Atiku bínú sí Tinubu tó rán aṣojú ló sípàdé UNGA fún ìgbà kẹ́ta, ó ní ṣe ẹ̀rù ń ba Ààrẹ láti wọ America ni

Oríṣun àwòrán, Atiku Abubakar/Facebook
Atiku Abubakar, Igbakeji aarẹ Naijiria nigba kan, ti koro oju si bi Aarẹ Bola Tinubu ṣe ran aṣoju lọ sipade awọn olori agbaye ti a mọ si UNGA 81, eyi ti yoo waye ni New York, lorilẹede America.
Ọla ode yii ti i ṣe ọjọ kejilelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni ipade naa yoo bẹrẹ pẹrẹwu, Igbakeji aarẹ Naijiria, Kashim Shettima ni yoo si ṣoju fun Aarẹ.
Ni 2023 ti Aarẹ Tinubu gori aleefa lo yọju sipade naa funra rẹ, amọ ni 2024, 2025 ati ti ọdun 2026 yii, igbakeji rẹ lo ran lọ.
Ẹhonu Atiku
Ninu atẹjade ti Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Atiku Abubakar, Phrank Shaibu,fi sita lo ti beere pe ki lo de ti Tinubu n pa ọkan lara awọn agbejọpọ nla agbaye naa jẹ.
"O sọ fun wa pe ẹgbẹ Aarẹ Trump ni wa a jokoo si — ki lo n ba ọ lẹru ninu America?"
Bẹẹ ni Atiku beere ninu atẹjade rẹ naa.
Igbakeji aarẹ Naijriia tẹlẹ naa sọ pe ipade UNGA yii ṣe pataki pupọ.
O ni o n fun orilẹede ni anfaani lati ba awọn olori aye pade, sọrọ okoowo ati idagbasoke ilu ẹni.
Atiku mẹnuba awọn asọti ọrọ Tinubu l'America, to ni I ṣe pẹlu igbẹjọ, o ni boya nitori rẹ ni Aarẹ ṣe n sa fun America lẹmọlemọ.
Amọ ileeṣẹ Aarẹ ti sọ pe ko sohun to jọ pe Tinubu n sa fun America.
Wọn ni Aarẹ ti lọ si America tẹlẹ, ọrọ abẹnu Naijiria si jẹ ẹ logun, titi kan ọrọ aje ati aabo ilẹ wa bo ti wa ni Europe lọwọlọwọ.
UNGA 81: Mọ̀ nípa ìpàdé àwọn olórí àgbáyé ní New York, àti ìdí tí Ààrẹ Tinubu fi ní kí Shettima lọ

Oríṣun àwòrán, Vice President Kashim Shettima/Facebook
Bẹrẹ lati ọjọ kejilelogun oṣu Kẹsan-an ọdun 2026 yii, titi di ọjọ kejidinlọgbọn oṣu yii kan naa, ipade apapọ awọn olori agbaye yoo maa waye ni New York, lorilẹede America.
Ipade naa ti i ṣe "United Nations General Assembly'' (UNGA) jẹ ẹlẹẹkọkanlelọgọrin (81) iru rẹ.
Akori ipade apapọ UNGA ti ọdun yii ni wọn pe ni "Restoring trust, managing transformation: A United Nations that delivers for all".
Gẹgẹ bo ṣe yẹ, orilẹede Naijiria naa n kopa ninu ipade naa, Aarẹ Tinubu si yẹ ko wa nibẹ pẹlu, amọ Aarẹ fa iṣẹ naa le Igbakeji rẹ; Kashim Shettima lọwọ.
Shettima lewaju ikọ awọn gomina, minisita atawọn mi-in lọ si UNGA 81
Lati fidi ẹ mulẹ pe Aarẹ Bola Tinubu ko ni i le yọju sibi ipade naa fun ti ọdun yii, ileeṣẹ Aarẹ fi atẹjade kan sita lọjọ Aiku to kede pe Igbakeji rẹ, Kashim Shettima ni yoo ko ikọ Naijiria sodi lọ si New York.
Atẹjade ti Stanley Nkwocha; Amugbalẹgbẹẹ pataki fun Aarẹ lori eto iroyin fi sita, ṣalaye pe Aarẹ ti gbe iṣẹ naa le Igbakeji rẹ lọwọ.
Lara awọn ikọ ti wọn ni Shettima yoo lewaju fun ni Gomina Siminalayi Fubara lati ipinlẹ Rivers; Gomina Dauda Lawal ti ipinlẹ Zamfara; awọn minisita atawọn lọga-lọga lẹnu iṣẹ ọba.
Ki ni Shettima yoo ṣe gẹgẹ bii aṣoju Naijiria ni UNGA 81?
Nibi ipade yii, Igbakeji Aarẹ Naijiria; Kashim Shettima yoo ka ọrọ apapọ Naijiria, ninu rẹ ni yoo ti sọ ipo ti orilẹede yii wa ati ohun to mu lọkunkundun lori awon ọrọ to n ṣẹlẹ lagbaaye.
Yoo sọrọ nipa aabo, idagbasoke ọrọ aje ati ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ilẹ okeere, gẹgẹ bi atẹjade ijọba wa ṣe sọ.
Bakan naa ni Igbakeji aarẹ Naijiria yoo tun kopa ninu ipade awọn onipo giga, nibi ti wọn yoo ti sọrọ lorii ẹtọ idagbasoke, ayipada oju ọjọ atawọn iṣẹlẹ mi-in to ṣe pataki si Naijiria ati ilẹ Adulawọ.
Eyi ni igba kẹta ti Aarẹ Bola Tinubu ko yọju sibi ipade apapọ UNGA latigba to ti depo aarẹ ni 2023.
Bo tilẹ jẹ pe Aarẹ Tinubu ko si ni Naijiria lasiko yii, ṣaaju ni ahesọ ti n jade pe yoo gba ilẹ Europe to wa lọ si New York, nibi ipade naa.
Koda, awọn kan sọ pe eto ti wa nilẹ fun un lati jokoo lẹgbẹ Aarẹ Donald Trump ilẹ America.
Amọ eyi ko pada ri bẹẹ, pẹlu bi ileeṣẹ Aarẹ ṣe kede pe Igbakeji rẹ ni yoo ko awọn ikọ Naijiria lọ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, awon idi ti aarẹ ko fi lọ mọ ni ai si nile rẹ ati ko le mojuto awọn ọrọ abẹle miran nibi to lọ.


























