Toyin Abraham sọ̀rọ̀ nípa nǹkan mánigbàgbé tó ṣẹlẹ̀ sí i èyí tó gbomi lójú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/Instagram
Gbajugbaja oṣere, Toyin Abraham tun ti sọrọ bi iroyin ṣe n lọ lori ayelujara pe igbeyawo rẹ ati Kolawole Ajeyemi ti tuka.
Toyin tun sọrọ ninu fidio kan to ti tan kalẹ lori ayelujara nipa bi oyun oṣu mẹrin ṣe walẹ ninu rẹ.
Ilumọọka oṣere naa sọrọ yii nibi isin orin Bestie Jesu Concert 2026 to waye niluu Eko lopin ọsẹ to kọja.
Nibi eto naa lo tun ti sọ nipa bi Pasitọ Bolaji Idowu ṣe ṣeranwọ pẹlu owo fun un ti o si tun gbadura fun un pẹlu.
Toyin ni oun wa lori itage nibi ti oun ti n ṣere lọwọ nigba ti oyun naa walẹ.
''Mo ti wa ninu oyun oṣu mẹrin, amọ, oyun naa walẹ, nigba ti mo n ṣere lọwọ ni iṣẹlẹ yii waye.
Ọkan mi poruuru, mi o fẹ pe mama mi tori wọn ti dagba.''
Gajugbaju oṣere naa to tun jẹ olootu ere sọ pe oun sọ fun ọkọ oun nigba naa, amọ, lẹyin naa ni oun sọ fun Pasitọ Bolaji ti alufaa naa si bẹrẹ sii gbadura foun lẹsẹ kẹsẹ.
''Mo sọ fun ọkọ mi, ṣugbọn ibi to wa jinna, bayii ni mo pe Pasitọ Bolaji.
Alufaa Bolaji bẹrẹ sii gbadura fun mi, wọn si beere wi pe nibo ni mo wa?
Mo si dahun wi pe mo wa lọna ile iwosan, wọn tun beere wi pe ki lo n ṣẹlẹ.
Mo sọ fun wọn pe wọn fẹ lọ ko inu mi nile iwosan lẹyin ti oyun ti walẹ lara mi.
Bayii ni Pasitọ Bolaji fi owo to to miliọnu ranṣẹ si mi, mo dupẹ lọwọ yin o, ojiṣẹ Ọlọrun,'' Toyin ṣalaye.
Ti ẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ iroyin ori ayelujara kan ti gbe iroyin kan jade tẹlẹ pe Toyin sọrọ nileeṣẹ tẹlifisan Channels TV lọdun 2022 pe oun sunkun nigba ti oyun bajẹ lara oun tori pe oun fẹ bi ọmọ kan tabi meji si i.
Ìpinyà láàárín Toyin àti Kolawole? Ohun tí a mọ̀ rèé
Ṣaaju ni Toyin Abraham ti sọrọ lori iroyin to n lọ lori ayelujara pe igbeyawo oun ati ọkọ rẹ, Kolawole Ajeyemi ti tuka.
Ni ọjọru ni ọkan lara awọn to maa n gbe iroyin lori ayelujara, Fatitell Gist kọ soju opo Instagram rẹ pe kudiẹkudiẹ ti n waye ninu igbeyawo Toyin Abraham ati ọkọ rẹ ati pe Toyin ti ko jade nile lọ si ile tuntun kan to ṣẹṣẹ kọ.
O kọ soju opo rẹ naa pe awuyewuye to ṣi n lọ labẹnu ni iroyin naa ati pe eeyan kan ti orukọ rẹ n jẹ Bukky Jesse lo kọkọ gbe iroyin naa sita pe aarin Toyin ati ọkọ rẹ ko danmọran mọ.
Amọ Toyin Abraham ti wa fesi si ahesọ ọrọ naa pẹlu esi to fi sabẹ iroyin ti Fatitell Gist gbe sita naa.
Toyin kọ sabẹ iroyin naa pe "a kọ lorukọ baba, ọmọ ati ẹmi mimọ, ori wa kọ ọ, ẹlẹdaa wa kọ ọ."
Esi Toyin Abraham ṣafihan pe ahesọ ọrọ lasan ni iroyin ati pe irọ to jina si ootọ ni pe igbeyawo wọn n koju wahala tabi pe awọn mejeeji ti pinya.
Agba oṣere naa tun kọ pe ipinya ko si ninu irinajo oun ati ọkọ oun nitori oun ko gbadura fun ituka laaarin oun ọkọ oun ati pe oun n fi adura jagun fun idile naa.
Igba akọkọ kọ niyi tawọn tọkọtaya naa yoo ma kojun irufẹ iroyin bayii.
Ọpọ igba ni wọn ti gbe iroyin pe igbeyawo Toyin ati ọkọ rẹ, ti oun naa jẹ agba oṣere, ti fori ṣọpọn ṣugbọn ti awọn ololufẹ mejeeji yoo tako iroyin bẹẹ.
Ni ọdun 2019 ni Toyin ati Kolawole ṣe igbeyawo ranpẹ ni ilana ibilẹ lẹyin ti awọn mejeeji ti ṣe ọrẹ fun ọpọ ọdun lagbole ere sinima Yoruba.
Lẹyin igbeyawo naa ni tọkọtaya ọhun bi ọmọ ọkunrin ti wọn pe orukọ rẹ ni Ire.
Ṣaaju igbeyawo naa ni Kolawole ti bi ọmọbinrin kan eyi ti Toyin maa n pe ni akọbi rẹ, to si maa n sọ pe ọmọ meji ni Ọlọrun fi kẹ igbeyawo awọn.


























