Ààfin Olubadan fọhùn síta lórí bí orí oyè Lekan Alabi, Abese Olubadan, ṣe sùn ìta

Olubadan Rashidi Ladoja lapa osi, Oloogbe Oloye Lekan Alabi lapa ọtun. Olubadan de fila pupa, o wọṣọ alawọ aro, o di de fila pupa o si lo ilekẹ sọrun rẹ,o n rẹrin-in musẹ. Oloogbe Lekan Alabi ni tiẹ n sọrọ si ẹrọ gbohungbohun, o de fila alawọ ewe si agbada funfun to ni awọn kan naa. O lo igo soju.

Oríṣun àwòrán, Olubadan's Palace/ Oloye Lekan Alabi/Facebook

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ọjọ Abamẹta to kọja yii ni gbajugbaja akọroyin to tun jẹ oloye agba nilẹ Ibadan, Oloogbe Oloye Lekan Alabi jade laye, ti wọn si sin oku rẹ lọjọ keji si itẹ igbalode kan to wa nilu Fiditi.

Amọ titi di asiko yii ni ọpọ eeyan ṣi n sọrọ lorii bi Abese Olubadan ko ṣe jẹ sinsin siluu Ibadan, to jẹ ilu Fiditi nipinlẹ Oyo kan naa ni wọn gbe e lọ lati sin.

Wọn woye pe ori oye kii sun ita ni wọn n wi, ki wa lo de ti ọba lọla se gbe ori ade ati ori oye sun sita?

Bo tilẹ jẹ pe awọn ọmọ oloogbe naa ti ṣe awọn alaye kan siwaju lori igbesẹ ti wọn gbe yii, awuyewuye ko tan lori ayelujara pẹlu bi wọn ṣe n sọ pe ori ade ti sun sita.

Eyi lo mu BBC News Yoruba kan si Aafin Olubadan Ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja, lati mọ iha ti wọn kọ si ọrọ yii, ati pe ṣe ori ade ti sunta loootọ niyẹn?

"Ìfẹ́ ọkàn Oloogbe ni pe ki wọn maṣe sin oku rẹ sinu ile"

Akọwe iroyin fun Olubadan Ladoja, Ọmọọba Adeola Oloko ṣalaye fun BBC News Yoruba lori ọrọ yii lọjọ Aje, ati iha ti aafin Olubadan kọ si isẹlẹ naa.

Adeola Oloko ni "Aafin Olubadan ko lodi si bi wọn ṣe sin oku Oloye Lekan Alabi si ilu Fiditi, ko si lodi sofin tabi aṣa ilẹ Ibadan pe wọn ko sin wọn siluu Ibadan.

"Lakọkọ na, ifẹ ọkan Oloogbe Oloye Lekan Alabi ni pe ki wọn mase sin wọn sinu ile wọn.

Koda, a le sọ pe o nifẹ sibi ti wọn sin wọn si yẹn.

"Wọn ti sọ fawọn ọmọ wọn tẹlẹ pe ki wọn to ku pe ki wọn mase sin awọn sile bawọn ba ku.

"Emi paapaa ti de itẹ oku ti wọn sin wọn si yẹn ri, ibẹ dara pupọ, itẹ́ igbalode ni.

"Ki i ṣe Oloye Lekan Alabi nikan ni eeyan nla ti won yoo sin sibẹ, awọn ẹlomi-in niluu Ibadan naa wa nibẹ ti wọn jẹ gbajumọ, ti wọn sin si itẹ oku naa.

"Itẹ oku aladaani si tun ni, ki i ṣe iru wa o giri wa. Aaye to wuyi ni."

"Fiditi ki i ṣe ajeji Ibadan, ipinlẹ Oyo kan naa ni wa"

Koko keji ti Ọmọọba Oloko fi gbe ọrọ naa lẹsẹ ni pe ilu Fiditi ti wọn sin agba oye naa si ki i ṣe ajeji si Ibadan, ipinle Oyo naa ṣi ni.

O ni ajọṣepọ to danmọọran wa laaarin ilu Ibadan ati Fiditi, to fa a tawon to ba fẹ ki wọn sin awọn si itẹ oku to wa nibẹ lati Ibadan, le sun ibẹ titi ayeraye.

