Kí ló ṣokùnfà ikú ọmọ ìyá mẹ́ta lọ́jọ́ kan náà l'Ondo? Ohun tí a mọ̀ rèé

Ọga ọlọpaa Ondo, Felix Ohagwu, n rin pẹlu iṣọmọgbe rẹ ninu igbo

Oríṣun àwòrán, Ondo police/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ninu ibanujẹ ni ẹbi kan wa bayii npinlẹ Ondo lẹyin ti ọmọ iya mẹta padanu ẹmi wọn lọjọ kan naa.

Ẹkun sọ lẹyin ti wọn ri oku awọn mẹtẹẹta ninu odo kekere kan, lẹyin ti wọn ti n wa wọn kiri.

A gbọ wi pe baba awọn ọmọ naa, Samuel Jonah, ni wọn ba lọ si oko ki wọn to morile ọna ile lati oko.

Nigba ti baba wọn de ile ti ko ri wọn lo figbe ta wi pe nnkan ti ṣe oun.

Bayii ni wọn bẹrẹ sii wa awọn ọmọ naa kiri ki wọn to ri oku wọn leti odo kan lọjọ Abamẹta opin ọsẹ to kọja.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lori ohun to ṣokunfa iku awọn ọmọ naa.

Agbẹnusọ ọlọpaa Ondo, DSP Abayomi Jimoh, sọ pe awọn ọmọ naa wa pẹlu baba wọn ninu oko ki wọn to maa lọ ile.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii le sọ pato nnkan to ṣokunfa iku awọn ọmọ iya mẹta naa.

Amọ, agbẹnusọ ọlọpaa ṣalaye pe iwadii si n tẹsiwaju lati mọ nnkan to ṣekupa awọn ọmọ mẹta naa.

‘’Baba awọn ọmọ naa ti gba oku wọn lati sin wọn, nigba ti ileeṣẹ ọlọpaa n tẹsiuwaju iwadii rẹ lati tu iṣu de isalẹ ikoko lori iku ojiji to pa awọn ọmọ mẹta naa.

DSP Jimoh ni ileeṣẹ ti ranṣẹ ibanikẹdun rẹ si ẹbi awọn ọmọ to doloogbe ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ko ṣai rọ awọn obi ati alagbatọ lati maa bojuto awọn ọmọ wọn daadaa papaa julọ awọn to ba fẹ lọ ṣere lodo tori ewu to wa nibẹ.

Iku awọn ọmọ mẹta naa ti di nnkan ti o n kọ awọn ara ilu lominu wi pe ki lo le ṣokunfa iku awọn ọmọ mẹtẹẹta yìí.

Bi ẹbi awọn ọmọ naa ṣe n ṣọfọ ni awọn eeyan n duro de abọ iwadii ọlọpaa lori ohun to ṣekupa awọn ọmọ mẹtẹẹta naa.