ṣoju awọn afurasi maraarun-un, nigba ti igbẹjọ naa bẹrẹ niwaju Onidajọ Saliu Ibrahim.

Ṣugbọn niṣe ni Muhammad dide lati tako igbesẹ naa, to si jẹ ko di mimọ pe agbẹjọro Bala Dakum to n gbẹnusọ fun awọn tẹlẹ, lawọn fẹ lati maa tẹsiwaju nipa gbigba ẹnu sọ fun awọn.

Muhammad sọ ninu ọrọ rẹ pe, "Bala Dakum ni agbẹjọro to n gbẹnusọ fun wa tẹlẹ, oun naa la ṣi fẹ ko maa gbẹnusọ fun wa."

"Ìpinnu àwọn afurasí bá òfin mu"

Nigba to n sọrọ, agbẹjọro Oyedepo jẹ ko di mimọ pe awọn ti wọn fẹsun kan ni ẹtọ labẹ ofin, si agbẹjọro to ba wu wọn, ti wọn si gbọdọ bọwọ fun un.

Oyedepo sọ fun ile-ẹjọ pe ajọ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS jẹ ajọ to n bọwọ fun ofin, ati pe ko si eyi to kan wọn nipa titako awọn afurasi nile-ẹjọ, bi ko ṣe pe ki idajọ ododo waye.

Idi ree ti Onidajọ Ibrahim fi sun igbẹjọ afurasi naa si oni, Ọjọbọ.

Onidajọ Ibrahim sọ pe ki awọn afurasi naa kan si agbẹjọro Dakum, lati rii daju pe o farahan niwaju ile-ẹjọ.

Bẹẹ lo paṣẹ fun ajọ DSS lati faaye gba awọn afurasi naa lati ri agbẹjọro wọn, lati le palẹmọ ṣe igbaradi ki igbẹjọ too bẹrẹ.