Ìjọba APC kò pèsè iná la ṣe ń fowó ra epo tanná sí títì- Seyi Makinde dá a padà fún Sharafadeen Alli

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ Seyi Makinde.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Jiju oko ọrọ lura ẹni to n waye laaarin Gomina Seyi Makinde ati Sẹnetọ Sharafadeen Alli to n dupo gomina ninu ẹgbẹ APC ipinlẹ Oyo ṣi n tẹsiwaju.

Igun Seyi Makinde ti ni ai mu adehunṣẹ ẹgbẹ APC nipa ipese ina lo fa a ti ijọba ipinlẹ Oyo ṣe n fowo ilu ra epo si jẹnẹretọ to n tan ina soju popo kiri.

Ẹ o ranti pe igun Sharafadeen Alli lo fesun yii kan Seyi Makinde, lẹyin ti gomina naa sọ pe lọya ti ko de kootu ri ni Alli n ṣe.

"Ilakaka Alli lati di gomina ko le pana itẹsiwaju ipinlẹ Oyo"

Ninu atẹjade ti Ọmọwe Sulaimon Olanrewaju, Oludamọran pataki fun Gomina Makinde nipa iroyin fi sita lọjọ Abamẹta lo ti ni:

"Ariwo ti ikọ ipolongo yii n pa kiri lọwọ yii ti fi han pe oṣelu wọn ti mu dandan dani, o si han pe wọn fẹẹ fipa fi ara wọn han ni.

"Nipa ọrọ ina ojuu popo, ijọba Makinde ko ni I tọrọ aforiji laye fun pe o n tanna sipinlẹ Oyo, o si n wa aabo rẹ.

"Idi kan ṣoṣo ta a fi n lo jẹnẹretọ ni pe ijọba apapọ ti APC n dari , ẹgbẹ Sẹnetọ Sharafadeen Alli, ti kuna lati pese ina ọba to duro deede ti wọn ṣeleri fawọn ọmọ Naijiria.

"Bi opo to gbe ina ọba duro kaaakiri Naijiria ba duro deede ni, ko ni I si idi kankan lati maa lo jẹneretọ to n lo disu.

"O yẹ ki Sẹnetọ Alli koju ẹgbẹ rẹ fun iwa ibanilojujẹ ti wọn n hu lẹka ina ọba".

"A ti tun Papa iṣere Lekan Salami ṣe, o foju han kedere"

Nipa ẹsun keji ti i ṣe kikuna lati tun papa iṣere Lekan Salami ṣe, eyi ti APC fi kan ijọba Makinde, igun gomina naa tun da a pada pe:

"Atunṣe to waye nibẹ ti jẹ ki ohun ti iṣakoso to kọja ko le ṣe jẹ ṣiṣe bayii.

"Ibadan ti n gbalejo awọn ifẹsẹwọnsẹ onilu-siluu, titi kan idije Falconets ati Senegal oṣu Keji ọdun 2026."

Atẹjade naa sọ pe ijọba sinmi diẹ fun awọn idije agbaye 3SC ki wọn le tun papa naa ṣe si I bii ti agbaye ni.

"Inu lo n bi Senato Sharafadeen Alli, nitori ododo ti Makinde sọ pe jẹkurẹdi lọya ni.

"Eyi ki i ṣe eebu, ootọ ọrọ ni, ooto si maa n ja eeyan jẹ nigba ti wọn ba tu aṣiri ọlọdun pipẹ ni."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa wi.

O tun sọ pe Onimọẹrọ to ni apọnle ni Seyi Makinde, to bẹẹ ti ẹgbẹ awọn onimọ ẹrọ Naijiria ka a yẹ pẹlu ami ẹyẹ ọkan lara wọn.

Ijọba Makinde ko raye ẹjọ wẹwẹ bi atẹjade yii ṣe wi, wọn ni iṣẹ itẹsiwaju ipinlẹ Oyo lo gbe dani.

Lọ́yà tí ò dé kóòtù rí: Sharafa Alli fèsì, ''Ẹnjiníà tó fi N250bn owó ìlú ra epo sí jẹnẹrétọ̀ faná sí títì ni Makinde''

Ṣenetọ Sharafadeen Alli lapa osi, o de fila ẹgbẹ oṣelu APC o si wọ agbada alawọ aro, o mu ẹrọ gbohun-gbohun dani. Gomina Seyi Makinde lapa ọtun, o wọsọ alawọ aro pẹlu fila ẹgbẹ oṣelu APM rẹ.

Oríṣun àwòrán, Senator Sharafadeen Alli/Facebook/ Gov. Seyi Makinde/Facebook

Isọrọ ni'gbesi.

