A máa tọwọ́ bọ̀wé àdéhùn tí yóò parí ogun Iran lọ́jọ́ Àìkú – Donald Trump

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ orilẹede America; Donald Trump, ti kede pe ọjọ Aiku ni America ati Iran yoo tọwọ bọwe adehun kan, eyi ti yoo fopin si ogun ti wọn jọ n ba ara wọn ja.
Yatọ si eyi, Trump kede loju opo ayelujara Truth, pe lẹyin ti ẹnu ba ti ko lori adehun naa, awọn yoo ṣi oju opo Strait of Hormuz to n gbe epo pupọ wọle lẹsẹkẹsẹ.
Amọ bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Trump kede awọn ọrọ yii, Iran ko fi gbogbo ara gba asiko ti aarẹ America naa n dá.
Ṣaaju lọjọ Abamẹta ni Pakistan, orilẹede to jẹ alarena laaarin awọn ilu mejeeji, ti sọ pe o ṣee ṣe ki wọn fẹnuko le adehun naa laarin ọjọ kan pere.
Ki Trump too sọrọ tiẹ ni Agbẹnusọ Iran lori ọrọ ilẹ okeere, Esmaeil Baghaei, ti sọ pe asiko ti Trump n da naa gba afiyesi.
"A maa ni lati duro wo ọjọ gan-an ti itọwọbọwe adehun naa yoo jẹ, bo tilẹ jẹ pe ko le jẹ ọla."
Bẹẹ ni Baghaei wi.
Nipa awọn nnkan agbara ti America n fẹsun rẹ kan Iran pe wọn n ko jọ

Oríṣun àwòrán, Donald Trump
Nigba ti asiko ba to, ti ko si rogbodiyan tabi ogun mọ, Aarẹ Trump sọ pe nigba naa ni awọn yoo lọ ko wọn, awọn yoo si ba a jẹ to ba ya.
Fun ọpọlọpọ ọdun ni awọn orilẹede to ti goke agba, eyi ti America wa lara wọn, ti n fẹsun kan Iran pe o n gbiyanju lati ṣe ado oloro.
Lọpọ igba naa si ni Iran ti ni ko sohun to jọ bẹẹ.
Awijare Iran ni pe oun n gbe awọn nnkan naa kalẹ lati fi pese ina mọnamọna ni, ati fun awọn iṣẹ iwadii.
Lori adehun to fẹ fopin si ogun ti wọn fẹ ṣe yii, Olootu ilẹ Pakistani, Shehbaz Sharif, ti ṣaaju sọ pe:
"Adehun alaafia ti a fẹ ṣe ti sunmọ wa ju ti tẹlẹ lọ".
O ni laaarin ọjọ kan ṣoṣo ni.
Lọjọ Ẹti to kọja yii, Minisita Iran fun ilẹ okeede; Seyed Abbas Araghchi, naa sọ pe adehun kan to fẹ waye pẹlu US ti sunmọle tan.
Adehun naa ni afojusun wa pe yoo fopin si aigbọra ẹni ye laarin Israel ati Hezbollah ni Lebanon bo ṣe sọ.
Araghchi tun sọ fun ileeṣẹ amohunmaworan ijọba Iran, pe adehun naa yoo kan ṣiṣi oju opo Strait of Hormuz, yoo si tun gbẹsẹ kuro lori awọn papakọ Iran ti America ti pa.
Ohun to ti ṣẹlẹ ṣaaju
Ọjọ kejidinlọgbọn oṣu Keji ọdun 2026 yii ni ogun bẹrẹ, nigba ti America ati Israel kọlu Iran, eyi to mu Iran naa da a pada fun won atawọn alajọṣe wọn.
Bakan naa ni wọn ti ọna epo Strait of Hormuz pa, eyi ti i
ṣe ọna kan gboogi ti wọn n gbe epo ati afẹfẹ idana gba lagbaaye.
Ọlọkan -o-jọkan igbesẹ ni awọn ilu tọrọ yii kan ti gbe lati jẹ ki ogun sinmi, amọ gbogbo rẹ ko kẹsẹ jari.
Loṣu Kẹrin ọdun yii ni wọn tun jọ fẹnuko lati jẹ kogun o mi, amọ niṣe ni America ati Iran tun sọko ado oloro sira wọn laaarin adehun naa, eyi ti wọn ṣi tun ju lu ara wọn ninu ọsẹ to kọja yii.
























