Ṣé lóòótọ́ ni Tinubu buwọ́lù ẹ̀wọ̀n gbére fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá kùnà láti dá owóòyá NELFUND padà fún ìjọba? Àlàyé rèé

Akẹkọọkunrin kan ati akẹkọọbinrin meji, Aarẹ Bola Tinubu wọ buba olomi buluu pẹlu fila

Oríṣun àwòrán, NELFUND/Bola Tinubu/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ NELFUND to n ri si eto ẹyawo fawọn akẹkọọ ile ẹkọ giga lorilẹede Naijiria ti sọ pe iroyin ofege niroyin to sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu ijiya ẹwọn gbere fawọn akẹkọọ ti ko ba ri owo ti wọn ba ya lọwọ ajọ naa da pada lẹyin ti wọn ba ti kẹkọọ gboye tan.

Ajọ NELFUND fi aworan kan to ṣafihan iwaju iwe iroyin ''The Daily Tribune, Thursday, May 27, 2027'' soju opo X rẹ, eyi ti wọn sọ pe kii ṣe iwe iroyin naa.

Akori to wa lori iroyin naa sọ pe ''Tinubu: Gbogbo akẹkọọ to ba kuna lati san owo ti ijọba ya wọn pada ni yoo lọ ẹwọn gbere.''

Ajọ NELFUND wa fontẹ lu oju iwe iroyin naa gẹgẹ bii ayederu iwe iroyin.

Ṣaaju ni NELFUND ti kọkọ sọ pe irọ to jinna si ootọ niroyin kan to ni ajọ naa ko sanwo fawọn akẹkọọ mọ.

Bakan naa ni ajọ NELFUND tun sọ pe ko si otitọ ninu iroyin mii to sọ pe awọn to gba owo naa gbọdọ bẹrẹ sii sanwo ọhun pada, nigba ti wọn ba si wa nile ẹkọ tabi ni kete ti wọn ba ti pari eto ẹkọ wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ohun ti ofin sọ nipa eto ẹyawo NELFUND

Lọdun 2024 ni Tinubu buwọlu ofin idasilẹ ajọ NELFUND to n ri si eto owooya fawọn akẹkọọ ti ko rọwọ họri lawọn ile ẹkọ giga ni Naijiria.

Ajọ NELFUND maa n ya awọn akẹkọọ lowo lai gba ele lori rẹ.

Lara owo yii ni wọn fi n sanwo ile iwe ati owo ounjẹ loṣooṣu.

Gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ, lẹyin ọdun meji ti akẹkọọ ba ti pari eto isinruulu agunbanirọ lẹyin to ba ti kuro nile ẹkọ ni o gbọdọ da owo naa pada.

Lẹyin igba ti iru akẹkọọ bẹẹ ba ti bẹrẹ sii ṣiṣẹ ni yoo bẹrẹ sii sanwo naa pada.

Ida mẹwaa owo oṣu ti iru akẹkọọ bẹẹ ba n gba ni yoo maa da pada fun ajọ NELFUND loṣooṣu.

Ida mẹwaa owo ti wọn ba n ri loṣooṣu naa lawọn akẹkọọ to ba n ṣiṣẹ ara wọn ti wọn ba gba iru owo yii yoo maa da pada.

Awọn akẹkọọ ti ko ba tii ri iṣẹ lẹyin ọdun meji ti wọn ba ti pari eto isinruulu agunbanibarọ wọn lanfaani lati sun sisan owo naa pada siwaju pẹlu ọdun meji nipa ibura nile ẹjọ.