Wo bí ìtakùrọ̀sọ BBC Yorùbá ṣe lọ láàárín àwọn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun

Asia to ṣafihan awọn oludije sipo gomina nipinlẹ Osun

Oríṣun àwòrán, BBC YORUBA

Àkọlé àwòrán, Asia eto itakurọsọ BBC Yoruba
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2026 yii ni itakurọsọ laaarin awọn oludije sipo gomina ipinlẹ Osun waye, eyi ti BBC News Yoruba gbe kalẹ.

Ọpọ awọn eeyan, paapaa awọn ololufẹ oludije kọọkan ni wọn peju lati wo bi eto naa ṣe lọ, ti onikaluku si n beere oniruuru ibeere to n ru wọn loju.

Oludije mẹrinla ni wọn jade sita lati du ipo ninu eto idibo gomina Osun to n bọ lọna lọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

Oludije sipo gomina bii Ademola Adeleke lati ẹgbẹ Accord; Bola Oyebamiji lati ẹgbẹ oṣelu APC; Najeem Salaam lati ẹgbẹ oṣelu ADC; Olajide Esan ti AAC; Olufemi Adesuyi ti ẹgbẹ oṣelu ZLP ati awọn miran ni BBC Yoruba fi iwe pe lati wa nibi eto itakurọsọ naa, ṣugbọn to jẹ pe awọn mẹta pere lo yọju.

Ọnarebu Najeem Salaam tọpọ mọ si Iwaloye, Ọgbẹni Olajide Esan ti ẹgbẹ oṣelu AAC ati Ọgbẹni Olufẹmi tẹgbẹ oṣelu ZLP ni wọn yọju.

Ọnarebu Najeem Salaam

Ọnarebu Najeem Salaam ṣalaye lẹkunrẹrẹ fun BBC Yoruba ati awọn araalu, to si jẹ ko di mimọ pe lara afojusun toun ni, bi araalu ba dibo yan oun ni riro awọn agbẹ ati olokoowo kereje-kereje lagbara, ipese ina ọba to dara, ati awọn miran.

Salaam ni oun ni ọpọlọpọ iriri lati ṣe ohun ti araalu n fẹ, paapaa lati yi orukọ ipinlẹ naa pada kuro ni ipinlẹ oṣiṣẹ ti gbogbo eeyan mọn-ọn-mọ, si ipinlẹ ti yoo jẹ eyi to n pe awọn olokoowo nla-nla lagbaaye wọle.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe;

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ẹni to ba yẹ loye lo n joye, ẹni to ba mọ ọna lo n tọ ọ. Awọn nnkan ti mo fẹẹ ṣe, ti mo ti polongo rẹ, ti mo si ti fi sita, to yatọ si ohun ti wọn ti n ṣẹlẹ, tabi eyi ti wọn n ṣe lọwọlọwọ, lo jẹ ki n jade sita, lo jẹ ki n gbagbọ, ti Osun si fi duro ti mi wi pe emi ni mo yẹ loye naa ni ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

"Ni akọkọ, ni ipinlẹ Osun lonii, emi ni oludije akọkọ to sọrọ nipa ina mọnamọna wi pe bi mo ba loore ọfẹ lati de ipo yii, ina mọnamọna wa ko nii ṣẹju mọ, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan naa ti n to lẹyin rẹ.

"Eleyi ko si ninu nnkan ti awọn ijọba wa ti ṣe nipinlẹ Osun. Ọdun 2023 ni wọn ṣagbekalẹ eto naa, pe ki awọn ipinlẹ kọọkan ṣeto ina wọn bo ṣe wu wọn.

"Mo rii pe o ti ṣẹlẹ lawọn ipinlẹ kan, ti ko si ṣẹlẹ lọdọ wa. To ba ṣẹlẹ lọdọ wa, ọrọ aje wa a lọ soke sii. Ina mọnamọna jẹ ọkan lara awọn ọpakutẹlẹ ti eto ọrọ aje wa fi n mẹhẹ. Tia ba ri ti ina ṣe, gbogbo nnkan maa duro deedee.