"Oloogbe Lekan Alabi ki i ṣe ọba, agba oye ni ko to ku, ori oye le sun ita to ba fẹ́, amọ ori ade nikan ni ki i sun sita"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Lara ọrọ tawọn eeyan n sọ nipa isẹlẹ naa ni pe ori ade oloye Lekan Alabi ti sun sita bayii amọ Akọwe iroyin Olubadan sọ pe eyi ko ri bẹẹ.

O ni Agba oye ilẹ Ibadan ni Oloogbe Lekan Alabi, ki i ṣe ọba.

"Ṣe ẹ mọ pe ipo Abese Olubadan ni Oloogbe naa wa ti ọlọjọ fi de, to ba jẹ pe wọn de bii ipo Ẹkaarun Olubadan ni, wọn ko ba gba ade.

Eyi si tumọ si pe wọn ko ni i sin wọn sibomi-in ju ilẹ Ibadan lọ.

Idi ni pe wọn ti n sunmọ ipo ti ọba le fi kan wọn nigba yẹn ni yẹn.

Amọ ipo Abese Olubadan ti wọn wa, ṣi fun wọn ni anfaani gẹgẹ bii oloye lati sun sibomi-in yatọ si ilẹ Ibadan."

Oloko sọ pe oloye to ba wu ko sun sita le sunta, eyi to ba wu ko sun s'Ibadan le sun Ibadan.

O ni sugbọn ko si Olubadan to ku ti wọn sin sita ri, ilu Ibadan ni gbogbo Olubadan n sun si.

" Ko ṣẹlẹ ri, ki wọn si Olubadan sibomi-in ju ilẹ Ibadan lọ, Ibadan ni wọn n sinku gbogbo wọn si, awọn ori ade ti ko gbọdọ suntan niyẹn.

"Amọ ti a ba ri Oloye to wu pe ki wọn sin oun silẹ ibomi-in, ko sohun to buru nibẹ rara.

"Ko lodi, ko si tumọ si pe ọmọ ilẹ ibi ti wọn sin in si yẹn ni ẹni naa jẹ, ohun ti wọn fẹ niyẹn ni."

Bẹẹ ni Akọwe iroyin Olubadan ṣalaye lati fopin si awuyewuye to n lọ lori ọrọ naa, ko si tun maa jẹ idahun si ibeere awọn to fẹ mọ idi ti wọn fi sin agba oye Ibadan, Lekan Alabi, siluu Fiditi.

Ìdí tí a kò fi sin Olóye Lekan Alabi, Abese Olubadan sílùú Ibadan-Tunji Alabi, ọmọ Olóògbé

Oloogbe Oloye Lekan Alabi lapa osi, awọn to n ṣeto ilẹ gbigbẹ nibi isinku rẹ pẹlu awọn ẹbi lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Oloye Lekan Alabi/ Facebook/ BBC

Nigba ti ikede iku Oloye Oloogbe Lekan Alabi, Abese Olubadan jade lọjọ Abamẹta, ti wọn si kede pe wọn yoo sinku lọjọ Aiku, ko sẹni to ro o pe ilẹ Ibadan kọ ni Baba naa yoo sun.

Ṣaaju lọjọ Aiku naa ni wọn ti kirun si oku lara nile rẹ to wa ni Akobo, niluu Ibadan.

Imam agba ilu Ibadan, Alhaji Agbọtọmọkekere lo ṣe waasi to si sọrọ lori bi Oloye Lekan Alabi ṣe lo igbe-aye rẹ.

Amọ nigba ti akoko to lati sinku, itẹ oku aladani kan niluu Fiditi, nipinlẹ Oyo ni awọn ẹbi Oloogbe gbe baba naa lọ ti wọn si sinku naa sibẹ.

Eyi mu ọpọ eeyan maa beere pe ki lo le ṣẹlẹ ti agba oye ilẹ Ibadan yoo lọ sun oorun ayeraye rẹ niluu Fiditi, dipo ilẹ Ibadan ti wọn ti bi i.

BBC News Yoruba wa nibi isinku naa, ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe to ba wa sọrọ lori eyi, Tunji Alabi si ṣalaye pe:

"A fẹ ibi ti abojuto yoo ti wa fun wọn, a fẹ aabo,ati pe baba funra rẹ ko fẹran ibi idọti lati sun"

Ninu alaye Tunji Alabi to jẹ abigbẹyin Oloogbe Lekan Alabi lo ti sọ pe awọn fẹ ibi ti abojuto to peye yoo ti wa fun baba.

