Iran yarí, ó lóun kò sọ pé òun yóò ṣèpàdé jógunómí pẹ̀lú Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lodi si ọrọ Aarẹ America, Donald Trump, pe orilẹede rẹ ati Iran ti ṣetan lati bẹrẹ ipade ti yoo fopin si ogun to n lọ lọwọ lọjọ Aje ọsẹ yii, orilẹede Iran ti ni oun ko figba kan ba Trump sọ ohun to jọ bẹẹ.
Eyi n waye lẹyin ti America dẹkun ikọlu ti wọn ni ko ba le gan-an ka ni awọn ṣe e fun Iran ni.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Aiku ni Trump sọ pe ajọsọ naa yoo bẹrẹ lọsan-an ọjọ Aje.
Bẹẹ lo ti kọkọ sọrọ loju opo ayelujara pe Iran atawọn alajọṣe rẹ lagbegbe Middle East ti ni koun duro na, nitori ẹnu ti ko sibi kan lori ọrọ yii.
Iran ni ọrọ ko ri bẹẹ
Lọjọ Aje ti Aarẹ Trump sọ pe ajọsọ yoo bẹrẹ ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ilẹ okeere ni Iran sọ pe awọn ko ba Aarẹ America dunaa-dura kankan .
Bẹẹ ni wọn ni awọn ko ni eto kankan niwaju nipa a n jokoo sọrọ tabi fẹnuko si pe ki ogun o sin mi na.
Agbẹnusọ wọn, Esmaeil Baghaei, fi kun un pe Tehran lo n ba Oman dunaa- dura lori aabo oju opo Strait of Hormuz.
Trump to ni ipade yoo waye lọjọ Aje ko sọ ibi ti yoo ti waye, bẹẹ ni ko sọ awọn ti yoo wa nibẹ.
Amọ ṣaaju ni Trump ti ni Arẹmọ Saudi Arabia, Mohammed Bin Salman atawọn alajọṣe America bii United Arab Emirates ati Qatar, ti bẹ oun lati ma ṣe kọlu Iran lopin ọsẹ to kọja yii.
Pẹlu gbogbo eyi, Minisita eto aabo fun Iran; Majid Ibn al-Reza, sọ pe ihalẹ agbẹ ni awọn ka idunkooko awọn alatako si, koda bo ba n dun bii iro ogun.
"Wọn o le mu wa lojiji, bẹẹ ni ohun to ṣoju wa ko ni i ṣẹyin wa."
Bẹẹ ni Majid Ibn al-Reza.
Lọjọ Satide to kọja ni Aarẹ Trump ti kọkọ sọ pe oun ṣetan lati kọlu Iran lọna ogun ti ẹnikan ko ri ri latigba ti ogun agbaye keji ti waye.
Amọ o pada yi ọrọ naa pada si pe ijokoo sọrọ asọye yoo waye lọjọ Aje, ki Iran too da a pada pe oun ko jokoo ipade kankan lori ati fopin si ikọlu.
Ṣaa, ohun kan to daju ni pe ogun naa n ni ipa to lagbara lori owo epo lagbaaye latigba to ti bẹrẹ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji ọdun 2026 yii.
Eyi ko ṣẹyin oju opo Strait of Hormuz ti wọn tipa, to si jẹ pe epo ti wọn n lo lagbaaye n gba ibẹ.




























