Wo ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ agbésùnmọ̀mí tí iléeṣẹ́ ológun ń wá, bí wọn ṣe burú sí àti ìdí tó ṣe gbé ẹ̀bùn N60m kalẹ̀ fún ṣíṣe àwárí wọn

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Ileeṣẹ ologun Naijiria ti kede pe oun yoo fi obitibiti owo ta ẹnikẹni to ba le sọ ibi ti awọn adari ẹgbẹ ISWAP kan ti wọn ti di ogboloogboo sinu igbesunmọmi wa lọrẹ.
Awọn wọnyi ni ileeṣẹ ologun Naijiria n wa ju lọ ti wọn si ti n dọdẹ wọn tipẹ amọ ti ọwọ ko ti i ba wọn.
O kere tan, ẹni to ba le pese awọn ọna ti wọn yoo fi ri awọn agbesunmọmi ISWAP naa mu yoo gba to ọgọta miliọnu naira (60m) bi ileeṣẹ ologun ṣe sọ.
Awọn wo gan-an ni olori ogun ISWAP naa?
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun HADIN KAI ṣe wi, awọn olori ogun ISWAP ti wọn n wa yii lo n ṣọṣẹ lagbegbe Borno.
Wọn kede eyi lẹyin ti wọn koju awọn ikọ ISWAP ati ISIS kan lagbegbe Lake Chad ati nipinlẹ Borno.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ ologun Naijiria ṣe darukọ wọn, awọn olori agbesunmọmi ISWAP ti wọn n wa naa ni:
"Abu Musa Al-Mangawi Baa Shuwa – Wali (Oun ni wọn pe ni Gomina ISIS lẹkun Iwọ-Oorun Africa.
"Igbakeji rẹ ni wọn pe ni Amirul Jaish Muhammad Jidda ("Apa rẹ kan ti ge") ati Hamad Abu Hanifa ti wọn pe ni Amirul-Fiya awọn ISWAP.
Miliọnu mẹwaa naira ni ileeṣẹ ologun loun yoo fun ẹni to ba le ṣọ ibi ti wọn yoo ti ri Muhammad Jidda mu. Oun ni Olori ISWAP ni abala Jaish.
Aadọta miliọnu naira (50 million) ni wọn gbe le ori Ibn Muhammad ti wọn pe ni olori ẹgbẹ naa ni ẹkun Amniya.
Bakan naa ni awọn ọmọ ẹgbẹ agbesunmọmi yii miran naa tun wa ti wọn jẹ onipo giga ti awọn ologun n wa.
Lati mu iṣẹ naa ya, ileeṣẹ ologun fi aworan awọn ti wọn yii lede pẹlu alaye to yẹ nipa wọn.
"Gbogbo ohun ti a ba gbọ nipa wọn, aṣiri ni yoo jẹ. Bẹẹ si ni aabo to daju yoo wa fawọn to ba ta wa lolobo nipa wọn, gẹgẹ bo ṣe yẹ ko ri labẹ ofin. "
Bẹẹ ni atẹjade awọn ologun naa wi.
"Ẹ ma ṣe gbiyanju pe ẹ fẹ mu wọn funra yin o"
Lara imọran ti ẹka ologun "Operation HADIN KAI" gba awon omo Naijiria nipa iṣẹ yìí ni pé kí wọn má ṣe gbìyànjú láti mú àwọn agbesunmọmi náà fúnra wọn.
Won ni kí aráàlú ma ṣe ko wọn loju tabi gbìyànjú lati mú àwọn agbesunmọmi nàa silẹ títí tí àwọn ológun yóò fi dé.
Eyi lewu púpò gege bí iileese ológun ṣe sọ, nitori awọn agbesunmọmi naa ni awọn nnkan ija buruku lọwọ.
"A ń kilọ gidigidi fun aráàlú láti má ṣe gbiyanju mímú àwọn afurasi agbesunmomi náà fúnra wọn.
"A ro yín kí ẹ má ṣe koju won fún ìdí kankan."
Ìlérí owó ńlá tileese ológun ṣe lórí àwọn agbesunmomi yìí ń fi hàn bo se wù wọn tó láti yanjú àwọn Boko Haram àti ISWAP lagbegbe Lake Chad ati ilẹ yii.
Ninu awọn idojukọ agbesunmọmi to waye laipẹ yii , ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti pa awọn olori agbesunmọmi kan, wọn si mu awọn kan ṣikun si ahamọ, bẹẹ ni wọn ṣi n tẹsiwaju ninu igbiyanju wọn.



























