Adeleke wọ́ báǹkì First Bank àti EFCC lọ sílé-ẹjọ́ lórí àkáǹtì ìjọba Osun tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé

Gomina Ademola Adeleke tipinlẹ Osun lo mu ẹrọ gbohungbohun dani, to si n sọrọ - Nigba ti alaga EFCC ka ọwọ rẹ mejeeji mọra wọn, to si n wo

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Facebook EFCC/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 16

Gomina Ademola Adeleke ti wọn ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC lọ siwaju ile ẹjọ giga apapọ tiluu Abuja, nibi to ti fẹsun iwa aṣemaṣe kan wọn.

Ninu iwe ẹsun naa ni Gomina Adele ti n beere fun biliọnu meji naira, gẹgẹbi owo gba-ma-binu, lori iwa ti ajọ naa hu.

Ajọ EFCC lo gbẹsẹ le apo aṣuwọn ikowosi ijọba ipinlẹ Osun l'Ọjọru, ọsẹ yii, nibi ti wọn ti sọ pe awọn ṣakiyesi ọpọ owo to n fo kaakiri lati inu apo ikowosi naa lọ apo aṣuwọn miran to jẹ ti awọn ileeṣẹ aladani.

Ijọba ipinlẹ rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun ajọ EFCC pe ko san biliọnu meji naira fun un bi owo itanran lori igbesẹ ti ko ba ofin mu, to gbe

Lara ẹsun naa ni pe ajọ EFCC ko ni ẹtọ tabi aṣẹ lati gbẹsẹ le apo ikowosi FSAA ijọba ipinlẹ Osun, eyi ti wọn ni nile ifowopamọ First Bank Nigeria Limited.

Adajọ agba ati alakoso eto iṣuna agba nipinlẹ Osun ni wọn jẹ olufẹsunkan kinni ati ikẹta ninu iwe ẹsun naa.

EFCC, alaga rẹ, ati ile ifowopamọ si First Bank ni ijọba ipinlẹ Osun fẹsun kan niwaju ile-ẹjọ, ninu ẹsu ti igbimọ agbẹjọro rẹ, eyi ti Amofin M. T. Adekilekun pe.

Wọn jẹ ko di mimọ pe bi ajọ EFCC ṣe gbẹsẹ le aṣuwọn ti nọmba rẹ jẹ 2017170947 ko ba ofin mu, bẹẹ si ni ko ba iwe ofin ilẹ Naijiria mu, to si tun le dabaru gbogbo eto ati ilana iṣẹ ijọba duro nipinlẹ naa.

Ijọba ipinlẹ naa rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fun ajọ EFCC lati san biliọnu meji naira fohun, gẹgẹ bi owo itanran lori igbesẹ ti ko ba ofin mu, to gbe.

Bakan naa lo tun ni ki wọn beere lọwọ ajọ naa, ati alaga rẹ, boya lotitọ ni wọn lẹtọ lati gbẹsẹ le apo aṣuwọn ijọba, lai tẹle ilana ofin, ni ibamu pẹlu abala akọkọ, ikẹfa, ikẹrindinlogoji, ikẹrinlelogoji, ati ikejilelọgọjọ ninu iwe ofin ilẹ Naijiria.

O ni ajọ EFCC ko lẹtọọ kankan lati gbẹsẹ le apo aṣuwọn rẹ, lai kọkọ gba aṣẹ lati ọdọ ile-ẹjọ, koda, to lo tun wa ninu iwe ofin to da ajọ ọhun silẹ.

Siwaju sii ni wọn rọ ile-ẹjọ lati ṣagbeyẹwo lẹta ti ajọ EFCC kọ ranṣẹ si ile ifowopamọ First Bank lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, lati gbẹsẹ le apo aṣuwọn ikowosi rẹ jẹ eyi ti wọn fi tẹ ofin loju mọlẹ.

Wọn tun jẹ ko di mimọ pe igbesẹ aṣilo agbara ati ipo, dida si ọrọ to nii ṣe pẹlu ojuṣe ohun, ati idunkooko mọ ṣiṣiṣẹ sin awọn araalu ni iwa aibofin mu EFCC hu.

Ẹ̀sun First Bank

Ijọba ipinlẹ Osun tun fẹsun kan ile ifowopamọ First Bank lati tẹwọ gba aṣẹ ajọ EFCC lai jẹ pe wọn ṣafihan iwe idanilọwọkọ ti wọn gba lati ile-ẹjọ.