"Awọn to n lo ina a rii lo, ileeṣẹ a lo, ijọba yoo lo o, adani yoo lo – ti a ba rii ṣe, ti eto aabo si duro ninu awọn eto ti mo fẹẹ ṣe, o da mi loju pe a ko nii laagun pupọ ju lati gbe awọn olokoowo wọle lati wa da ileeṣẹ silẹ nipinlẹ Osun."

Siwaju sii, o ni eto ẹkọ ọfẹ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ titi de girama jẹ oun logun pupọ, to si loun yoo ṣagbekalẹ rẹ nigba toun ba de ipo naa.

Olajide Esan naa sọrọ

Oludije yii sọ pe iṣẹ ilu ni Ọlọrun gbe le oun lọwọ, oun fẹ sin ipinlẹ Osun ni, ko ba owo de.

Olajide sọrọ yii lalẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Keje ọdun 2026 yii, nibi itakurọsọ ti ileeṣẹ BBC News Yoruba gbe kalẹ fawọn to fẹ di gomina ipinlẹ Osun ninu ibo to ku si dẹdẹ naa.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu AAC ti Omoyele Sowore n dupo aarẹ Naijiria labẹ rẹ naa sọ pe:

" O di ọjọ ti araalu ba mọ pe wọn n jẹun ọmọ ninu oyun ni pẹlu owo ti wọn n gba lọwọ oṣelu, ko too ye wọn pe ohun to yẹ ki wọn jẹ́ ni wọn n jẹ.

"Emi o ni owo ti mo maa fun araalu lati dibo fun mi o, bi ẹ ba ri ẹlomi-in ti ẹ ro pe o tun kunju oṣuwọn ju mi lọ, to fẹẹ sinlu ju mi lọ, ẹ lọọ dibo fun un."

Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Olajide Esan sọ pe ohun ti oun mu ni pataki ni gbigba ijọba fun araalu, nigba ti araalu ba ti le sọ ohun ti wọn fẹ.

O ni eto kan toun pe ni Osun Residence Data Base yoo jẹ koun mọ iye agba ati ọmọde to wa l'Osun ati ohun ti wọn n fẹ, ti ko fi ni fi sibi ikan ju ibi kan lọ.

Bakan naa lo ni oun tun ni eto mi-in ti yoo ri si iṣuna, o pe e ni Financial Dashboard.

"Eyi yoo jẹ kawọn ara ipinlẹ Osun mọ iye to n wọ apo ijọba, yoo jẹ ki wọn mọ iye ti ijọba n na lọwọ ati iye to ku lapo ijọba, to jẹ pe ti naira kan wọn ba sọnu, wọn yoo le beere pe, 'Gomina, naira kan wa da."

Olufemi Adesuyi, ZLP

Oludije sipo gomina ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Zenith Labour Party ni Ọgbẹni Olufẹmi Adesuyi, to si wa lara awọn ti BBC Yoruba ranṣẹ pe lati wa nibi eto itakurọsọ to waye.

O ṣeni laanu pe pẹlu bi oludije naa ṣe yọju to, ẹrọ nẹtiwọọki rẹ ko faaye gba a lati kopa.

Gbogbo igbiyanju rẹ lati darapọ lo ja si pabo, pẹlu oniruuru igbiyanju rẹ.

Sẹnetọ Ademola Adeleke

Ṣaaju asiko yii ni BBC Yoruba ti fi iwe ranṣẹ si Gomina Ademola Adeleke nipa eto itakurọsọ yii, to si ṣeleri lati wa nibẹ ni gbogbo ọna, ṣugbọn to ṣeni laanu wi pe ko yọju titi digba ti eto naa fi wa si opin.

Nibi ifọrọwerọ ti BBC Yoruba ṣe fun Adeleke, a ṣalaye bi eto naa yoo ṣe lọ fun un, to si fi wa lọkan balẹ wi pe oun yoo kopa.

