Mo fẹ́ ìyàwó mẹ́rin ni Ilorin, a sì jọ ń lo Ásìkí ara wa- Baba Aremu Alapata

Baba ẹni ọdun mewaa le ọgọrun, Abdulkadri Aremu ni bi oun se di eni to di iyawo mẹrin ọtọọtọ ko seyin pe nnkan rọrun pupọ fun oun nigba ti oun di eni to ni iyawo mẹrin ju asiko ti oun ni iyawo kan lọ.
Aremu ni oun gbagbọ oun ati awọn iyawo oun merin jọ n lo arísìkí ara wọn ti nnkan ti rọrun fun wọn titi di asiko yii.
Ti kò bá ki n ṣe ọ̀rọ̀ Islam, n bá fẹ́ ju ìyáwò mẹ́rin lọ:- Alhaji Abdulkadri ile Mogaji ni Ilorin, nipinlẹ Kwara
Láti jẹhun pẹlu iyawo kan ti Baba mi fẹ́ fun mi nira púpọ̀; ìgbà ti Iya mi fẹ iyawo keji tun jẹ ko rọrun díẹ̀ síi fun mi, ayafi igba ti mo fẹ ìyàwó kẹta lo wa rọrun sii fun mi-Alapatà Abdulkadir
Lẹyin ti Alhaja Adijatu Aremu ti gba iyawo mẹta, o ni pe:- Mo gba Orogun bii tọmọtiya nitori pe ẹsẹ gbogbo wọn dara nile ọkọ mi ni eyi ti nkan fi rọ mi lọrun sii..
Awawu Aremu:- Emi niyawo kẹrin ti Alhaji fẹ gbẹyin, N ko ya ounjẹ latigba ti mo ti wọle, ẹran ni èmi náà n tà. Ti a ba ja bayii, wọn a pari ẹ fun wa naa ni. Ko si iyọnu nitori pe Mo tẹriba fun awọn Iya ni.