Ijọba naa rọ ile-ẹjọ lati beere alaye lọwọ awọn alakoso ile ifowopamọ ọhun boya wọn ni ẹtọ lati gbẹsẹ le apo aṣuwọn ohun, nitori lẹta lasan ti wọn ri gba lati ọdọ awọn alakoso ajọ EFCC.

Awọn agbẹjọro ijọba ọhun sọ pe ile ifowopamọ naa ti tapa si ofin igbẹkẹle lori igbesẹ ti wọn gbe naa, nipa di da ajọ EFCC lohun lati gbẹsẹ le apo aṣuwọn ijọba Osun.

Àkọlé fídíò, Tí mo bá tún ayé wa, nkò lè ṣe àgùnbánirọ̀

Ṣé EFCC lágbára lábẹ́ òfin láti gbẹ́sẹ̀ lé àkáǹtì ijọba ìpínlẹ̀ ? Àlàyé rèé

Ni ibi gbogbo lagbaaye, ti ilana ati ofin ba ti wa, igbesẹ yowu ti ijọba tabi ẹka to n ri si ọrọ ilu yoo ba gbe gbọdọ wa ni ibamu pẹlu alakalẹ ofin.

Amọ latigba ti ajọ EFCC to n ri si ajẹbanu ni Naijiria ti gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun ni ọpọ eeyan ti n sọ pe igbesẹ naa ko tọna labẹ ofin.

Bo tilẹ jẹ pe EFCC fi awọn alaye kan gbe ipinnu naa lẹsẹ, Aarẹ Tinubu pada paṣẹ pe ki wọn gbẹsẹ kuro lori akanti naa kia, nitori ko yẹ ki wọn ṣe bẹẹ bi idibo Osun ṣe ku si dẹdẹ.

Ṣugbọn ki gan-an pato ni ofin ilẹ yii sọ nipa iwa ti EFCC hu fun ijọba Osun? Ṣe o tọna tabi bẹẹ kọ? Alaye ree.

Gomina Ademola Adeleke lapa osi, aworan akede ajọ EFCC lapa ọtun

Oríṣun àwòrán, Gov. Ademola Adeleke/FB/ EFCC/X

Ohun ti ofin sọ lẹka EFCC

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Fun EFCC, abala 38 (1) ofin wọn sọ pe :

"Ajọ yii le wadii ko si gba àbọ lati ọdọ ẹnikẹni, ajọ tabi ileeṣẹ lai si idiwọ kankan lati lo agbara rẹ."

Abala keji ofin naa sọ pe iwa ọdaran ni fun ẹnikẹni lati di EFCC lọwọ iṣẹ rẹ, tabi ki eeyan kọ lati fọwọsowọpọ pẹlu wọn bi wọn ba n ṣe iwadii to ba ofin mu.

Ijiya ti wọn lo wa fun ẹni to ba di wọn lọwọ ni ẹwọn ọdun marun-un tabi owo itanran ẹgbẹrun lọna ogun naira.

Ẹni naa si le sanwo ko si tun pada ṣẹwọn bi ofin ajọ naa ṣe sọ.

Amọ abala EFCC yii ko sọ nnkan kan nipa boya o lẹtọọ lati gbesẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ.

Ni Naijiria, awọn ijọba ipinlẹ ni idaji ẹtọ lati da duro, bẹẹ ni ẹtọ imuniti si wa fun awọn gomina labẹ ofin.

Bakan naa ni abala kẹrinlelogun ofin to de kiko ọrọ jọ lọna eru, ki eeyan si wa fi sọri ohun to ba ofin mu (Money laundering) ṣalaye pe:

"Ẹka to kaju ẹ labẹ ofin le beere fun tabi yẹ akọsilẹ ibi ti owo ti n jade wo, lati mọ boya wọn n tẹle ofin."

Amọ ẹka yii ko tun sọ boya EFCC lagbara lati gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ.

Iyatọ kan to wa nibẹ ni pe abala kẹfa ofin EFCC sọ pe ajọ naa le tọpinpin ibi ti magomago ba ti n waye, ki wọn gbẹsẹ le e tabi gba awọn ohun ti wọn fi magomago naa ko jọ.

Wọn fi abala 7(6) ofin to de kikiwojọ lọna èrú gbe ohun ti wọn ṣe fun ijọba Osun lẹsẹ.

Abala keje ofin wọn sọ pe banki le fi ẹjọ ẹka ti ọwọ rẹ ko ba mọ nipa owo sun EFCC, amọ a ko le fidi ẹ mulẹ boya banki lo fi ẹjọ ijọba Osun sun, ti EFCC fi fofin de akanti wọn tabi bẹẹ kọ.

