Ìbanilórúkọjẹ́ lẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ́n fi kàn mí, Oluomo sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tílé aṣòfin Ogun fagilé ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan adarí ilé tẹ́lẹ̀

Gomina Dapo Abiodun wọ kootu pẹlu awo loju rẹ, o ba ọwọ pẹlu abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ, Họnarebu Olakunle Oluomo to wọ aṣọ adirẹ

Oríṣun àwòrán, Prince Dapo Abiodun/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun ti kede wi pe abẹnugan ile tẹlẹ, Olakunle Oluomo ko jẹbi ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan an.

Ile tun fẹnuko nibi ijokoo wọn lonii Ọjọru niluu Abeokuta wi pe iyọnipo rẹ ti di ikọwefiposilẹ bayii.

Igbesẹ yii waye lẹyin ti igbimọ kan eyi ti igbakeji abẹnugan ile, Arabinrin Lateefat Ajayi jabọ iṣẹ rẹ fun ile lori ọrọ naa.

Ọrọ naa da lori aba ti Họnarebu Oluomo gbe siwaju ile lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kẹta ọdun yii pe ki wọn yi ẹsun ikowojọ ti wọn kan oun danu.

Họnarebu Ajayi lo dabaa wi pe ki ile gba aba naa wọle, eyi ti aṣofin Yusuf Amosun ṣikeji aba naa.

Ile fi idi rẹ mulẹ wi pe ẹsun ikowojẹ ko si ninu awọn ẹsun ti wọn fi kan Oluomo ki wọn to yọ ọ nipo.

Gbogbo ile fẹnu ko wi pe ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan Oluomo ko fẹsẹ mulẹ tori ko si ẹri to daju lati le fidi rẹ mulẹ.

Ile tun foju aanu wo Oluomo lẹyin to bẹbẹ wi pe ki wọn yọ ẹsun ikowojẹ kuro ninu ẹsun ti wọn fi kan an.

Wọn ni igbesẹ ile yii wa ni ibamu pẹlu abala 36 iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.

Igbimọ to ṣewadii Oluomo sọ pe awọn ko ri ẹri to daju to le fi idi ẹsun ikowojẹ mulẹ.

Bayii ni ile tun pinnu wi pe ko ni wa ninu akọsilẹ wi pe ile yọ Oluomu nipo, wọn ni nnkan ti yoo wa ni akọsilẹ ni pe o kọwe fipo silẹ.

Ile aṣofin ipinlẹ Ogun ni awọn gbe igbesẹ yii waye lati ri pe iṣọkan wa laarin awọn ọmọ ile.

''Ko si ipo ti eeyan le wa nile aṣofin ti o gbe lati ile rẹ''

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrẹ rẹ, Oluomo ṣalaye fun BBC Yoruba pe ''lẹyin ti ile ẹjọ sọ fun mi pe ile to yan mi sipo gẹgẹ abẹnugan tun le yọ mi nipo, nigba naa ni mo bẹ wọn pe ki wọn yọ ẹsun ikowojẹ kuro ninu ẹsun ti wọn fi kan mi nigba ti wọn fẹ yọ mi nipo

Mo ni ki wọn ṣe iwadii mi, ki wọn si kede abọ iwadii naa lori ẹsun ikowojẹ naa.

Mi o ba ti lọ ile ẹjọ to ba jẹ pe wọn o fẹsun ikowojẹ kan mi ni.''

Amọ, abẹnugan ile aṣofin ipinlẹ Ogun tẹlẹ sọ pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe abọ iwadii ti wọn ṣe fi han oun o kowo ile jẹ.

Lori bi ile ti sọ wi pe awọn ti iyọnipo rẹ si ikọwefiposilẹ, Oluomu sọ fun BBC Yoruba pe nnkan to jẹ oun logun julọ ni ibanilorukọjẹ ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan oun.

O ni o wu wọn ni wọn fi yi iyọnipo oun pada si ikọwefiposilẹ, ṣugbọn oun dun pe ẹsun ikoeojẹ to le fa ibanilorukọ foun ti kuro nibẹ.

Oluomo ni oun tun ti n ba gbogbo awọn to tako oun ninu ile aṣofin ṣe ajọṣepọ pada, lai na an ni nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin.

Adari ile tẹlẹ ni oun ti gba pe o ṣee ṣe ko jẹ pe lara kadara oun ni iyọnipo to ṣẹlẹ.

''Ko si ipo ti eeyan le wa nile aṣofin, ko sẹni to gbe ipo naa wa.

Onikalaku yoo pada sile rẹ ti a ba ti ṣiṣẹ tan nile.

Nitori naa, mo n ba gbogbo awọn ọmọ ile yooku ṣe daadaa, koda, emi atawọn kan ninu wọn tun ti pe ara wa lori ago lonii.

Mi o ba ẹnikankan ja, mi o ba ẹnikankan binu,'' Oluomo lo sọ bẹẹ.