Igun Sẹnetọ Sharafadeen Alli, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Oyo ti da esi ọrọ ti Gomina Seyi Makinde sọ nipa oludije sipo gomina Oyo naa pada fun un.

Ẹ o ranti pe lọjọ Ẹti ni Gomina Seyi Makinde pede to taba Sharafadeen Alli, nigba to ni lọya ti ko dele ẹjọ ri laye rẹ ni.

Makinde tun ṣalaye bawọn eeyan to n ba ṣejọba ṣe dangajia to, to si ni to ba wu awọn eeyan Oyo, ki wọn lọ dibo fun ẹni to pe ara rẹ ni lọya ti ko ṣe ẹjọ kankan ri.

Lọjọ keji ti i ṣe ọjọ Abamẹta ni ikọ to n polongo ibo fun Sharafadeen Alli da a pada fun Makinde pe:

"Aimọkan ati inunibini lo n ṣe Ẹnjinia to fi N250bn ra epo si jẹnẹretọ fana sojuu popo"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu atẹjade ti ẹgbẹ to n polongo ibo fun Alli fi sita lati ọwọ Adari ikede wọn; Bisi Oladele, ni wọn ti sọ pe ọrọ ẹnu Makinde fi aimọkan ati inunibini han.

"Makinde wulẹ kede aimọkan ati inunibini rẹ ni, nitori o ti han kedere pe Alli lawọn eeyan n ba lọ ni 2027.

"Ẹnjinia to ti na ju N250bn lati ra disu si jẹnẹretọ to n tanna si oju popo."

Lori iṣẹ lọya ti Makinde sọ pe Alli ko ṣe ri, ikọ to n ṣatilẹyin fun Alli sọ pe irọ gbuu ni.

"Ọdun 1987 ni Alli bẹrẹ iṣẹ lọya gẹgẹ bii agunbanirọ pẹlu A. E. Enumah & Associates,ni Nnewi, ipinlẹ Anambra.

"Ibẹ ni wọn ti kọkọ gba a siṣẹ nitori o mọṣẹ daadaa, awọn obi rẹ lo ni dandan ko ṣaa maa pada bọ n'Ibadan,ki wọn le maa ri i nilẹ Yoruba."

Atẹjade naa sọ pe lodi si ohun ti Makinde fi aimọkan sọ, wọn ni Alli ki I ṣe lọya oniṣẹ kan, bi ko ṣe akọṣẹmọṣẹ agbẹjọrọ.

Atẹjade naa ko ṣai ka ọpọ ileeṣẹ ti wọn ni Sharafadeen Alli ti ṣiṣẹ amofin ri, koda laye Western Region, titi di 1991 ti wọn yan an sipo Alaga akọkọ fun ijọba ibilẹ Ariwa Ibadan.

"O da ileeṣẹ agbẹjọrọ tirẹ to pe ni Biodun Alli & Co silẹ n'Ibadan ni 1994, bẹẹ lo si ṣiṣẹ kiri."

Bi ẹnikẹni ba fẹẹ wadii ijẹlọya tootọ Sharafadeen Alli, atẹjade naa sọ pe akọsilẹ rẹ wa lọdọ awọn ẹgbẹ agbẹjọro ni Naijiria (Nigerian Bar Association),ẹka tilu Ibadan. Bakan naa ni wọn lo tun wa lọdọ ajọ to n fi orukọ ileeṣẹ silẹ (Corporate Affairs Commission).

Awọn ẹsun ti wọn fi kan Onimọẹrọ Seyi Makinde

Gẹgẹ bi APC Oyo ṣe koju Onimọẹrọ Seyi Makinde ninu atẹjade naa, wọn ni o ṣe ni laanu pe bi Gomina yii ṣe kẹkọọ nipa Ina mọnamọna to, ko ri ọna abayọ si iṣoro ina to ṣe soju popo.

Owo ipinlẹ Oyo to N400bn ni wọn ni Makinde fi gbe ina ọhun ro kiri.

Owo ilu ni wọn lo fi n ra epo ti wọn fi n tan awọn ina ọhun pẹlu ẹrọ amunawa ti a mọ si jẹnẹretọ.

Eyi n pa ilu lara nipa inawo nikan kọ, bi ko ṣe pe o tun n mu ewu ba ẹmi araalu pẹlu ni APC Oyo sọ.

APC Oyo sọ pe bi ko ba ṣe pe Makinde fẹ fi owo ilu ṣararindin, ki lo de to ba ina solar ti ijọba to kuro nipo fi silẹ jẹ.

Wọn ni dipo ko tun wọn ṣe tabi ko sọ wọn di ti igbalode si I, niṣe lo ba wọn jẹ.