'Àṣìlò agbara ni igbesẹ EFCC yii, o lodi labẹ ofin- Ààrẹ ẹgbẹ awọn lọya ni Naijiria (NBA)

Lati tan imọlẹ si ọrọ yii si i, Aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọrọ ni Naijiria; Nigeria Bar Association (NBA), Afam Osigwe, ṣalaye pe igbesẹ EFCC si ijọba Osun ko tọna rara.

O ni aṣilo agbara ni.

"Ko si ajọ ijọba kankan tabi ẹnikẹni to lẹtọọ tabi agbara lati paṣẹ pe ijọba ipinlẹ ko le gba owo ninu apo ikowosi rẹ.

"Akọkọ ni pe igbesẹ naa le di ọpọ nnkan lọwọ"

Osigwe to ṣalaye bẹẹ fun ẹka iroyin Punch tẹsiwaju pe:

"Bi EFCC ba mọ pe awọn eeyan n lo akanti kan fun ajẹbanu, wọn le gba aṣẹ ile ẹjọ, amọ wọn o le deede fofin de akanti."

"Iru aṣẹ bẹẹ lodi sofin, o si tako agbara EFCC funra rẹ, o le fa aṣilo agbara. Ko tiẹ yẹ ki iru rẹ waye rara."

Bẹẹ ni Aarẹ NBA naa ṣalaye.

Osigwe loun gba awọn banki nimọran lati ma ṣe tẹlẹ iru aṣẹ bẹẹ latọdọ EFCC, nitori o lodi sofin.

Ojú gbà mi tì fún EFCC tó fòfin de àkáǹtì ìjọba Osun, ẹ gbẹ́sẹ̀ kúrò níbẹ̀ kíá – Ààrẹ Tinubu pàṣẹ

Aare Bola Tinubu

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency

Bi awuyewuye ṣe gbode kan lati Ọjọru ti ajọ EFCC ti gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun ni ọpọ eeyan ti n sọ pe ko sọgbọn ki Aarẹ Bola Tinubu ma mọ nipa rẹ.

Amọ Aarẹ Tinubu ti ni ọwọ oun ko si ninu igbesẹ EFCC rara, oju si ti oun fun wọn pe wọn tiẹ ṣe ohun to jọ bẹẹ.

Atẹjade ti ileeṣẹ Aarẹ fi sita l'Ọjọbọ, ọjọ kẹfa oṣu Kẹjọ yii ni Tinubu ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ọhun, to si paṣẹ pe ki EFCC gbẹsẹ kuro lori akanti ijọba Osun lẹyẹ o sọka.

"Bi ibo ṣe ku si dẹdẹ l'Osun, ko yẹ ki EFCC fofin de asunwọn wọn"

Atẹjade naa ti Bayo Onanuga, Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin fi sita, ṣalaye pe ko tọna fun EFCC lati fi ofin de apo ikowosi ipinlẹ Osun bi ibo ṣe ku si dẹdẹ nibẹ.

" Ohun gbogbo ti awọn ẹka ijọba ba ṣe ni wọn maa n sọ pe mo mọ nipa e, koda bi mi o tiẹ gbọ nipa ẹ ṣaaju ri.

"Ọjọ diẹ lo ku fun ipinlẹ Osun lati dibo sipo gomina, fun idi eyi, ko si ohun to yẹ ko ṣẹlẹ ti yoo maa tọka si pe EFCC tabi ẹka ijọba kankan fẹ di idibo naa lọwọ ni.

"Gẹgẹ bo ṣe yẹ, mo ti paṣẹ pe ki EFCC tete gba kootu lọ lati mu ofin yoowu ti wọn ba fi de apo ikowosi ijọba Osun kuro."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade Aarẹ naa wi.

O ni bi wọn ṣe sare gba aṣẹ ti wọn fi de akanti naa ko tọna.

Aarẹ ni latigba toun ti de ipo loun ti maa n sọ pe kawón ileeṣẹ to n ri si ajẹbanu siṣẹ wọn lai si idasi kankan, tabi fifi ẹjọ ṣègbè.

O ni nitori rẹ loun ko ṣe ki n da si ọrọ EFCC tabi awọn ajọ to farapẹ ẹ.

Amọ ni ti Osun to ṣẹlẹ yii, Aarẹ ni ki EFCC tete gbẹsẹ kuro lori owo ijọba Osun. Aṣẹ ni.

