Àlàyé rèé lórí ipa táwọn ikọ̀ aláàbò kó lórí báwọn Àgùnbánirọ̀ mẹ́ẹ̀dógún, aráàlú mẹ́fa, tí wọn jí gbé ní Kogi, ṣe gba ìtúsílẹ̀ àti ohun tí ààrẹ Tinubu sọ

Awọn agunbanirọ ti ori ko yọ lọwọ ajinigbe ni wọn n di mọ awọn mọlẹbi wọn lasiko ti wọn gba itusilẹ

Oríṣun àwòrán, Kogi State Police Command/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Orin ọpẹ ati ayọ lo gba ẹnu awọn mọlẹbi awọn agunbanirọ mẹẹdogun ti awọn agbebọn jigbe nipinlẹ Kogi, nigba ti wọn pada gba itusilẹ.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi lo fidi rẹ mulẹ lọjọ Aje, ọsẹ yii wi pe awọn ti doola awọn ti wọn jigbe naa kuro lọwọ awọn agbebọn, ti wọn si ti pada sọdọ awọn eeyan wọn.

Kii ṣe awọn agunbanirọ yii nikan lawọn ajinigbe digun ko salọ, bi ko ṣe pe wọn tun ji awọn araalu gbe pẹlu wọn, eyi ti apapọ gbogbo wọn jẹ mọkanlelogun.

Ọpọ ninu awọn mọlẹbi awọn ti agbebọn jigbe yii, ni wọn ti fẹẹ sọ ireti nu, wi pe awọn ko tun nii foju kan awọn eeyan wọn ti wọn jigbe yii mọ, paapaa bi wọn ṣe n fọkan si bi wọn yoo ṣe san owo tabua lati fi gba wọn silẹ.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Kogi, Saliu Oyiza Afusat fi sita lọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026, o sọ pe apapọ awọn oṣiṣẹ eleto aabo ni wọn ṣiṣẹ ti wọn fi gba awọn ti wọn jigbe naa silẹ.

Afusat sọ pe inu igbo kan to wa lagbegbe Ekume ni wọn tọpinpin awọn ajinigbe naa si, ti wọn fi lọ koju wọn nibẹ..

"Lẹyin ti awọn agunbanirọ mẹwaa moribọ ninu igbo Egume, iwadii ileeṣẹ ọlọpaa, ologun, ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ati awọn eleto aabo miran lewaju lọ lati ṣayẹwo si gbogbo agbegbe inu igbo Egume," agbẹnusọ naa ṣalayẹ.

"Bi awọn agbebọn naa ṣe gburo gbogbo idunkooko apapọ ẹṣọ aabo, ni wọn ti na papa bora, ti wọn si fi awọn ti wọn jigbe silẹ salọ."

Àwọn tó gba ìtúsílẹ̀ ti n gba ìtọ́jú

Laisko ti wọn n ko awọn to gba itusilẹ naa kuro ninu igbo

Oríṣun àwòrán, Kogi State Police Command/X

Afusat fidi rẹ mulẹ pe lẹyin ti wọn gba awọn eeyan naa silẹ kuro lahaamọ awọn ajinigbe, o ni ile iwosan ti wọn ti n gba itọju ni gbogbo wọn wa bayii.

"Gbogbo awọn ti wọn gba itusilẹ ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii. Bakan naa ni ẹni to fara gbọta lẹsẹ ti n gba itọju to pe ye, ati pe ko sẹni to ku ninu gbogbo awọn ti wọn jigbe, ati awọn ẹṣọ aabo to lọ ṣiṣẹ naa.

O wa sọ ọ di mimọ pe ọga awọn, Nasiru Bello Kankarofi ti gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto aabo to lọ ṣiṣẹ itusilẹ awọn ti wọn jigbe naa.

Bakan naa lo gbe oriyin fun awọn ara agbegbe ti awọn ajinigbe naa lo lati fi tọju awọn ti wọn jigbe si, fun akitiyan lati tu aṣiri awọn afurasi ọdaran naa.

Bẹẹ lo ṣeleri wi pe ọwọ agbofinro yoo tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu iwa ijinigbe naa laipẹ, ti wọn yoo si foju ba ile-ẹjọ nigba ti asiko ba to.

Kí ni Ààrẹ Tinubu sọ?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n fi idunnu rẹ han, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu sọ pe iwuri ati idunnu nla lo jẹ foun pe awọn agunbanirọ ati araalu naa gba itusilẹ lai farapa.

"Inu mi dun lati gbọ iroyin wi pe awọn agunbanirọ ati awọn araalu mẹfa ti awọn ọdaran kan jigbe nipinlẹ Kogi lọsẹ to kọja ti gba ominira ara wọn pada," Aarẹ sọ bẹẹ.

"Iṣẹ itusilẹ ti awọn ileeṣẹ eleto aabo bii ọlọpaa, ologun, DSS ati awọn ọlọdẹ ibilẹ ṣe lo gba awọn mọkanlelogun ti wọn jigbe, leyi ti wọn jẹ ọkunrin mẹjọ ati obinrin mẹtala.

"Awọn agunbanirọ naa ati awon ti wọn jigbe pẹlu wọn ti wa nibi ti wọn ti n gba itọju lori awọn nnkan ti wọn koju lahaamọ, ko to di pe wọn pada sọdọ awọn mọlẹbi wọn."

Siwaju sii ni aarẹ fidi rẹ mulẹ pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo ṣi wa lori iṣẹ lati rii pe ọwọ tẹ gbogbo awọn to lọwọ ninu ijinigbe naa, pẹlu ileri wi pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ yoo foju winna ofin.

O wa jẹ ko di mimọ pe, "Iṣakoso mi fi ara jin lati rii pe awọn araalu le rin irin-ajo kaakiri orileede yii lai ni ibẹru lọkan."