Àwọn Alfa Ilorin láwọn ò fẹ́ 'Ìrù-Ẹkùn' tí Sunday Igboho dá sílẹ̀ ni Kwara, Ààrẹ Ìgbómìnà fèsì pé Ọ̀rọ̀ wọn kò mọ́gbọ́n wá

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn Alfa Ilorin ti pariwọ sita pe awọn o fẹ oloye Sunday Adeyemo ti ọpọ mọ si Sunday Igboho ni Ipinlẹ Kwara.
Eyi ko sẹyin fọnran kan to n ja rain lori ayelujara nibi ti agbẹjọro kan, Umar Imam ti la a mọlẹ pe, awọn ko fẹ Sunday Igboho ati ẹgbẹ Iru Ẹkun rẹ ni ipinlẹ naa.
Ti ẹ ko ba gbagbe, ni ọsẹ to kọja ni Oloye Sunday Igboho ati awọn ẹmẹwa rẹ lọ si ilu Ganmọ ni ipinlẹ Kwara lati safilọlẹ ẹgbẹ Iru Ẹkun lọna ati koju awọn agbesunmọmi ti wọn n yọ ipinlẹ naa lẹnu.
Ìdí tí a ò fi fẹ́ Ìrù-Ẹkùn ní Kwara
BBC News Yoruba ba agbẹjọro Umar Imam sọrọ lori ago, o si ṣalaye awọn idi to fi sọ pe awọn ko fẹ Sunday Igboho ati ẹgbẹ Iru Ẹkun rẹ.
Umar Imam to ni oun n gbẹnusọ fun ẹgbẹ kan to n daabo bo asa ati ise Ilorin sọ pe "Sunday Igboho to da Iru Ẹkun kalẹ jẹ ẹlẹya n mẹya.
"Sunday Igboho lo n jijagbara fun idasilẹ orile-ede Yoruba, oun lo n pe fun ki Naijiria pin, kii se ohun aṣiri, nnkan ti gbogbo wa mọ ni.
"Igba naa wọn ni awọn n kogun bọ wa Ilorin lati wa yọ ọba Ilorin nipo ki wọn si yan ọba alade, awọn ọrọ yii o jẹ ki a le fọkan tan Sunday Igboho ati Iru Ẹkun rẹ."
Umar Imam ni lootọ oun ko ni aṣẹ ati sọrọ fun Ilorin amọ ni ti ẹgbẹ ti oun n soju, awọn o fẹ Sunday Igboho.
O tẹsiwaju pe, kiise pe inu awọn o ni dun ti Igboho ba le sẹgun agbesunmọmi ni Kwara, amọ ọrọ bi o se n lọ Fulani mọ awọn ọdaran lawọn koro oju si.
"A ri bi wọn ṣe n se fun awọn Fulani ni ipinlẹ Oyo, paapaa julọ ni Igangan, iru eyi la o fẹ ko sẹlẹ ni Kwara.
"Ẹni ti wọn ba mu fún ẹsun agbesunmọmi, ki wọn kaa kun ọdaran, ki wọn si ye lọ wọn mọ ẹya Fulani.
"Gbogbo awọn Fulani pọ ti wọn ti gbe ohun ribiribi ṣe fun orilẹede yii, ṣugbọn a o ni gba ki a lọ wọn mọ ẹya wọn, ṣugbọn ọdaran ni wọn fi n pariwo Fulani kaakiri.
"Eleyi ni a o fẹ, a si ṣetan lati ja ija naa labẹ ofin nitori a ko fẹ rogbodiyan ni ipinlẹ Kwara.
Ọ̀rọ̀ náà kò mọ́gbọ́n wá - Ààrẹ Ìgbómìnà fèsì
Ẹwẹ BBC Yoruba kan si Aarẹ ọmọ ibilẹ Igbomina, Oloye Bisi Fakayode lori aago lati mọ idahun ẹgbẹ rẹ lori ọrọ ọhun.
Oloye Fakayode sọ pe ọrọ ti agbẹjọro naa sọ ko mu ọgbọn dani, pe ko si yẹ ki wọn gbọ eru ẹ lẹnu ẹni to kawe.
Fakayode sọ pe "Ẹni to sọ pe awọn o fẹ Sunday Igboho ni Kwara jẹ ẹni ti ko ni ifẹ nitori ohun to ba de ba oju, o de ba imu.
"Ka ni o ni ifẹ ni, yoo mọ wi pe, ti wọn ba n pa ọmọ iya rẹ, o yẹ ki oun tara.
"Isẹ ti wọn o ran wọn ni wọn yoo maa jẹ, bẹẹ si ni bi Igboho ṣe de, ibi ti wọn ti n payan, ti wọn ti n jiyan gbe lo lọ taara.
"Koda, o ṣe sheu fun Emir nigba to n sọrọ, Igboho o wa lati dunkoko mọ ẹya kankan ṣugbọn o wa lati dẹkun agbesunmọmi ni.
"Ki Igboho to wa, sebi Miyetti Allah ti wọn jẹ Fulani ati Bororo ti kọkọ wa lati ṣe aabo fun wa, a o si binu sii.
"Ki wa lode ti wọn fi n pariwo nigbati Igboho to jẹ Yoruba wa lati dẹkun iwa ibi ni ti wọn n wu ni ilu wa?"
Bawo ni ọrọ 'Iru Ẹkun' ṣe jẹ gan ni Kwara?