"Bakan naa lo kọ lati tun papa iṣere Lekan Salami to wa, l'Adamasingba, n'Ibadan ṣe lẹyin ti ajọ CAF ti gba pe ki ẹgbẹ agbabọọlu Shooting Stars Sports Club gbalejo idije nibẹ.

"Lẹyin owo to ju N5bn lọ, papa iṣere naa ko ri atunṣe, ko si le gbalejo idije orilẹede kiri.

"Ki wa ni Gomina Makinde tunṣe? Awọn wo lo fọwọ si i pe o ti daa? Ki lo de ti Shooting Stars fi gbọdọ maa wa ibomi-in lati dije bii Abeokuta, nipinlẹ Ogun lẹyin tawọn eeyan ipinlẹ Oyo ti fi owo ori sisan tun ti wọn ṣe?

Eyi atawọn nnkan mi-in bẹẹ ni APC Oyo fi koju Gomina Seyi Makinde.

Wọn ni ironu Ikoko ni yoo pa aja ni ọrọ Sharafadeen Alli jẹ fun un, iyẹn lo jẹ ko maa sọ ohun ti ko ri bẹẹ lọrọ.

Kí ló ṣẹlẹ̀ tí Seyi Makinde ń pe Sharafadeen Alli ní lọ́yà tí ò dé kóòtù rí? Àlàyé rèé

Gomina Seyi Makinde lapa osi, o wọsọ alawọ aro, o si de fila pupa, o fi igo soju. Sẹnetọ Sharafadeen Alli lapa ọtun, oun naa wọsọ alawọ aro, o de fila alawọ kan naa.

Oríṣun àwòrán, Gov. Seyi Makinde/ Facebook/ BBC

Gomina ipinlẹ Oyo, Onimọẹrọ Seyi Makinde, ti ju ogulutu ọrọ lu oludije sipo gomina ipinlẹ Oyo ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Sharafadeen Alli, bii idibo ọdun to n bọ ṣe n sunmọ etile.

Ọrọ nipa kikun oju oṣunwọn, iṣẹ ti wọn gbe dani ati bi kaluku ṣe dangajia to lo fa a ti oko ọrọ fi bọ lati ẹnu Makinde si Sharafadeen.

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Gomina Seyi Makinde ti saa rẹ nipo gomina Oyo yoo kasẹ nilẹ lọdun to n bọ ti kede ipinnu rẹ lati dupo aarẹ Naijiria ninu ẹgbẹ oṣelu APM ni 2027.

Bẹẹ si ni Sẹnetọ Sharafadeen Alli to n ṣoju Guusu ipinlẹ Oyo naa n gbe igbesẹ lati di gomina ipinlẹ naa lọdun to n bọ, ninu ẹgbẹ oṣelu APC.

Amọ lọjọ Ẹti to kọja yii, lasiko ti Makinde n ṣalaye awọn iṣẹ to ṣe nipo gomina ati bawọn eeyan to n ba a ṣiṣẹ ṣe kaju ẹ si, o sọrọ ti ọpọ eeyan gba pe Sẹnetọ Alli lo n ba wi.

Makinde to ṣẹṣẹ pada sẹnu iṣẹ lẹyin isinmi ọlọdọọdun rẹ sọ pe:

"Ẹyin naa ri ikọ to duro niwaju yin. Onimọẹrọ ni mi, ọmọ ẹgbẹ awọn Onimọẹrọ lorilẹede Naijiria.

"Agbẹjọro ni Adele gomina, o si tun ti jẹ olootu idajọ ri. Ọjọgbọn onimọ nipa ọrọ aje ni Akọwe ijọba, Ọmọwe ni olori oṣiṣẹ.

"Awọn mọkanla to wa nipo akọkọ ninu wa la mu wa sipinlẹ Oyo.

"To ba dẹ wa wu yin, tẹ ẹ lọọ dibo fẹni to sọ pe lọya loun ti o de kootu ri. Ẹ jẹ ko darukọ ẹjọ kan to ṣe ri."

Bi Gomina Makinde ṣe sọrọ yii ni ọpọ eeyan ti bẹrẹ si i gbe e kiri pe Sharafadeen Alli lo n ba wi.

Amọ Makinde ko dakẹ sibẹ, o tun ni ki alatako oun waa tọka aṣeyọri rẹ kankan to ti ṣe, pẹlu awọn ohun to tiẹ fẹ ṣe fawọn eeyan ipinlẹ Oyo.

O ni oṣelu ki i ṣe nnkan awada, akọ iṣẹ ni.

Makinde sọ pe kadara ọpọ eeyan lo rọ mọ oṣelu, ki i ṣe ibi ere rara.