Igbó ọba Niger làwọn ológun, ọlọ́pàá àti ọdẹ ti dóòlà àwọn èèyàn Woro, ní Kwara, tí ajínigbé gbé lóṣù mẹ́fà sẹ́yìn, wọ́n ti dé sí Ilorin - Ọlọ́pàá Kwara

Awọn eeyan ilu Woro nipinlẹ Kwara ti wọn gba idande lọwọ ajinigbe
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Awọn eeyan ilu Wọrọ ni ijọba ibilẹ Kaiama ati awọn eeyan Yashikira ni ijọba ibilẹ Baruten ipinlẹ Kwara, ti awọn agbesunmọmi ji gbe ti de si ilu Ilọrin, Olu ilu ipinlẹ Kwara.

Awọn eeyan naa la gbọ pe wọn ti wa ni ile Emir Yashikira to wa ni ilu Ilọrin.

Ọmọ ilu naa kan to ba Akọroyin BBC News Yorùbá sọrọ nipa iṣẹlẹ naa laarọ Ẹti ọjọ keje oṣu yii fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.

Ọgbẹni Gunu Lafia sọ pe nnkan bi aago mẹjọ alẹ ana ni wọn gunlẹ sí ilu Ilọrin.

Lasiko toun naa n sọrọ, ẹnikan to ni ki a fi orukọ bo oun lasiri sọ pe, wọn yóò ko wọn lọ ile ijọba laago mẹta ọsan oni.

Bolanle Osikolu, Komisana feto iroyin nipinlẹ Kwara wọ asọ kaba olomi aro, o si we gele dudu

"Awọn agbesunmọmi n dunkoko lati fẹ awọn iyawo Emir ti wọn ji gbe, ti wọn yóò si fi awọn obinrin to ku lọkọ ni tipatipa"

Bẹẹ ba gbagbe, lọjọ kẹta osu keji ọdun yii lawọn agbesunmọmi yawọ ilu Wọrọ ni ijọba ibilẹ Kaiama ipinlẹ Kwara nibi ti wọn ti sekupa ọpọlọpọ eeyan, ti wọn si tun ji awọn eeyan mẹtalelọgọjọ gbe.

Ninu awọn ti wọn ji gbe lati ri iyawo Emir ilu naa ati awọn ogowẹrẹ pẹlu awọn obinrin.

Lati gba naa ni wọn ti wa ni ahamọ awọn agbesunmọmi, tawọn agbesunmọmi naa si n dunkoko lati fẹ awọn iyawo Emir ti wọn ji gbe, ti wọn yóò si fi awọn obinrin to ku lọkọ ni tipatipa.

Ṣugbọn lọjọru ọjọ karun osu yii ni awọn agbesunmọmi naa yọnda gbogbo awọn ti wọn ji gbe naa.

Awọn eeyan ilu Woro nipinlẹ Kwara ti wọn gba idande lọwọ ajinigbe

Igbo-ọba National Park, ni Kanji, ipinlẹ Niger, ni wọn ti doola awọn eeyan Kaiama ti ajinigbe gbe - Ijọba ipinlẹ Kwara

Lasiko to n ba BBC Yorùbá sọrọ lana, Kọmisọna feto Ibaraẹnisọrọ ni ipinlẹ Kwara Arabinrin Bọlanle Olukoju sọ pe, lootọ ni wọn ti yọnda gbogbo awọn ti wọn ji gbe.

O salaye pe igbo-ọba National Park ni Kanji ipinlẹ Niger ni wọn ti doola wọn.

O tẹsiwaju pe gbogbo wọn n gba itọju lọwọ ni ile iwosan kan to jẹ ti ijọba apapọ.

Kin ni awọn ọlọpaa sọ lori ẹ?

Kọmisọna ileesẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Kwara Adekimi Ojo, toun naa ba akọroyin wa sọrọ, fidi rẹ mulẹ pe, wọn ti doola ẹmi gbogbo awọn ti wọn ji gbe.