Ajafun Iran Yoruba nni, Oloye Sunday Igboho sefilọlẹ ikọ eleto aabo naa lọjọbọ ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu keje ni ile ọmọ ibilẹ Igbomina to wa ni ilu Ganmọ, Ilọrin, Ipinlẹ Kwara.
BBC News Yoruba bawọn peju sibi eto naa to bẹrẹ ni nnkan bi ago meji abọ Ọsan, tawọn eeyan ẹkun Gusu Kwara si peju si lọpọ yanturu.
Nigba to n sọrọ, Oloye Sunday Igboho sọ pe, asiko ti to bayii ti alafia yóò jọba ni Ẹkun Guusu Kwara.
Oloye Sunday Igboho salaye pe, Aarẹ Bọla Tinubu ti fun oun lasẹ lati bẹrẹ ikọ eleto alaabo Iru Ẹkun pẹlu ifọwọsowọpọ awọn Ọlọpaa.
Oloye Sunday Igboho fikun pe, gbogbo ilu tawọn agbesunmọmi ti le awọn eeyan kuro nilu ni Ẹkun Gusu Kwara loun yóò de bẹrẹ lati oni lọ.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, ẹnikẹni ti awọn ba ba ibọn lọwọ rẹ ninu Igbo lai se ọdẹ tabi vigilante, ọdaran ni.
O ni kawọn oniwa ọdaran tete kuro ninu Igbo Ẹkun Gusu Kwara nitori Iru Ẹkun ti bẹrẹ iṣẹ ni Kwara.
O tẹsiwaju pe, aarẹ Bola Tinubu ni ki wọn maa gboriyin fun lori aseyọri iru ẹkun, eni yoowu to ba ni ifẹ si iṣẹ Iru Ẹkun ko forukọsilẹ, ọfẹ ni igbaniwọle.
Igboho wa gba awọn ọmọ ikọ iru Ẹkun ni mọran lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn agbofinro pẹlu alaye pe, ki wọn yago fun sise idajọ lọwọ ara ẹni.
O tun lo akoko naa lati fi dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu ati Gomina Abdulrahman Abdulrazak fun aye ti wọn fi gbàá.
Ki lo sẹlẹ tẹlẹ latẹyin wa nipa eto aabo ẹkun guusu Kwara?

Ẹkun Gusu Kwara n koju iṣoro ọrọ eto abo lati bi ọdun melo kan sẹyin.
Iṣẹlẹ naa si ti ko ipaya ba ọpọ awọn ara ilu de bi pe ọpọ lo ti sa kuro nilu wọn, ti wọn si sa lọ si ilu mi.
Awọn ijọba ibilẹ ti ọrọ naa kan julọ ni Ijọba ibilẹ Ifẹlodun, Ekiti, Isin, Oke ẹrọ ati ijọba ibilẹ Irẹpodun ti gbogbo wọn wa ni Ẹkun Gusu Kwara.
Awọn agbesunmọmi wọ inu ilu lọ lati lọ ji awọn eeyan gbe, bẹẹni wọn tún ji awọn eeyan gbe nile Ijọsin.
Ko si Isọ oru lawọn ile ijọsin to wa lẹkun idibo naa mọ, ti bẹru ti bẹru lawọn eeyan n gbe lẹkun naa.
Awọn to ni ayẹyẹ o le lọ ilu abinibi wọn lati lọ ṣe ayẹyẹ mọ, se ni wọn sin oku iya tabi Baba wọn si ilu ti wọn gbe latari ibẹru awọn ajinigbe.
Koda, ijọba ti pasẹ laipe yii pe ko gbọdọ ṣi ayẹyẹ opin Ọdun tawọn ile ẹkọ ṣe


