Gbogbo ọjọ Ẹti, ko to di pe eto naa bẹrẹ ni BBC fi n ba awọn alabaṣiṣẹpọ gomina sọrọ lati wa ni imurasilẹ, ti won si fi ye wa pe ka fọkan balẹ, gomina yoo kopa.

Koda, titi ti eto naa fi n lọ lọwọ lawọn alabaṣiṣẹpọ gomina fi n ṣeleri fun wa pe gomina yoo darapọ mọ wa, ṣugbọn to pada jẹ pe a ko ri wọn.

Ọgbẹni Bola Oyebamiji

Oludije sipo gomina ipinlẹ Osun labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC ni Ogbẹni Bola Oyebamiji, ẹni to ṣeleri lati kopa nibi eto itakurọsọ naa.

Yatọ si pe awọn aṣoju BBC Yoruba fi ẹnu sọ fun oludije naa lasiko ifọrọwerọ ti wọn ṣe pẹlu rẹ niluu Oṣogbo laipẹ yii, a tun kọwe ranṣẹ si i lati fi to o leti, toun naa si ṣeleri lati yọju.

Gbogbo asiko ti itakurọsọ naa n lọ lọwọ ni BBC n gbiyanju lati pe akiyesi rẹ si i, paapaa lati mu ileri to ṣe wa si imuṣẹ, nipa yiyọju sibi eto naa, ṣugbọn to jẹ pe pabo lo ja si.

Òní lònìí ń jẹ́...Ìtàkùrọ̀sọ BBC láàárín àwọn olùdíje sípò gómìnà Osun yóò wáyé

Awon oludije gomina nipinle Osun ree, pelu akoko ti itakuroso yoo waye

Oríṣun àwòrán, BBC YORUBA

Àkọlé àwòrán, Awọn oludije sipo gomina Osun

Gbogbo eto lo ti pari patapata fun akanṣe eto itakurọsọ laaarin awọn oludije s'ipo gomina nipinlẹ Osun, ninu eto idibo to fẹẹ waye ninu oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Ọjọ Abamẹta tii ṣe ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina ipinlẹ Osun yoo waye, gẹgẹ bi ajọ eleto idibo nilẹ Naijiria, INEC ṣe kede rẹ ninu oṣu Keji, ọdun yii.

BBC Yoruba lo fẹẹ ṣagbatẹru eto itakurọsọ naa, nibi ti awọn eeyan kaakiri agbaye yoo ti farabalẹ wo o lori ikanni ayelujara ati awọn ileeṣẹ amohunmaworan, to fi mọ redio nipinlẹ Osun.

Awọn oludije sipo gomina mẹta ọtọọtọ bii Gomina Ademola Adeleke lati inu ẹgbẹ oṣelu Accord, Bola Oyebamiji lati inu ẹgbẹ oṣelu APC ati Najeem Salaam toun yoo dije lẹgbẹ oṣelu ADC ni wọn yoo jọ dahun oniruuru ibeere lati ọdọ awọn akọṣẹmọṣẹ akọroyin BBC ati awọn oludibo nipinlẹ Osun.

Agogo mẹfa irọlẹ ọjọ Ẹti, tii ṣe Furaide, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Keje, ọdun 2026 ni eto itakurọsọ naa yoo waye lori awọn ikanni ayelujara ti BBC Yoruba.

Kii ṣe igba akọkọ ree ti eto itakurọsọ ọhun yoo maa waye, paapaa nipinlẹ Osun, ṣugbọn to jẹ pe ọna ara-ọtọ ni ti ọdun 2026 yii fẹẹ gba waye, pẹlu bi gbogbo awọn oludije mẹtẹẹta ṣe ti wa ni igbaradi.

awọn araalu yoo ni anfaani lati beere awọn ibeere, yala eyi to n ru wọn loju, tabi awọn ohun ti wọn nilo lati mọ nipa iṣejọba oludije kọọkan, bi wọn ba de ipo ti wọn n foju sọna fun.

Bi eto itakuroso yoo se lo
Àkọlé àwòrán, Aworan to sapejuwe itakuroso naa