Ododo kéde ọjọ́ mẹ́ta láti kẹ́dùn Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀ Ibrahim Idris tó doólògbé

Usman Ododo, Yahaya Bello ati oloogbe Ibrahim Idris

Oríṣun àwòrán, Onogwu Muhammed/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Kogi, Ahmed Usman Ododo, ti kede ọjọ mẹta lati kẹdun gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ibrahim Idris to jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin.

Ododo tun paṣẹ wi pe ki wọn gbe asia orilẹede Naijiria ati ti ipinlẹ Kogi walẹ ni gbogbo ọfiisi ileeṣẹ ijọba lati le bu iyi fun oloogbe naa.

Ṣaaju ni Gomina Ododo ti ṣabẹwo si ẹbi oloogbe lati kẹdun pẹlu wọn.

Gomina ipinlẹ Kogi sọ ninu ọrọ ikẹdun rẹ pe iku ti mu ọkan pataki ninu awọn ọmọbibi ipinlẹ Kogi lọ.

Ododo tun kede wi pe ijọba ni yoo ṣeto isinku gomina tẹlẹ naa.

''Alhajii Idris sin ipinlẹ Kogi laarin ọdun 2003 si 2011, o si mu idagbasoke ba ipinlẹ Kogi lasiko rẹ.

Ijọba Gomina Idris pese ohun amayedẹrun, eto ẹkọ to ye koororo, eto ilera to mọyan lori atawọn nnkan mere mere mii fun araalu lasiko rẹ,'' Ododo lo sọ bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Kogi sọ pe awọn eeyan ipinlẹ naa ko le gbage oloogbe ọhun laelae fun iṣẹ ribi ribi ti o ṣe.

O wa rọ awọn ẹbi rẹ pe ki wọn tu ara wọn ninu pẹlu oriṣiiriṣii nnkan rere tawọn eeyan fi n ranti Alhaji Idris.

O ni asiko yii tun n ran awọn eeyan leti nipa igbe aye oloogbe eyi ti o fi sin ilu, nigba ti o wa ni ijọba.

Ododo wa gbadura wi pe ki Eledua pa aṣiṣe gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ naa rẹ, ki o si tẹ ẹ si afẹfẹ rere.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀ Ibrahim Idris jáde láyé lẹ́ni ọdún 77, Ododo, Bello, Natasha ń ṣèdárò

Oloogbe Ibrahim Idris wọ agbada funfun pẹlu fila

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Idris

Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ ri, Alhaji Ibrahim Idris, ti jade laye.

Ogunjọ oṣu Kẹsan an ọdun yii ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe Alhaji Idris jade laye lẹni ọdun mẹtadinlọgọrin lorilẹede UK.

Ẹwẹ, Gomina ipinlẹ Kogi, Ahmed Usman Ododo, Yahaya Bello to jẹ gomina ipinlẹ naa tẹlẹ atawọn alẹnulọrọ mii lagbo oṣelu ti ṣabẹwo sile oloogbe l'Abuja lati kẹdun pẹlu ẹbi rẹ.

Oludamọran gomina Ododo lori ibaṣepọ pẹlu araalu, Onogwu Muhammed to jẹ akọwe iroyin tẹlẹ fun Gomina tẹlẹ ri, Yahaya Bello lo sọ loju opo Facebook rẹ nipa abẹwo awọn eeyan naa sile oloogbe l'Abuja.

Muhammed sọ loju opo ayelujara rẹ pe ''Gomina Usman Ododo, Gomina tẹlẹ ri Yahaya Bello, CON, kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Abdullahi Bello atawọn abẹnugan lagbo oṣelu mii ti de sile oloogbe Gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ ri, Ibrahim Idris to jade laye lọsan ọjọ oni ọjọ Aiku.''

Idris jẹ gomina ipinlẹ Kogi laarin ọdun 2003 si ọdun 2012, Idris Wada lo gori aleefa gẹgẹ bii gomina lẹyin rẹ.

A ko le sọ pato nnkan to ṣokunfa iku rẹ ni asiko yii.

Sẹnẹtọ to n ṣoju aaringbungbun Kogi, Natasha Akpoti-Uduaghan, naa ti n ṣedaro gomina ipinlẹ Kogi tẹlẹ to doloogbe.

Natasha ni eekan ninu itan ipinlẹ Kogi ati ni ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Idris i ṣe.