O fi kun un pe Oloye Lekan Alabi ko fẹran idọti rara nigba aye rẹ, eyi si tun jẹ idi kan tawọn fi gbe e wa si aaye naa ni Fiditi.

Bakan naa lo ni awọn fẹ ki aabo to peye wa fun oku baba.

Tunji tun sọ pe awọn itẹkuu ilu Ibadan ti kun, bẹẹ ni igbo ti pọju nibẹ.

O ṣalaye pe ẹnikan to fẹran aṣa ni Oloogbe Lekan Alabi, ko si fẹ irẹjẹ.

Iyawo oloogbe naa sọrọ pẹlu, o ni alabaaro toun maa n fi ọrọ lọ lo ti jade laye yẹn.

Lara awọn eeyan to wa nibi eto isinku naa ni:

Sẹnetọ Sarafadeen Ali, Kọmisanna fun iroyin nipinlẹ Ọyọ; Ọmọọba Dọtun Oyelade, Kọmiṣanna to n ri ṣi eto Aṣa ati Igbafẹ nipinlẹ Ọyọ; Ọmọwe Wasiu Olatunbosun ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Wo àwọn nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Olóyè Lekan Alabi, Abese Olubadan ilẹ̀ Ibadan tó jáde láyé

Oloogbe Oloye Lekan Alabi

Oríṣun àwòrán, Oloye Lekan Alabi/ Facebook.

Agba oye ilẹ Ibadan to tun jẹ agba ninu iṣẹ iroyin, Oloye Lekan Alabi, ti jade laye.

Gẹgẹ bi atẹjade ti Akọwe iroyin fun Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja, iyẹn Adeola Oloko fi sita, owurọ ọjọ Abamẹta, ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni Oloye Alabi papoda.

Oloogbe Alabi ni Abese Olubadan nigba aye rẹ.

Ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) ni nigba to jade laye.

Gẹgẹ bi ohun ti a gbọ, ọla ọjọ Aiku ni wọn yoo sinku Oloogbe Lekan Alabi nilana ẹsin Islam.

Ta a ni Oloogbe Oloye Lekan Alabi?

Oloogbe Oloye Lekan Alabi

Oríṣun àwòrán, Oloye Lekan Alabi/Facebook

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 1950 ni wọn bi Oloogbe Oloye Lekan Alabi, ọmọ ilu Ibadan nipinlẹ Oyo ni.

O lọ sile ẹkọ 7th-Day Adventist Primary School, Oke-Foko, Ibadan ati African Church Grammar School, Apata Ganga, Ibadan.

Oloogbe ṣiṣẹ tiṣa nile ẹkọ alakọọbẹrẹ St John's Anglican Primary School, Ibadan.

Ni 1973, wọn gba a sileeṣe iwe iroyin Sketch gẹgẹ bii akọroyin.

O lọ sile ẹkọ College of Journalism, 'Fleet Street', London to gbajumọ pupọ ni 1976, o si yege nibẹ ni 1978.

Lekan Alabi fiṣẹ silẹ ni Sketch, o dara pọ mọ ileeṣẹ tẹlifiṣan apapọ NTA, Ibadan.

Ọdun1983 lo ṣiṣẹ bii Akọwe iroyin fun Oloogbe Bola Ige to jẹ gomina Oyo nigba naa.

O di ipo naa mu lati 1983 de 1989.

Bakan naa lo ṣe fun Major-General Oladayo Popoola, Ọgagun Adetunji Olurin ati Ọgagun Sasaenia Oresanya.

Oloye Alabi ni Alaga ẹgbẹ Adegoke Adelabu (Penkelemesi) ati the Yusufu Olatunji (Baba l'Egba).

Ọkan lara awọn ọmọ igbimọ Olufọkantan ẹgbẹ Adekunle Fajuyi Foundation, D.O.Fagunwa Foundation, Duro Ladipo Foundation ati bẹẹ bẹẹ lọ ni.

Oloye Ibadan to n reti ati depo Olubadan lọjọ kan ni Oloogbe Lekan Alabi, ki ọlọjọ too de sipo Abese Olubadan to wa.