O ni iru iṣẹlẹ bẹẹ ko ni sẹlẹ ni ipinlẹ Kwara mọ, nitori lati igba ti iṣẹlẹ naa ti sẹlẹ lawọn ti yawọ Igbo lati koju awọn agbesunmọmi.

O fikun pe, ikọ eleto abo apapọ ilẹ wa to sakojọpọ awọn ọmọ Ogun, Ọlọpaa, Ọdẹ, ọmọ ogun ofurufu lati ọfisi Oludamọran agba lori eto aabo apapọ ,lo jumọ se isẹ naa.

Ikọ agbesunmọmi pẹlu ibọn, wọn duro togun-togun, bo oju wọn pẹlu asia dudu onikeu .Ọkọ̀ wọn wa nibẹ, awọn igi kan naa wa ni aṣalẹ ti wọn duro si ọhun.

Oríṣun àwòrán, Others

Lẹ́yìn oṣù mẹ́fà nígbèkùn, àwọn tí agbésùnmọ̀mí gbé lọ nílùú Woro àti Nuku ní Kwara gba ìtúsílẹ̀

Saaju la ti mu iroyin wa fun yin pe jọba ipinlẹ Kwara ti kede pe awọn eeyan tawọn ajinigbe ji gbe lọ niluu Woro ati Nuku nipinlẹ Kwara ti gba itusilẹ bayii.

Itusilẹ naa lo n waye lẹyin oṣu mẹfa tawọn eeyan naa ti wa nigbekun ajinigbe.

Loju opo Facebook to jẹ ti ijọba ipinlẹ Kwara ni wọn ti kede itusilẹ ọhun l'Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Kẹjọ ọdun 2026.

Ijọba ibilẹ Kaiama ni ilu Woro ati Nuku wa ni Kwara.

Iroyin sọ pe awọn eeyan naa to mẹ́rìndínlọ́gọ́sàn-án (176) niye nigba ti wọn ko wọn lọ.

"A dupẹ fun Oluwa, a si ki Aarẹ Tinubu, awọn ẹṣọ alaabo"

Ninu atẹjade ti ijọba Kwara fi kede ominira awọn eeyan naa ni won ti ni:

" Alihamdulillaah, a si dupẹ fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu, awọn ẹṣọ alaabo ati gbogbo eeyan pata to kopa ninu aṣeyọri nla yii. A dupẹ !"

Ki lo ṣẹlẹ ṣaaju?

Tẹ o ba gbagbe, ọkan lara awọn ikọlu to milẹ titi lọdun yii ni eyi to waye lọjọ kẹta oṣu Keji ọdun 2026, niluu Woro ati Nuku, ipinlẹ Kwara.

Ikọlu naa ni eyi ti awọn afurasi Boko Haram ti kọ lẹta sawọn araalu, pe awọn fẹ wa ṣe waasi nibẹ, ti awọn araalu naa si ni awọn ko fẹ waasi wọn.

Ipadabọ rẹ ni bawọn agbesunmọmi to le lọgọrun-un ṣe yabo awọn ilu meji naa pẹlu ọpọlọpọ ọkada, ti wọn ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si ko ọpọ eeyan wọgbo lọ.

Ko din ni eeyan igba (200) ti wọn pa, ọpọ farapa pẹlu, bẹẹ ni ọpọ eeyan di alarinkiri ti ko ni ẹbi tabi ẹnikẹni mọ, wọn ko si rile wọ mọ pẹlu.

Awọn ikọ fijilante to fẹ koju awọn agbesunmomi naa, wọn gba agbara lọwọ wọn nipa didana sun wọn mọ ibudo wọn.

Fun ọpọlọpọ oṣu lẹyin ikọlu naa, awọn ilu naa ko kun mọ pẹlu bi wọn ṣe di ahoro nitori ibẹru agbesunmọmi.

Lasiko ti a pari iroyin yii, ijọba ipinlẹ Kwara ko ti I sọrọ lori ọna tawọn to gba itusilẹ naa gba ri ominira.