EFCC bẹ̀rẹ̀ àlàyé bí Adeleke, ADC, ẹgbẹ́ amòfin àtàwọn aráàlú ṣe fọnmú lórí àpò àsùnwọ́n owó ìjọba Osun tí wọn fòfin dè

Alaga ajo EFCC, Ola Olukayode ree to ka owo mejeeji papo, o si n wo ọọkan - Enikeji re ni Gomina Ademola Adeleke to mu ẹrọ gbohungbohun dani, to si n sọrọ

Oríṣun àwòrán, Olukayode ati Adeleke/Screenshot

Àkọlé àwòrán, Ola olukayode ati Gomina Adeleke

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, EFCC ti ṣalaye lẹkunrẹrẹ nipa idi ti wọn fi gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun, labẹ iṣakoso Gomina Ademola Adeleke.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọjọru ana ni Gomina Adeleke pariwo sita pe ajọ EFCC ti gbẹsẹ le apo aṣuwọn ti wọn fi n san owo oṣu fun gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata.

Ṣugbọn ajọ naa, nigba ti wọn n fesi, jẹ ko di mimọ pe awọn ko gbe igbesẹ naa nipa oṣelu, bi ko ṣe pe iwadii ti awọn ti bẹrẹ lati bi oṣu mẹrin sẹyin lo fa a, to fi ri bẹẹ.

Lati inu oṣu Kẹta ọdun 2026 la ti bẹrẹ iwadii lórí bi ijọba ṣe n fi ọwọ jibiti mu owo to to biliọnu mọkanla naira - EFCC

Ninu atẹjade ti EFCC fi soju opo wọn lalẹ Ọjọru, wọn ni ohun to ṣe pataki fun awọn ni lati jẹ ki gbogbo aye mọ ohun to n ṣẹlẹ.

Wọn ni bi awọn ko ba tete gbe igbesẹ ọhun, o ṣee ṣe ki owo ipinlẹ Osun, to tun jẹ owo gbogbo araalu ba eto idibo gomina to m bọ lọ.

"O ṣe pataki fun ajọ EFCC lati sọ ọ sita gbangba lori idi pataki ti a fi gbe igbesẹ ti a fi gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun, lai wo ti ọrọ eto idibo gomina to n bọ nipinlẹ naa," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Lati inu oṣu Kẹta, ọdun 2026 la ti bẹrẹ iṣẹ iwadii to nii ṣe pẹlu ẹsun bi ijọba ṣe n fi ọwọ jibiti mu awọn owo bii Ecology Funds, owo iranlọwọ ati to wa ninu akọsilẹ igbimọ FAAC, leyi to to biliọnu mọkanla naira.

"Fun idi eyi, awọn alẹnulọrọ ijọba kan, paapaa alakoso eto iṣuna nipinlẹ naa, ti wa si ọdọ ajọ EFCC lati fọrọ wa a lẹnu wo." EFCC jẹ ko di mimọ.

"A ko ba ti fofin de apo ikowosi naa, ṣugbọn bi ọpọlọpọ owo ṣe n fo jade lati lati inu rẹ n fu wa lara"

Bakan naa ni ajọ EFCC tun sọ pe awọn ko ba ti ma gbe igbesẹ gbigbẹsẹ le apo ikowosi, ṣugbọn bi ọpọlọpọ owo ṣe n fo jade lati ọjọ keji, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 nii furasi.

"Ajọ yii kofiri owo gọbọi to n fo lati inu apo ikowosi naa lọ sinu awọn apo aṣuwọn awọn ileeṣẹ kan, ti a si ni lati tete da wọn lọwọ kọ nipa gbigbẹsẹ le apo ikowosi naa, lati ma jẹ ki owo miran tun jade sita," EFCC sọ fawọn ọmọ Naijiria.

Atẹjade ọhun tun tẹsiwaju pe, "Ojuṣe ajọ EFCC ni lati daabo bo owo araalu to wa ni ikawọ ijọba, to fi mọ dukia atawọn ohun amuṣọrọ ijọba. AJọ yii ko le kawọ gbera nipa bi wọn ṣe n ṣe owo ilu kumọkumọ.

"Nigba ti ajọ mọ nipa eto idibo gomina to m ọ nipinlẹ Osun, a ni ojuṣe lati tete daabo bo owo ipinlẹ naa. O maa jẹ ohun ti ko bojumu fun ajọ yii lati faaye gba oniruuru awawi lati faaye gba awọn iwa ti ko bofin mu, nitori ọrọ eto idibo to n bọ lọna."

