Ìdí rèé tí Dangote fi ṣe àfikún owó epo bẹntiróòlù fún ìgbà mẹ́ta láàrin ọ̀sẹ̀ kan àti ipa rẹ̀ lórí aráàlú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile ifọporọbi Dangote ti ṣalaye idi ti o fi ṣe afiku owo epo bẹntiroolu fun igba mẹta ọtọọtọ laarin ọjọ mẹjọ.
Ile ifọpo Dangote sọ pe afikun owo epo bẹntiroolu naa ko ṣẹyin epo rọbi ọwọnlọwọn ti ileeṣẹ naa ti ra lati oke okun papaa julọ lasiko ti owo epo rọbi lọ soke lọja agbaye.
Alaye yii waye lẹyin tawọn eeyan bẹrẹ sii ra jala epo bẹntiroolu kan ni N1,310 si N1,320 nipinlẹ Eko ati Ogun, koda awọn mii ti n ra a ni N1,400 lawọn agbegbe mii.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn eeyan ti n ra epo bẹntiroolu ni N1,350 lawọn agbegbe kan lapa ariwa Naijiria, koda, a tun gbọ pe o ju bẹẹ lọ lawọn ibikan to jinna.
Eyi ṣẹlẹ latari igbesẹ ileeṣẹ ifọporọbi Dangote lati fi N65 kun owo lita kan epo bẹntiroolu lati N1,200 si N1,265 bẹrẹ lati ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii.
Eyi lo si jẹ igba kẹta ti Dangote yoo ṣafikun owo epo laarin ọjọ mẹjọ.
Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọlọpọ wi pe lasiko ti owo epo n lọọlẹ lagbaaye ni Dangote tun n ṣafikun owo epo ni Naijiria.
''Ileeṣẹ ifọporọbi Dangote ko le tẹle iye ti wọn n ta epo bẹntiroolu lọja agbaye lati ta epo ti wọn ti ra ṣaaju akoko yii''
Ẹwẹ, ọga agba kan nileeṣẹ ifọporọbi Dangote to ba iwe iroyin The Punch sọrọ amọ ti darukọ rẹ sọ pe, ileeṣẹ naa ko le tẹle iye ti wọn n ta epo lọja agbaye lati ta epo ti wọn ti ra ṣaaju akoko yii.
Ọga agba naa ṣalaye wi pe asiko ti Dangote ra epo rọbi ati asiko ti wọn fọ epo naa jinna sira wọn.
''Ti eeyan ba fẹ ra epo rọbi lonii, o ni asiko ti yoo sanwo fun epo naa, bakan naa lo ni asiko ti yoo ṣeto ọkọ oju omi ti yoo gbe epo naa wa si Naijiria ati igba ti epo ọhun yoo de lati fọ ọ fun lilo.
Ati wi pe epo ti a maa n ra kii ṣe epo kekere rara, lasiko ti owo epo si lọ soke lọja agbaye ni a ti ra epo yii,'' ọga agba ileeṣẹ ifọporọbi Dangote lo sọ bẹẹ.
Ileeṣẹ Dangote kọkọ ṣe afikun owo epo bẹntiroolu lati N1,165 si N1,185 lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹjọ yii.
Lẹyin ọjọ marun un ni Dangote tun kede afikun owo epo lọ si N1,200.
Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii kan naa ni ileeṣẹ ifọporọbi Dangote tun gbe owo epo lati N1,200 lọ si N1,265.
Afikun owo epo yii tun ti jẹ ki ọpọ eeyan maa kọminu lori ibaṣepọ to wa laarin iye ti wọn n ta epo rọbi lọja agbaye ati iye tawọn alagbata epo n ta bẹntiroolu fawọn eeyan ni Naijiria.
Ẹwẹ, akọwe ẹgbẹ alagbata epo bẹntiroolu, IPMAN, Chinedu Ukadike, ti ṣalaye pe oniruuru ipenija tawọn alagbata epo n koju lo le mu wọn ṣafikun owo epo.
Ukadike sọ pe lara awọn ipenija naa ni bi iye ti wọn n ta epo lọjọ agbaye ti n ṣe ṣege ṣege.
Bakan naa ni o tun sọ pe iye ti wọn n ṣẹ owo naira si dọla naa le ṣokunfa afikun owo epo bẹntiroolu.
Wo iye ìgbà tí Dangote ti ṣe àfikún owó epo ní Naijiria lọ́dún 2026
Adari ileeṣẹ ifọpo Dangote, David Bird, ti sọ pe kii ṣe pe awọn kan maa n ṣadeede fi kun owo epo bẹntiro bo ṣe wu awọn ni.
Ninu atẹjade kan ni Bird ti sọ pe ohun to n ṣẹlẹ ninu ọja epo rọbi lagbaye lo maa n sọ iye ti owo epo yoo jẹ lorilẹede kọọkan, ninu eyii ti Naijiria wa.
Nigba ti Dangote kọkọ bẹrẹ si n ta epo fun awọn ọmọ Naijiria, nnkan bii ₦898 lo n ta lita epo kan.
Lẹyin naa lo kede pe oun yoo maa ta lita kan laarin ₦960 si ₦990 fun awọn ti wọn ba fẹ ra epo naa lọpọ yanturu.
Ni ibẹrẹ ọdun 2026, ₦774 si ₦874 ni Dangote ta epo rẹ amọ nigba ti ogun Amẹrika ati Israel bẹrẹ, owo epo gbera soke lagbaye, eyii to ṣokunfa afikun iye ti wọn n ta epo naa ni Naijiria.
Lati igba ti ogun Iran ọhun ti bẹrẹ ni owo epo ti n le si lagbaye ti wọn si n ta agba epo kan laarin $80 si $90.
Ileeṣẹ ifọpo Dangote din owo epo bẹntiro rẹ ku si ₦1,075 fun jala epo kan lati ₦1,175 to n ta a tẹlẹ pẹlu adinku ₦100.
Agbẹnusọ ileeṣẹ naa Anthony Chiejina sọ fun awọn akọroyin pe epo ti wọn ba n pin lati ori omi ni wọn yoo ta ni ₦1,050.
Wọn ni "pẹlu agbeyẹwo iye owo ti a n ta epo ti a sẹ, a ti din PMS ku lati ₦1,175 si ₦1,075 (adinkun ₦100) fun lita kan.
Loṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni ileeṣẹ ifọpo Dangote tun mu alekun ba iye ti wọn n ta bẹntiroolu pelu naira marundinlọgọrin, N75.
Ileeṣẹ naa kede naa jade pe owo lita epo kan yoo tun gbenu soke si N1,275 lati N1,200.
Loṣu Keje ọdun 2026 yii ni ileeṣẹ ifọpo Dangote bẹrẹ sii ta jaala epo bẹntiroolu kan ni bii N1,300 naira ki o too tun walẹ.
Ileeṣẹ Dangote kọkọ ṣe afikun owo epo bẹntiroolu lati N1,165 si N1,185 lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹjọ yii.
Lẹyin ọjọ marun un ni Dangote tun kede afikun owo epo eyi to jẹ ki jala epo kan di N1,200.
Lọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kẹjọ yii ni ileeṣẹ ifọporọbi Dangote tun gbe owo epo lati N1,200 lọ si N1,265.



























