Àlàyé rèé lórí ohun táwọn dókìtà nílé ìwòsàn LAUTECH ń bèèrè fún, bí ìyanṣẹ́lódì wọn ṣe wọ ọjọ́ mẹ́rin

Ohun tawọn dokita fi maa n ṣayẹwo to wa lọrun obinrin kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ṣe ni ẹkọ ko foju mimu han fawọn alaisan ti wọn n gba itọju ni ile iwosan olukọni LAUTECH Teaching Hospital to wa ni Ogbomoso, ipinlẹ Oyo bi iyanṣẹlodi tawọn dokita ile iwosan naa gunle bayii ti wọ ọjọ mẹrin.

Ẹgbẹ awọn dokita ile iwosan naa sọ pe awọn ko i tii gbọ ohunkohun lati ọdọ ijọba ipinlẹ Oyo lati ọjọ Ẹti, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹjọ ti wọn ti gunle iyanṣẹlodi naa.

Ọsẹ mẹjọ kan ni awọn dokita naa ti n ṣekilọ ti wọn si n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ Oyo labẹ idari Gomina Seyi Makinde lati tete mojuto gbogbo nnkan ti awọn n beere fun ki wọn maa gunle iyanṣẹlodi.

Awọn dokita naa lo n beere fun pe ki ijọba mojuto igbayegbadun awọn, ki wọn si gba awọn dokita kun awọn oṣiṣẹ to wa nile iwosan naa lojuna a ti mu adinku ba iṣẹ to wọ awọn lọrun.

Ni ọjọ Kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹfa ni awọn dokita naa ti kọkọ ṣẹwele iyanṣẹlodi ti wọn gbiyanju lati gunle, ti wọn si fun ijọba atawọn alẹnulọrọ lẹka eto ilera ni gbedeke ọsẹ mẹjọ lati dahun sawọn ibeere wọn tabi ki awọn bẹrẹ iyanṣẹlodi mii.

Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita naa ni LAUTECH, Dokita Adedapo Mustapha nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aiku sọ pe, awọn dokita naa pinnu lati gunle iyanṣẹlodi naa lẹyin ti gbedeke ọsẹ mẹjọ ti wọn fun wọn pe lai gbọ ohunkohun lati ọdọ ijọba.

Mustapha ṣalaye pe awọn ko i tii gbọ ohunkohun lati ọdọ ijọba lati igba ti awọn ti gunle iyanṣẹlodi naa.

O sọ pe awọn aṣoju ileeṣẹ eto ilera nikan ni wọn fi ọrọ ẹnu lasan sọ fun awon lati fọkan balẹ amọ ti gbogbo awọn ileri asan naa ti su awọn dokita, ti wọn si n fẹ ayipada fun bi wọn ṣe n ṣiṣẹ.

O fi kun pe erongba awọn ni lati tẹsiwaju lati jiroro pẹlu awọn alẹnulọrọ, ti wọn si rọ Gomina Seyi Makinde lati tete da awọn lohun gbogbo ibeere awọn ki wọn le pada sẹnu iṣẹ wọn.

Ki ni awọn dokita naa n beere fun?

Ohun ti awọn dokita naa n beere fun ni sisan ajẹlẹ owo oṣu to kere julọ ti ijọba jẹ wọn, awọn ajẹmọnu wọn ati lati buwọlu owo ajẹmọnu tuntun ti wọn buwọlu fawọn dokita.

Bakan naa ni wọn tun n beere pe ki ijọba gbe atẹjade sita lati gba awọn dokita ṣenu iṣẹ sii.

Wọn ni ki ijọba tun ṣe agbejade owo idanilẹkọọ Medical Residency Training Fund eyi to wa fun ṣiṣe idanilẹkọọ fawọn dokita.

Awọn nnkan mii tun wọn tun n beere ni atunṣe awọn ibi ti awọn dokita maa n duro si nigba ti wọn b awa lẹnu iṣẹ alẹ, ki wọn si ṣe si iye wakati tawọn dokita n lo lẹnu iṣẹ ki iṣẹ ye wọn wọ lọrun.

Awọn dokita naa sọ pe awọn akẹgbẹ awọn ni ipinlẹ Osun, Ondo, Ekiti, Eko ati Ogun ni wọn ti n jẹ anfaani yii yatọ si awọn nikan.

Ile iwosan yii lo n pese eto iwosan fawọn olugbe ilu Ogbomoso ati agbegbe rẹ to fi mọ ilu Oyo, Iseyin atawọn ilu mii to sunmọ wọn.