"Kìí ṣe ìpínlẹ̀ Osun níkan là n ṣe ìwádìí àpò ìkówósí rẹ̀"

Siwaju sii ni ajọ EFCC jẹ ko di mimọ pe kii ṣe ipinlẹ Osun nikan ni awọn n tọpinpin apo ikowosi rẹ, bi ko ṣe pe gbogbo ipinlẹ to wa ni Naijiria ni.

Ajọ naa sọ pe to ba to asiko lati gbe igbesẹ lori apo aṣuwọn awọn ijọba ipinlẹ yooku, ko si nnkan ti yoo da wọn lọwọ kọ lati ṣe e.

"O ṣe pataki fun ipinlẹ naa lati mọ pe ajọ yii n wo gbogbo awọn eto iṣuna awọn ipinlẹ kaakiri bii ti ipinlẹ Osun," EFCC tu sọ bẹẹ.

"Ọpọ ninu awọn ipinlẹ wọnyi la n ṣe iwadii wọn lati mọ eyi to lẹbọ lẹru, ati awọn ti wọn wẹ-yan-kan-n-kan.

"Gbogbo igba ni ajọ yii maa n tọka si i pe awọn kii ṣe oloṣelu, bẹẹ ni ko si ojuṣaaju ninu iṣẹ awọn, bi ko ṣe pe awọn n ṣiṣẹ fun ọmọ Naijiria ni.

"A gbesẹ le apo ikowosi ipinlẹ Osun lati daabo bo jiji owo ijọba gbe. A rọ gbogbo araalu lati ma ṣe gba irọ ti wọn n pa gbọ, nitori pe ifẹ gbogbo ọmọ Naijiria lo leke, ati pe ajọ yii yoo daabo bo o."

EFCC pe ko ni ẹtọ kankan labẹ ofin lati fofin de akanti ijọba ipinlẹ kan lai gba asẹ ile ẹjọ - Ẹgbẹ awọn amofin

Ẹgbẹ awọn agbẹjọro nilẹ Naijiria, NBA ti wa dide lati tako igbesẹ ti ajọ EFCC gbe, nipa gbigbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun.

NBA sọ pe ajọ EFCC ko ni ẹtọ kankan labẹ ofin lati gbe iru igbesẹ ti wọn gbe naa, lai tẹle ilana ofin to tọ.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Afam Osigwe ninu ifọrọwerọ to ṣe l'Ọjọru, lo ti ṣalaye pe gbogbo igbesẹ lati gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ kan ni lati kapa ijọba, to si tun jẹ igbesẹ aṣilo agbara.

Osigwe jẹ ko di mimọ niṣe lo yẹ ki ajọ EFCC gba ile-ẹjọ lọ lati ṣalaye ohun to n ṣẹlẹ lati le gba aṣẹ, to si ni ajọ naa ko lẹtọọ kankan lati da ọwọ wu.

"Ko si ijọba kan, tabi ileeṣẹ ijọba, tabi ẹnikẹni lati gbẹsẹ le apo ikowosi ipinlẹ kankan. Akọkọ ni pe aṣẹ naa yoo da ijọba lọwọ kọ lati ṣiṣẹ. Bi EFCC ba mọ pe iwa ijẹkujẹ n ṣẹlẹ, ohun ti wọn ni lati ṣe ni pe ki wọn gba ile-ẹjọ lọ, ṣugbọn wọn ko le da ọwọ wu lati gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ kan," Osigwe sọ bẹẹ.

EFCC gbẹ́sẹ̀ lé àpò ìkówósí ìjọba Osun, Adeleke ní kóòtù yóò bá àwọn dà a

Alaga EFCC,Ola Olukoyede lapa osi, Gomina Ademola Adeleke lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, EFCC/Gov. Ademola Adeleke/FB

Bi idibo sipo gomina ipinlẹ Osun sẹ ku ọjọ mẹwaa lonii, iroyin to gbode ni pe ajọ EFCC to n ri si ajẹbanu ti gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe fidi ẹ mulẹ lẹyin ti Gomina Ademola Adeleke ba awọn akọroyin sọrọ l'Ọjọru nibi ipade oniroyin l'Osogbo, asunwọn ti wọn fi n san owo oṣu awọn oṣiṣẹ ni EFCC gbe ote le.

Wọn ko le gba owo jade nibẹ, wọn ko le lo kaadi ATM, bẹẹ ni wọn ko le fi ọna kankan gba owo jade lati ibẹ.

