Kí ló dé tí obìnrin kan ṣe bẹ́ sínú Ọ̀sà l‘Eko, kí àwọn òmùwẹ̀ apẹja tó dóòlà ẹ̀mí rẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Obinrin kan ni iroyin fi to wa leti pe awọn omuwẹ apẹja ti doola ẹmi rẹ, lẹyin to bẹ sinu agbami ọsa lati gba ẹmi ara rẹ.
Gẹgẹ iroyin to tẹ BBC lọwọ ṣe sọ, a gbọ pe agbami ọsa ti afara Idumota si Carter ni obinrin lọ bẹ si, lọsan ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii.
Awọn to wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ naa sọ pe ile aye lo su obinrin ọhun, to fi pinnu lati gba ẹmi ara rẹ lojiji.
Ninu fọnran kan to n kaakiri ori ayelujara, la ti ri obinrin ọhun to jokoo ninu ọkọ oju omi, lẹyin ti awọn omuwẹ gbe e jade ninu okun nla naa.
Pakopako ni obinrin naa n wo, lẹyin ti wọn doola ẹmi rẹ tan, ti ko si sọ ohunkohun ni gbogbo asiko ti awọn eeyan n beere ọrọ lọwọ rẹ.
Oniruuru ibeere ni awọn to n kọja n beere lọwọ obinrin naa, lati mọ idi pataki to fi pa ọkan pọ lati gba ẹmi ara rẹ lojiji.
"Ki lẹ n ro, to fi le to bẹẹ?" obinrin kan sọ bẹẹ ninu fọnran to n kaakiri ọhun.
Bakan naa la tun gbọ ohun ọkunrin kan to n sọ pe, "Nko le tori ironu, ki n gba ẹmi ara mi," ti ọkunrin miran si sare da a lohun pe, "Gbadura ki o ma ba a si niru ipo yii,"
Pẹlu bi obinrin naa ṣe kọ lati sọrọ jade ni gbogbo asiko naa, lo fa a ti ẹnikẹni ko fi tii mọ kulẹkulẹ erongba obinrin naa lati gb'ẹmi ara rẹ.





























