Kí ló ṣokùnfà ikú gbajúmọ̀ òṣèrèbìnrin, Nimmy Ferrari tó jáde láyé lásìkò tó n palẹ̀mọ́ láti ṣí ilé tuntun tó kọ́

Oríṣun àwòrán, Nimmyferrari/Facebook
Agboole oṣere tiata lo tun ti padanu ọkan lara awọn oṣerebinrin rẹ miran, Nimmy Ferrari.
Nimmy Ferrari la gbọ pe o jade lasiko to n ṣe ipalẹmọ ayẹyẹ lati ko sinu ile tuntun to ṣẹṣẹ kọ si ilu Sagamu nipinlẹ Ogun.
Ọkan lara awọn oṣerebinrin nni, Oluwakemisola Apesin, ẹni tọpọ mọ si Anti Sidi lo tufọ iku oloogbe naa lori ikanni ayelujara.
Alẹ ọjọ Aiku ni iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Ferrari ki aye pe o digboṣe, bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to le sọ pato nipa iru iku to pa a.
Ṣugbọn ṣa, ohun ti awọn kan n sọ ni pe iku rẹ ko le ṣẹyin aisan to jẹyọ, lẹyin to ṣiṣẹ abẹ lori iju to wa nikun rẹ.
Ferrari ni yoo jẹ oṣere tiata kẹrin ti yoo ku laaarin oṣu meji lera wọn ninu ọdun 2026, iyẹn laaarin oṣu kẹjọ si oṣu Kẹsan.
Kemity kéde ikú Nimmy Ferrari
Nigba to n kede iku Ferrari, Apesin ti wọn tun n pe ni Kemity kọ ọ soju opo ayelujara rẹ pe "Gbogbo eeyan lo ti pada sile, ṣugbọn a fi iwọ nikan silẹ IDERA Nimmyferrari, o dara o,"
Lati bi ọdun meloo sẹyin ni Ferrari ti n sa gbogbo ipa rẹ lati di gbajumọ nidi iṣẹ tiata ati lori ayelujara.
Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iku Ferrari ṣi n jẹ iyalẹnu fun awọn eeyan, mọlẹbi, paapaa awọn ololufẹ rẹ kaakiri agbaye.
Ṣugbọn ṣa, awọn mọlẹbi oloogbe yii ko tii sọrọ tabi kede iku oṣerebinrin naa, bẹẹ naa ni wọn ko tii fidi aisan to jẹyọ lẹyin iṣẹ abẹ to lọ ṣe mulẹ.
Fọnran kan to n kaakiri ori ayelujara lọjọ Aje, ọjọ keje, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ṣafihan ibi ti awọn eeyan ti pejọ lati banujẹ lori iku Ferrari.
Inu ile ti Nimmy Ferrari ṣẹṣẹ kọ pari, to si n ṣe ipalẹmọ lati ṣayẹyẹ rẹ ni awọn eeyan naa ti n gbera ṣanlẹ banujẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe ọjọ Aje naa ni wọn ti sinku oṣere naa sinu ile to ṣẹṣẹ kọ pari yii.
Àwọn òṣèré tó ti kú
Temitope Osoba ni iroyin iku rẹ kọkọ jade lọjọ kẹta, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026. Iku Osoba lo waye latari ipenija aisan jẹjẹrẹ ti ọmu to koju.
Lasiko ti awọn eeyan n kẹdun iku Osoba lọwọ, ni agba oṣere nni, Taiwo Hassan tọpọ mọ si Ogogo naa tun jade laye lẹyin aisan to nii ṣe pẹlu jẹjẹrẹ, eyi ti wọn lo ti wa ni ipele kẹrin.
Lẹyin naa ni oṣere miran, Atinuke Kareem naa tun ki aye pe o digboṣe lẹyin aisan ti wọn sọ pe ko yatọ si ti jẹjẹrẹ ti ọmu, eyi ti wọn lo ti n ba a finra lati bi ọdun diẹ sẹyin

