Igbesẹ n waye lẹyin wakati diẹ ti gomina Ademola Adeleke kede pe EFCC n pete ati fi ofin de akanti ijọba Osun ati tawọn lọgalọga nipinlẹ naa.

Ile ẹjọ giga Osogbo yoo ba wa da a- Gomina Adeleke

Ninu ọrọ rẹ nibi ipade oniroyin naa, Gomina Ademola Adeleke sọ pe owurọ oni Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Keje 2026 ni oun gba iwe kan lati ọdọ ajọ EFCC, eyi to ka pe wọn ti fofin de apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun.

Gẹgẹ bi Gomina Adeleke ṣe wi:

" Gbogbo yin lẹ mọ bi rogbodiyan ṣe n waye nipinlẹ Osun lati bii oṣu meloo sẹyin, ti wọn n pa awọn eeyan ipinlẹ Osun, ti wọn n yinbọn niluu, ti wọn n ko awọn ọmọ ẹgbẹ Accord lai mu ẹgbẹ alatako kankan.

"Ẹ mọ bi wọn ṣe da oju ijọba ibilẹ bolẹ pẹlu.

"Won ti pa ọpọ ọmọ egbẹ Accord, wọn ti awọn mi-in mole l'Abuja lai si iwe aṣẹ imuni kankan.

"Gbogbo ikọlu yii n waye pẹlu aṣẹ Gboyega Oyetola, lori ibo ti oludije re ko le bori.

"Aarọ oni ni a tun gba lẹta ti EFCC fi gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ Osun, amọ a o ni i gba iru ẹ laye.

"Won ko fi to kootu leti ti won fi fi leta ohun ranse, a o ni i dake ki won se ohun ti ofin ko faaye gba fun wa."

Gomina Adeleke sọ pe idunkooko mọ ijọba demokresi ni iru iwa yii, boun ba si gba ko lọ bẹẹ, iwọnba to ṣẹku ninu demokresi naa ni wọn yoo tun tẹ loju mọlẹ.

"Emi o beere nnkan mi-in, ju ki Alaga EFCC ṣalaye fawọn eeyan ipinlẹ Osun ati gbogbo ọmọ Naijiria lapapọ, idi ti wọn fi gbẹsẹ le asunwọn ijọba, ko si fi idi eri re han kawọn eeyan ri i.

"Yatọ si eyi, mo ti paṣẹ fun Olootu idajọ nipinlẹ Osun lati gbe ọrọ naa lọ sile ẹjọ giga ilu Osogbo, kootu yoo ni lati ba wa da a."

Asunwọn ti wón ti n sanwo awọn tiṣa, oṣiṣẹfẹyinti, ilera atawọn mi-in ni EFCC gbẹsẹ le, Adeleke ko si nawo ijọba polongo ibo- Olootu idajọ Osun

Amofin Jimi Bada, Olootu eto idajọ nipinlẹ Osun, ṣalaye ni tiẹ pe igbesẹ to lodi labẹ ofin ni EFCC gbe.

O ni wọn ko lẹtọọ labẹ ofin lati gbẹsẹ le apo ikowosi ijọba ipinlẹ rara.

" Apo ikowosi tijọba fi n sanwo oṣu oṣiṣẹ bii tiṣa, ijoba ibilẹ, tawọn oṣiṣẹfẹyinti, ti ilera, eto ẹkọ atawọn mi-in ni wọn gbẹsẹ le.

Eyi ko yẹ ko ri bẹẹ, nitori owo to wa fun iṣejọba ati fun araalu ni wọn gbẹsẹ le yẹn.

"Gomina Adeleke ko lo owo ijọba polongo ibo, o tun fi owo rẹ sanwo ijọba ibilẹ ni.

"Abala 24 ati 38 ofin to de owo nina ko fi aaye gba igbesẹ yii, eyi ni Gomina ṣe paṣẹ fun mi lati gbe ọrọ naa lọ si kootu."

Olootu idajọ Osun naa sọ pe ki I ṣe ọrọ ija, bẹẹ ni ijọba Osun bọwọ fun ẹka ijọba bi EFCC.

O ni ṣugbọn ile ẹjọ ni awọn yoo pada si, ki kootu ṣalaye idi ti EFCC yoo fi gbẹsẹ le asunwon ijọba.

Jimi Bada fi kun un pe ki araalu fi ọkan balẹ, ki won reti abọ kootu lai ṣiyemeji.

O ni ifẹ ti wọn ni si Adeleke yoo gbe e de ipo naa bo ti wu ki atako pọ to.