Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo lò nínú ìgbéyàwó mi àkọ́kọ́ tí ń kò sì rí ọmọ bí níbẹ̀-Toyosi Adesanya
Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ni mo lò nínú ìgbéyàwó mi àkọ́kọ́ tí ń kò sì rí ọmọ bí níbẹ̀-Toyosi Adesanya
Published
Ninu alaye ti Toyosi Adesanya to jẹ ọkan gboogi ninu ẹgbẹ oṣere TAMPAN lapapọ ṣe fun BBC News Yoruba lo ti sọ pe
Gẹgẹ bo ṣe wi lasiko ifọrọwerọ pẹlu BBC:
''Ẹẹmarun-un ni mo ṣiṣẹ abẹ lọdun 2022 nitori mo n wa ọmọ. Nigba to de asiko kan, dokita gan an sọ fun mi pe o to gẹẹ.''
Toyosi ni wiwa ọmọ ati riri ọmọ wa lọwọ Ọlọrun.
O sọ ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba pe gbogbo ọna ti eeyan maa fi n wa ọmọ ni oun gba fi wa ọmọ.
Toyosi ni loootọ loun ko jọ iṣoro airọmọbi toun la kọja, nitori oun ni igbagbọ pe Ọlọrun yoo sọ oun di ọlọmọ lọjọ kan.
Gbajumọ oṣere naa ni ''Mo gbagbọ pe ayọ gbogbo awọn to n woju Ọlọrun fun ọmọ naa yoo de bi ayọ temi naa ṣe de.''



