Okocha fi ẹ̀yìn Portable janlẹ̀ nínú ìjà ẹ̀ẹ̀kejì, Ọmọ Olalomi ṣàlàyé bó ṣe jẹ́

Habeeb Okikiola (Portable)

Oríṣun àwòrán, portablebaeby/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Ana ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2026 ni oṣere tiata; Charles Okocha ati gbajumọ olorin taka-sufee, Habeeb Okikiola tawọn eeyan mọ si Portable tun wọya ija fun igba keji, Okocha si fi ẹyin Were olorin nalẹ nigboro aye.

Lojiji ni kiku ara ẹni lẹṣẹẹ naa pari ni gbagede Balmora to ti waye ni Victoria Island, ipinlẹ Eko, nigba ti Portable binu jade nibi lẹyin ipele akọkọ.

Tẹ o ba gbagbe, eyi ni igba keji ti awọn gbajumọ mejeeji yoo wọya ija ẹṣẹ kikan, wọn ti kọkọ jọ ja ri ni 2023 ti Portable si bori.

Ninu eyi ti wọn pe orukọ rẹ ni "Unfinished Business" yii ni Okocha ti wa fi ajulọ han Portable, bo tilẹ jẹ pe Ọmọ Olalomi sọ pe oun loun bori ija naa.

Ki lo ṣẹlẹ nibi ija naa?

Nigba ti awọn gbajumọ mejeeji bẹrẹ si i ku ara wọn lẹṣẹẹ to lagbara, ti wọn wọya ija gidi ni Portable fi ẹṣẹ gbe Okocha ṣubu.

Ọrọ di ariwo laaarin agbo.

Nigba naa ni rẹfiri to n la wọn nija sare bọ sibẹ lati la wọn.

Awọn ẹṣọ alaabo naa sare ṣiṣẹ ọwọ wọn, bẹẹ ni awọn gidi-ganku ta a mọ si Bouncers naa wọ inu irin ti ija ọhun ti n waye lati pẹtu si ija naa.

Lẹyin ti wọn la awọn onija naa tan, ti wọn si pari ipele akọkọ ẹṣẹ kiku, Portable jade kuro nibẹ, awọn eeyan si n ho le e lori bo ṣe n lọ.

Ko pẹ ni Ọmọ Olalomi tun pada wa si ori irin ti ija ti waye, o ni boun ṣe fi ẹṣẹ gbe Okocha ṣubu tumọ si pe oun ti bori rẹ niyẹn.

Amọ awọn alakooso ibo naa ko gba eyi fun Portable, wọn ni nigba to ti le kuro nibi ija naa lojiji, Okocha ti jawe olubori niyẹn.

"A fẹnuko le ipinnu kan. Nigba ti Portable ti le pa ija ti lẹyin ipele akọkọ rẹ, o tumọ si pe Charles lo jawe olubori niyẹn."

Bẹẹ ni alakooso eto naa ṣalaye.

Bayii ni Portable ṣe bẹrẹ si i pariwo pe ọrọ ko ri bẹẹ, o ni Okocha ko ṣe daadaa pẹlu oun.

"Emi ni mo lu u to ba jẹ ti ọkunrin sọkunrin, niṣe lo ge mi jẹ"

Ninu fidio kan to fi si oju opo Instagram ẹ lọjọ Satide ti I ṣe ọjọ keji ija naa, Portable ṣalaye pe oun loun bori ija naa.

O ni oun fi ẹṣẹ gbe Charles ṣubu, ọkunrin naa si wa ge oun jẹ.

Portable sọ pe Okocha fun oun lọrun, o tun ge oun jẹ loun

ṣe ni oun o ja mọ.

O fi oju ọgbẹ kan han lẹyin rẹ, eyi to ni ibi ti Okocha ti ge oun jẹ niyẹn.

"Ṣe o yẹ ko tun maa ge mi jẹ, wọn o sọ fun mi pe o maa ge mi jẹ.

"Ẹyin ololufẹ mi, olorin ni mi o. Iṣẹ orin pe ju gbogbo ija ta a n ja yii lọ, ti mo ba gba ere mẹwaa, o pe mi ju gbogbo radarada yii lọ, aṣeju ni ijakadi, orin ti to."

Bẹẹ ni Portable wi.

Ki lo fa ija gan-an?

Portable lo fẹsun kan Charles Okocha pe o kọ lati san ọpọ owo miliọnu naira to oun lẹyin eto kan.

Amọ Okocha sọ pe ko ri bẹẹ, o ni ko si adehun owo kankan laarin oun ati Portable.

O fi kun un nigba naa pe pẹlu ẹ naa, oun ṣi fi ẹgbẹrun marun-un miliọnu ranṣẹ si i.

Ede aiyede naa lo pada de ori ayelujara, wọn si pada fẹnuko si jija ẹṣẹ ti gbogbo aye yoo ri lati yanju rẹ.

Oṣu Kejila ọdun 2023 ni wọn ja ija akọkọ ni Victoria Island, ipele mẹrin nija ọhun, Portable lo si pada bori ninu rẹ.

Amọ Okocha ni oun ko gba, o ni ko si akoyawọ ninu ija naa, bẹẹ lo ni ibọwọ ti Portable wọ lasiko ija naa ko pe oun.

Lẹyin naa ni Okocha kede pe awọn yoo tun ija naa ja, eyi to waye bayii ti wọn si kede rẹ pe oun lo fi ẹyin Portable janlẹ.

Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìjà Portable àti Charles Okocha tí yóò wáyé lónìí

Patako ipolongo ija awọn mejeji

Oríṣun àwòrán, X/@Moyradfin

Alẹ oni ni gbajugbaja were olorin, Habeeb 'Portable' Okikiola ati oṣere tiata Nollywood, Charles Okocha yoo pade lori papa lati kan ẹṣẹ.

Ipade wọn yii ni yoo jẹ igba keji ti awọn mejeji yoo kan ẹṣẹ lẹyin ti wọn ti kọkọ ja lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kejila, ọdun 2023.

Portable lo gbegba oroke lọdun naa lọhun lẹyin to fi ẹṣe dara soju Okocha.

Ṣaaju ija ti yoo waye lonii ni awọn mejeji ti n leri tantan mọ ara wọn ti wọn tu n sọrọ kobakungbe si ara wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, Portable ti pade Carter Efe ati Speed Dalington lẹyin ija akọkọ rẹ pẹlu Okocha.

Ninu ija oun ati Dalington, Portable lo bori amọ o lulẹ ninu ija rẹ pẹlu Carter Efe.

Bi Portable ṣe n leri tantan naa ni Okocha n sọ pe ajẹkun iya ni Portable yoo jẹ lalẹ oni.

Iwọnyii ni awọn ohun yo yẹ ki o mọ nipa ja naa

Oni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 ni ija naa yoo waye niluu Eko.

Awọn to n ṣagbatẹru rẹ ti sọ pe awọn eeyan yoo le maa wo ija naa lori ayelujara bo ṣe n lọ kaakiri agbaye.

Gbagede Balmoral Convention Centre, to wa ni Victoria Island, nilu Eko ni ija naa yoo ti waye.

AKọle ija ti yoo waye loni ni "Unfinished Business" (Chaos in the Ring card).